Esr 5

5
Iṣẹ́ Kíkọ́ Tẹmpili Tún Bẹ̀rẹ̀
1ṢUGBỌN awọn woli, Haggai woli, ati Sekariah ọmọ Iddo, sọ asọtẹlẹ fun awọn Ju ti o wà ni Juda ati Jerusalemu li orukọ Ọlọrun Israeli.
2Li akoko na ni Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli, ati Jeṣua ọmọ Josadaki dide, nwọn si bẹ̀rẹ si ikọ́ ile Ọlọrun ni Jerusalemu; awọn woli Ọlọrun si wà pẹlu wọn ti nràn wọn lọwọ.
3Li akoko kanna ni Tatnai, bãlẹ ni ihahin odò, ati Ṣetar-bosnai pẹlu awọn ẹgbẹ wọn, wá si ọdọ wọn, nwọn si wi fun wọn bayi pe, Tani fun nyin li aṣẹ lati kọ́ ile yi, ati lati tun odi yi ṣe?
4Nigbana ni awa wi fun wọn bayi, pe, Orukọ awọn ọkunrin ti nkọ́ ile yi ti ijẹ?
5Ṣugbọn oju Ọlọrun wọn mbẹ li ara awọn àgba Juda, ti nwọn kò fi le mu wọn ṣiwọ titi ọ̀ran na fi de ọdọ Dariusi: nigbana ni nwọn si fi èsi pada, nipa iwe nitori eyi.
6Atunkọ iwe da ti Tatnai, bãlẹ ni ihahin-odò, ati Ṣetar-bosnai, ati awọn ẹgbẹ rẹ̀ rán si Dariusi ọba: awọn ara Afarsaki ti ihahin-odò.
7Nwọn fi iwe ranṣẹ si i, ninu eyiti a kọ bayi; Si Dariusi, ọba, alafia gbogbo.
8Ki ọba ki o mọ̀ pe, awa lọ si igberiko Judea si ile Ọlọrun ẹniti o tobi, ti a fi okuta nlanla kọ, a si tẹ igi si inu ogiri na, iṣẹ yi nlọ siwaju kánkán, o si nṣe rere li ọwọ wọn.
9Nigbana ni awa bi awọn àgba wọnni li ère, a si wi fun wọn bayi pe, Tani fun nyin li aṣẹ lati kọ́ ile yi, ati lati mọ odi yi?
10Awa si bère orukọ wọn pẹlu, lati mu ki o da ọ li oju, ki a le kọwe orukọ awọn enia ti iṣe olori ninu wọn.
11Bayi ni nwọn si fi èsi fun wa wipe, Iranṣẹ Ọlọrun ọrun on aiye li awa iṣe, awa si nkọ́ ile ti a ti kọ́ li ọdun pupọ wọnyi sẹhin, ti ọba nla kan ni Israeli ti kọ́, ti o si ti pari.
12Ṣugbọn nitoriti awọn baba wa mu Ọlọrun ọrun binu, o fi wọn le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babiloni ti Kaldea, ẹniti o wó ile yi palẹ, ti o si kó awọn enia na lọ si Babiloni.
13Ṣugbọn li ọdun ekini Kirusi ọba Babiloni, Kirusi ọba na fi aṣẹ lelẹ lati kọ́ ile Ọlọrun yi.
14Pẹlupẹlu ohun èlo wura ati ti fàdaka ti ile Ọlọrun ti Nebukadnessari ko lati inu tempili ti o wà ni Jerusalemu jade, ti o si mu lọ sinu tempili Babiloni, awọn na ni Kirusi ọba ko lati inu tempili Babiloni jade, a si fi wọn le ẹnikan lọwọ, orukọ ẹniti ijẹ Ṣeṣbassari, ẹniti on fi jẹ bãlẹ;
15On si wi fun u pe, Kó ohun èlo wọnyi lọ, ki o fi wọn si inu tempili ti o wà ni Jerusalemu, ki o si mu ki a tun kọ ile Ọlọrun yi si ipò rẹ̀.
16Nigbana ni Ṣeṣbassari na wá, o si fi ipilẹ ile Ọlọrun ti o wà ni Jerusalemu lelẹ: ati lati igba na ani titi di isisiyi li o ti mbẹ, ni kikọ kò si ti ipari tan.
17Njẹ nitorina, bi o ba wu ọba, jẹ ki a wá inu ile iṣura ọba ti o wà nibẹ ni Babiloni, bi o ba ri bẹ̃, pe Kirusi ọba fi aṣẹ lelẹ lati kọ ile Ọlọrun yi ni Jerusalemu, ki ọba ki o sọ eyi ti o fẹ fun wa nipa ọ̀ran yi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Esr 5: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀