ẸMI Oluwa Jehofah mbẹ lara mi: nitori o ti fi ami ororo yàn mi lati wãsu ihin-rere fun awọn òtoṣi; o ti rán mi lati ṣe awotán awọn onirobinujẹ ọkàn, lati kede idasilẹ fun awọn igbekùn, ati iṣisilẹ tubu fun awọn ondè. Lati kede ọdun itẹwọgba Oluwa, ati ọjọ ẹsan Ọlọrun wa; lati tù gbogbo awọn ti ngbãwẹ̀ ninu. Lati yàn fun awọn ti nṣọ̀fọ fun Sioni, lati fi ọṣọ́ fun wọn nipo ẽrú, ororo ayọ̀ nipo ọ̀fọ, aṣọ iyìn nipo ẹmi ibanujẹ, ki a le pè wọn ni igi ododo, ọgbìn Oluwa, ki a le yìn i logo.
Kà Isa 61
Feti si Isa 61
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Isa 61:1-3
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò