Isa 42
42
Iranṣẹ Ọlọrun
1WÒ iranṣẹ mi, ẹniti mo gbéro: ayànfẹ mi, ẹniti inu mi dùn si; mo ti fi ẹmi mi fun u: on o mu idajọ wá fun awọn keferi.
2On kì yio kigbé, bẹ̃ni kì yio gbé ohùn soke, bẹ̃ni kì yio jẹ ki a gbọ́ ohùn rẹ̀ ni igboro.
3Iyè fifọ́ ni on ki yio ṣẹ, owú ti nrú ẹ̃fin ni on kì yio pa: yio mu idajọ wá si otitọ.
4Ãrẹ̀ kì yio mú u, a kì yio si daiyà fò o, titi yio fi gbé idajọ kalẹ li aiye, awọn erekùṣu yio duro de ofin rẹ̀.
5Bayi ni Ọlọrun Oluwa wi, ẹniti o dá ọrun, ti o si nà wọn jade; ẹniti o tẹ̀ aiye, ati ohun ti o ti inu rẹ̀ wá; ẹniti o fi ẽmi fun awọn enia lori rẹ̀, ati ẹmi fun awọn ti o nrin ninu rẹ̀:
6Emi Oluwa li o ti pè ọ ninu ododo, emi o si di ọwọ́ rẹ mu, emi o si pa ọ mọ, emi o si fi ọ ṣe majẹmu awọn enia, imọlẹ awọn keferi.
7Lati là oju awọn afọju, lati mu awọn ondè kuro ninu tubu, ati awọn ti o joko li okùnkun kuro ni ile tubu.
8Emi li Oluwa: eyi ni orukọ mi: ogo mi li emi kì yio fi fun ẹlòmiran, bẹ̃ni emi kì yio fi iyìn mi fun ere gbigbẹ́.
9Kiyesi i, nkan iṣãju ṣẹ, nkan titun ni emi si nsọ: ki nwọn to hù, mo mu nyin gbọ́ wọn.
Orin Ìyìn fún OLUWA
10Ẹ kọ orin titun si Oluwa, iyìn rẹ̀ lati opin aiye, ẹnyin ti nsọkalẹ lọ si okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀: erekùṣu, ati awọn ti ngbé inu wọn.
11Jẹ ki aginjù ati ilu-nla ibẹ gbé ohùn wọn soke, iletò wọnni ti Kedari ngbé: jẹ ki awọn ti ngbé apáta kọrin, jẹ ki wọn hó lati ori oke-nla wá.
12Jẹ ki wọn fi ogo fun Oluwa, ki wọn si wi iyìn rẹ̀ ninu erekùṣu.
13Oluwa yio jade bi ọkunrin alagbara, yio rú owú soke bi ologun: yio kigbé, nitõtọ, yio ké ramuramu; yio bori awọn ọta rẹ̀.
Ọlọrun ṣe Ìlérí láti Ran Àwọn Eniyan Rẹ̀ lọ́wọ́
14Lailai ni mo ti dakẹ́: mo ti gbe jẹ, mo ti pa ara mi mọra; nisisiyi emi o ké bi obinrin ti nrọbi; emi o parun, emi o si gbé mì lẹ̃kanna.
15Emi o sọ oke-nla ati òke-kékèké di ofo, emi o si mú gbogbo ewebẹ̀ wọn gbẹ: emi o sọ odò ṣiṣàn di iyangbẹ́ ilẹ, emi o si mú abàta gbẹ.
16Emi o si mu awọn afọju bá ọ̀na ti nwọn kò mọ̀ wá; emi o tọ́ wọn ninu ipa ti wọn kò ti mọ̀; emi o sọ okùnkun di imọlẹ niwaju wọn, ati ohun wiwọ́ di titọ. Nkan wọnyi li emi o ṣe fun wọn, emi kì yio si kọ̀ wọn silẹ.
17A o dá awọn ti o gbẹkẹle ere gbigbẹ́ padà, a o doju tì wọn gidigidi, awọn ti nwi fun ere didà pe, Ẹnyin ni ọlọrun wa.
Israẹli Kùnà láti Kẹ́kọ̀ọ́
18Gbọ́, ẹnyin aditi; ki ẹ si wò, ẹnyin afọju ki ẹnyin ki o le ri i.
19Tani afọju, bikoṣe iranṣẹ mi? tabi aditi, bi ikọ̀ mi ti mo rán? tani afọju bi ẹni pipé? ti o si fọju bi iranṣẹ Oluwa?
20Ni riri nkan pupọ, ṣugbọn iwọ kò kiyesi i; ni ṣiṣi eti, ṣugbọn on ko gbọ́.
21Inu Oluwa dùn gidigidi nitori ododo rẹ̀; yio gbe ofin ga, yio si sọ ọ di ọlọlá.
22Ṣugbọn enia ti a jà lole ti a si ko li ẹrù ni eyi: gbogbo wọn li a dẹkùn mu ninu ihò, a fi wọn pamọ ninu tubu: a fi wọn fun ikogun, ẹnikan ko si gbà wọn; a fi wọn fun ikogun, ẹnikan ko si wipe, Mu u pada.
23Tani ninu nyin ti o fi eti si eyi? ti o dẹti silẹ, ti yio si gbọ́ eyi ti mbọ̀ lẹhin?
24Tani fi Jakobu fun ikogun, ti o si fi Israeli fun ole? Oluwa ha kọ́ ẹniti a ti dẹṣẹ si? nitori nwọn kò fẹ rìn li ọ̀na rẹ̀, bẹ̃ni nwọn ko gbọ́ ti ofin rẹ̀.
25Nitorina ni o ṣe dà irúnu ibinu rẹ̀ si i lori, ati agbara ogun: o si ti tẹ̀ iná bọ̀ ọ yika, ṣugbọn on kò mọ̀; o si jo o, ṣugbọn on kò kà a si.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Isa 42: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: