Gẹn 3:7-9

Gẹn 3:7-9 YBCV

Oju awọn mejeji si là, nwọn si mọ̀ pe nwọn wà ni ìhoho; nwọn si gán ewe ọpọtọ pọ̀, nwọn si dá ibantẹ fun ara wọn. Nwọn si gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun, o nrìn ninu ọgbà ni itura ọjọ́: Adamu ati aya rẹ̀ si fi ara wọn pamọ́ kuro niwaju OLUWA Ọlọrun lãrin igi ọgbà. OLUWA Ọlọrun si kọ si Adamu, o si wi fun u pe, Nibo ni iwọ wà?