Hag 1
1
OLUWA pàṣẹ láti tún Tẹmpili Kọ́
1LI ọdun keji Dariusi ọba, li oṣù kẹfa, li ọjọ ekini oṣù na, ọ̀rọ Oluwa wá, nipa ọwọ Hagai woli, sọdọ Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli, bãlẹ Juda, ati sọdọ Joṣua ọmọ Josedeki, olori alufa, wipe,
2Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Awọn enia wọnyi nsọ pe, Akokò kò ti ide, akokò ti a ba fi kọ́ ile Oluwa.
3Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa wá nipa Hagai woli, wipe,
4Akokò ha ni fun nyin, ẹnyin, lati ma gbe ile ọṣọ nyin, ṣugbọn ile yi wà li ahoro?
5Njẹ nisisiyi bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, Ẹ kiyesi ọ̀na nyin.
6Ẹnyin ti fọ́n irugbin pupọ̀, ẹ si mu diẹ wá ile; ẹnyin njẹ, ṣugbọn ẹnyin kò yo: ẹnyin nmu, ṣugbọn kò tẹ nyin lọrun; ẹnyin mbora, ṣugbọn kò si ẹniti o gboná; ẹniti o si ngbowo ọ̀ya ńgbà a sinu ajadi àpo.
7Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: Ẹ kiyesi ọ̀na nyin.
8Ẹ gùn ori oke-nla lọ, ẹ si mu igi wá, ki ẹ si kọ́ ile na; inu mi yio si dùn si i, a o si yìn mi logo, li Oluwa wi.
9Ẹnyin tí nreti ọ̀pọ, ṣugbọn kiyesi i, diẹ ni; nigbati ẹnyin si mu u wá ile, mo si fẹ ẹ danù. Nitori kini? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Nitori ti ile mi ti o dahoro; ti olukuluku nyin si nsare fun ile ara rẹ̀.
10Nitorina ni a ṣe dá ìri ọrun duro lori nyin, a si da eso ilẹ duro.
11Mo si ti pè ọdá sori ilẹ, ati sori oke-nla, ati sori ọkà ati sori ọti-waini titún, ati sori ororo, ati sori ohun ti ilẹ mu jade, ati sori enia, ati sori ẹran, ati sori gbogbo iṣẹ ọwọ ẹni.
Àwọn Eniyan náà gbọ́ràn sí Àṣẹ OLUWA
12Nigbana ni Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli, ati Joṣua ọmọ Josedeki, olori alufa, pẹlu gbogbo enia iyokù, gba ohùn Oluwa Ọlọrun wọn gbọ́, ati ọ̀rọ Hagai woli, gẹgẹ bi Oluwa Ọlọrun wọn ti rán a, awọn enia si bẹ̀ru niwaju Oluwa.
13Nigbana ni Hagai iranṣẹ Oluwa jiṣẹ Oluwa fun awọn enia pe, Emi wà pẹlu nyin, li Oluwa wi.
14Oluwa si rú ẹ̀mi Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli, bãlẹ Juda soke, ati ẹmi Joṣua ọmọ Josedeki, olori alufa, ati ẹmi gbogbo awọn enia iyokù; nwọn si wá nwọn si ṣiṣẹ ni ile Oluwa awọn ọmọ-ogun Ọlọrun wọn.
15Li ọjọ kẹrinlelogun oṣù kẹfà, li ọdun keji Dariusi ọba.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Hag 1: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: