Isa 5
5
Orin Ọgbà Àjàrà
1NISISIYI, emi o kọ orin si olufẹ ọwọ́n mi, orin olùfẹ mi ọwọ́n niti ọ̀gba àjara rẹ̀. Olufẹ ọwọ́n mi ni ọ̀gba àjara lori okè ẹlẹtù loju:
2O si sọ ọ̀gba yi i ka, o si ṣà okuta kuro ninu rẹ̀, o si gbìn ayànfẹ àjara si inu rẹ̀, o si kọ ile iṣọ sãrin rẹ̀, o si ṣe ifunti sinu rẹ̀ pẹlu: o si wò pe ki o so eso, ṣugbọn eso kikan li o so.
3Njẹ nisisiyi, ẹnyin ara Jerusalemu ati ẹnyin ọkunrin Juda, emi bẹ̀ nyin, ṣe idajọ lãrin mi, ati lãrin ọ̀gba àjara mi.
4Kini a ba ṣe si ọ̀gba àjara mi ti emi kò ti ṣe ninu rẹ̀, nigbati mo wò pe iba so eso, ẽṣe ti o fi so eso kikan?
5Njẹ nisisiyi, ẹ wá na, emi o sọ ohun ti emi o ṣe si ọ̀gba àjara mi fun nyin: emi o mu ọ̀gba rẹ̀ kuro, a o si jẹ ẹ run, emi o wo ogiri rẹ̀ lu ilẹ, a o si tẹ̀ ẹ mọlẹ.
6Emi o si sọ ọ di ahoro, a kì yio tọ́ ẹka rẹ̀, bẹ̃ni a kì yio wà a, ṣugbọn ẹ̀wọn ati ẹ̀gún ni yio ma hù nibẹ, emi o si paṣẹ fun awọsanma ki o má rọjò sori rẹ̀.
7Nitori ọ̀gba àjara Oluwa awọn ọmọ-ogun ni ile Israeli, ati awọn ọkunrin Juda ni igi-gbìgbin ti o wù u, o reti idajọ, ṣugbọn kiyesi i, inilara; o si reti ododo; ṣugbọn kiyesi i, igbe.
Ìwà Burúkú Eniyan
8Egbe ni fun awọn ti o ni ile kún ile, ti nfi oko kún oko, titi ãyè kò fi si mọ, ki nwọn bà le nikan wà li ãrin ilẹ aiye!
9Li eti mi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun sọ pe, Nitõtọ ọ̀pọ ile ni yio di ahoro, ile nla ati daradara laisi olugbe.
10Nitõtọ ìwọn akeri mẹwa ọ̀gba àjara yio mu òṣuwọn bati kan wá, ati òṣuwọn irugbìn homeri kan yio mu òṣuwọn efa kan wá.
11Egbe ni fun awọn ti ima dide ni kùtukutu, ki nwọn le ma lepa ọti lile; ti nwọn wà ninu rẹ̀ titi di alẹ, titi ọti-waini mu ara wọn gbona!
12Ati durù, ati fioli, tabreti, ferè, ati ọti-waini wà ninu àse wọn: ṣugbọn nwọn kò kà iṣẹ Oluwa si, bẹ̃ni nwọn kò rò iṣẹ ọwọ́ rẹ̀.
13Nitorina awọn enia mi lọ si oko-ẹrú, nitoriti oye kò si, awọn ọlọla wọn di rirù, ati ọ̀pọlọpọ wọn gbẹ fun orùngbẹ.
14Nitorina ipò-òkú ti fun ara rẹ̀ li àye, o si là ẹnu rẹ̀ li aini ìwọn: ati ogo wọn, ati ọ̀pọlọpọ wọn, ati ọṣọ́ wọn, ati awọn ẹniti nyọ̀, yio sọkalẹ sinu rẹ̀.
15Enia lasan li a o rẹ̀ silẹ, ati ẹni-alagbara li a o rẹ̀ silẹ, oju agberaga li a o si rẹ̀ silẹ.
16Ṣugbọn Oluwa awọn ọmọ-ogun li a o gbe ga ni idajọ, ati Ọlọrun Ẹni-Mimọ́ yio jẹ mimọ́ ninu ododo.
17Nigbana li awọn ọdọ-agutan yio ma jẹ̀ gẹgẹ bi iṣe wọn, ati ibi ahoro awọn ti o sanra li awọn alejò yio ma jẹ.
18Egbe ni fun awọn ti nfi ohun asan fà ìwa buburu, ati awọn ti o dabi ẹnipe nfi okùn kẹkẹ́ fà ẹ̀ṣẹ.
19Awọn ti o wipe, Jẹ ki o yara, ki o si mu iṣẹ rẹ̀ yara, ki awa ki o le ri i: ati jẹ ki ìmọ Ẹni-Mimọ́ Israeli sunmọ ihin, ki o si wá, ki awa ki o le mọ̀ ọ.
20Egbe ni fun awọn ti npè ibi ni rere, ati rere ni ibi, ti nfi okùnkun ṣe imọlẹ, ati imọlẹ ṣe okùnkun: ti nfi ikorò pe adùn, ati adùn pe ikorò!
21Egbe ni fun awọn ti nwọn gbọ́n li oju ara wọn, ti nwọn si mọ̀ oye li oju ara wọn!
22Egbe ni fun awọn ti o ni ipá lati mu ọti-waini, ati awọn ọkunrin alagbara lati ṣe adàlu ọti lile:
23Awọn ẹniti o da are fun ẹni-buburu nitori ère, ti nwọn si mu ododo olododo kuro li ọwọ́ rẹ̀.
24Nitorina bi iná ti ijo akekù koriko run, ti ọwọ́ iná si ijo iyàngbo; bẹ̃ni egbò wọn yio da bi rirà; itanna wọn yio si gòke bi ekuru; nitori nwọn ti ṣá ofin Oluwa awọn ọmọ-ogun tì, nwọn si ti gàn ọ̀rọ Ẹni-Mimọ Israeli.
25Nitorina ni ibinu Oluwa fi ràn si enia rẹ̀, o si ti na ọwọ́ rẹ̀ si wọn, o si ti lù wọn: awọn òke si warìri, okú wọn si wà bi igbẹ li ãrin igboro. Ni gbogbo eyi ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ.
26Yio si gbe ọpágun soke si awọn orilẹ-ède ti o jìna, yio si kọ si wọn lati opin ilẹ wá, si kiyesi i, nwọn o yara wá kánkán.
27Kò si ẹniti yio rẹ̀, tabi ti yio kọsẹ ninu wọn, kò si ẹniti yio tõgbe tabi ti yio sùn: bẹ̃ni amùre ẹgbẹ wọn kì yio tu, bẹ̃ni okùn bàta wọn kì yio ja.
28Awọn ẹniti ọfà wọn mu, ti gbogbo ọrun wọn si kàn, a o ka patakò ẹsẹ ẹṣin wọn si okuta akọ, ati kẹkẹ́ wọn bi ãja.
29Kike wọn yio dabi ti kiniun, nwọn o ma ke bi awọn ọmọ kiniun, nitõtọ nwọn o ma ke, nwọn o si di ohun ọdẹ na mu, nwọn a si gbe e lọ li ailewu, kò si ẹnikan ti yio gbà a.
30Ati li ọjọ na nwọn o ho si wọn, bi hiho okun: bi ẹnikan ba si wo ilẹ na, kiyesi i, okùnkun ati ipọnju, imọlẹ si di okùnkun ninu awọsanma dudu rẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Isa 5: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: