Esr 1
1
Kirusi Ọba pàṣẹ pé kí Àwọn Juu Pada
1LI ọdun ekini Kirusi, ọba Persia, ki ọ̀rọ OLUWA lati ẹnu Jeremiah wá ki o le ṣẹ, OLUWA rú ẹmi Kirusi, ọba Persia soke, ti o mu ki a kede yi gbogbo ijọba rẹ̀ ka, a si kọwe rẹ̀ pẹlu wipe,
2Bayi ni Kirusi ọba Persia wi pe, OLUWA, Ọlọrun ọrun, ti fi gbogbo ijọba aiye fun mi; o si ti pa a li aṣẹ lati kọ ile fun on ni Jerusalemu ti o wà ni Juda.
3Tani ninu nyin ninu gbogbo enia rẹ̀? ki Ọlọrun rẹ̀ ki o wà pẹlu rẹ̀, ki o si goke lọ si Jerusalemu, ti o wà ni Juda, ki o si kọ ile OLUWA Ọlọrun Israeli, on li Ọlọrun, ti o wà ni Jerusalemu.
4Ati ẹnikẹni ti o kù lati ibikibi ti o ti ngbe, ki awọn enia ibugbe rẹ̀ ki o fi fadaka ràn a lọwọ, pẹlu wura, ati pẹlu ẹrù, ati pẹlu ẹran-ọ̀sin, pẹlu ọrẹ atinuwa fun ile Ọlọrun ti o wà ni Jerusalemu.
5Nigbana ni awọn olori awọn baba Juda ati Benjamini dide, ati awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, pẹlu gbogbo awọn ẹniti Ọlọrun rú ẹmi wọn soke, lati goke lọ, lati kọ́ ile OLUWA ti o wà ni Jerusalemu.
6Gbogbo awọn ti o wà li agbegbe wọn si fi ohun-èlo fadaka ràn wọn lọwọ, pẹlu wura, pẹlu ẹrù ati pẹlu ẹran-ọ̀sin, ati pẹlu ohun iyebiye, li aika gbogbo ọrẹ atinuwa.
7Kirusi ọba si ko ohun èlo ile OLUWA jade, ti Nebukadnessari ti ko jade lọ lati Jerusalemu, ti o si fi sinu ile ọlọrun rẹ̀;
8Kirusi ọba Persia si ko wọnyi jade nipa ọwọ Mitredati, oluṣọ iṣura, o si ka iye wọn fun Ṣeṣbassari (Serubbabeli) bãlẹ Juda.
9Iye wọn si li eyi: ọgbọn awo-pọ̀kọ wura, ẹgbẹrun awo-pọ̀kọ fadaka, ọbẹ mọkandilọgbọn,
10Ọgbọn ago wura, ago fadaka iru ekeji, irinwo o le mẹwa, ohun èlo miran si jẹ ẹgbẹrun.
11Gbogbo ohun-èlo wura ati ti fadaka jẹ ẹgbẹtadilọgbọn. Gbogbo wọnyi ni Ṣeṣbassari mu goke wá pẹlu awọn igbekun ti a mu goke lati Babiloni wá si Jerusalemu.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Esr 1: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: