Isa 21
21
Ìran nípa Ìṣubú Babiloni
1Ọ̀RỌ-ìmọ niti ijù okun. Gẹgẹ bi ãja gusù ti ikọja lọ; bẹ̃ni o ti ijù wá, lati ilẹ ti o li ẹ̀ru.
2Iran lile li a fi hàn mi; ọ̀dalẹ dalẹ, akoni si nkoni. Goke lọ, iwọ Elamu: dotì, iwọ Media; gbogbo ìmí-ẹ̀dùn inu rẹ̀ li emi ti mu da.
3Nitorina ni ẹgbẹ́ mi ṣe kun fun irora: irora si ti dì mi mu, gẹgẹ bi irora obinrin ti nrọbi: emi tẹ̀ ba nigbati emi gbọ́ ọ: emi dãmu nigbati emi ri i.
4Ọkàn mi nrò, ẹ̀ru dẹrùba mi: oru ayọ̀ mi li o ti sọ di ìbẹru fun mi.
5Pèse tabili silẹ, yàn alore, jẹ, mu: dide, ẹnyin ọmọ-alade, ẹ kùn asà nyin.
6Nitori bayi li Oluwa ti sọ fun mi, Lọ, fi ẹnikan ṣọ ọ̀na, jẹ ki o sọ ohun ti o ri.
7O si ri kẹkẹ́ pẹlu ẹlẹṣin meji-meji, kẹkẹ́ kẹtẹkẹtẹ, kẹkẹ́ ibakasiẹ; o si farabalẹ̀ tẹtilelẹ gidigidi:
8On si kigbe pe, kiniun kan: Oluwa mi, nigbagbogbo li emi nduro lori ile-iṣọ li ọsan, a si fi mi si iṣọ mi ni gbogbo oru:
9Si kiyesi i, kẹkẹ́ enia kan ni mbọ̀ wá yi, pẹlu ẹlẹṣin meji-meji. On si dahun, o si wipe, Babiloni ṣubu, o ṣubu; ati gbogbo ere fifin òriṣa rẹ̀ li o wó mọlẹ.
10Iwọ ìpaka mi, ati ọkà ilẹ ìpaka mi: eyi ti emi ti gbọ́ lọdọ Oluwa awọn ọmọ-ọgun, Ọlọrun Israeli li emi ti sọ fun ọ.
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Edomu
11Ọ̀rọ-ìmọ niti Duma. O ké si mi lati Seiri wá, Oluṣọ́, oru ti ri? Oluṣọ́ oru ti ri?
12Oluṣọ́ wipe, ilẹ nmọ́ bọ̀, alẹ si nlẹ pẹlu: bi ẹnyin o ba bere, ẹ bere: ẹ pada, ẹ wá.
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Arabia
13Ọ̀rọ-ìmọ niti Arabia. Ninu igbó Arabia li ẹnyin o wọ̀, ẹnyin ẹgbẹ́-erò Dedanimu.
14Awọn olugbé ilẹ Tema bù omi wá fun ẹniti ongbẹ ngbẹ, onjẹ wọn ni nwọn fi ṣaju ẹniti nsalọ.
15Nitori nwọn nsá fun idà, fun idà fifayọ, ati fun ọrun kikàn, ati fun ibinujẹ ogun.
16Nitori bayi li Oluwa ti sọ fun mi, ki ọdun kan to pe, gẹgẹ bi ọdun alagbaṣe, gbogbo ogo Kedari yio wọ̀.
17Iyokù ninu iye awọn tafàtafà, awọn alagbara ninu awọn ọmọ Kedari yio dinkù: nitori Oluwa Ọlọrun Israeli ti wi i.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Isa 21: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: