Jak 5

5
Ìkìlọ̀ fún Àwọn Ọlọ́rọ̀
1Ẹ wá nisisiyi, ẹnyin ọlọrọ̀, ẹ mã sọkun ki ẹ si mã pohunréré ẹkun nitori òṣi ti mbọ̀wá ta nyin.
2Ọrọ̀ nyin dibajẹ, kòkoro si ti jẹ̀ aṣọ nyin.
3Wura on fadaka nyin diparà; iparà wọn ni yio si ṣe ẹlẹri si nyin, ti yio si jẹ ẹran ara nyin bi iná. Ẹnyin ti kó iṣura jọ dè ọjọ ikẹhin.
4Kiyesi i, ọ̀ya awọn alagbaṣe ti nwọn ti ṣe ikore oko nyin, eyiti ẹ kò san, nke rara; ati igbe awọn ti o ṣe ikore si ti wọ inu eti Oluwa awọn ọmọ-ogun.
5Ẹnyin ti jẹ adùn li aiye, ẹnyin si ti fi ara nyin fun aiye jijẹ; ẹnyin ti bọ́ li ọjọ pipa.
6Ẹnyin ti da ẹbi fun olododo, ẹ si ti pa a; on kò kọ oju ija si nyin.
Sùúrù ati Adura
7Nitorina ará, ẹ mu sũru titi di ipadawa Oluwa. Kiyesi i, àgbẹ a mã reti eso iyebiye ti ilẹ, a si mu sũru de e, titi di igbà akọrọ̀ ati arọ̀kuro òjo.
8Ẹnyin pẹlu ẹ mu sũru; ẹ fi ọkàn nyin balẹ̀: nitori ipadawa Oluwa kù si dẹdẹ.
9Ẹ máṣe kùn si ọmọnikeji nyin, ará, ki a má bã dá nyin lẹbi: kiyesi i, onidajọ duro li ẹnu ilẹkun.
10Ará mi, ẹ fi awọn woli ti o ti nsọ̀rọ li orukọ Oluwa ṣe apẹrẹ ìya jijẹ, ati sũru.
11Sawò o, awa a mã kà awọn ti o farada ìya si ẹni ibukún. Ẹnyin ti gbọ́ ti sũru Jobu, ẹnyin si ri igbẹhin ti Oluwa ṣe; pe Oluwa kún fun iyọ́nu, o si ni ãnu.
12Ṣugbọn jù ohun gbogbo lọ, ará mi, ẹ máṣe búra, iba ṣe ifi ọrun búra, tabi ilẹ, tabi ibura-kibura miran: ṣugbọn jẹ ki bẹ̃ni nyin jẹ bẹ̃ni; ati bẹ̃kọ nyin jẹ bẹ̃kọ; ki ẹ má bã bọ́ sinu ẹbi.
13Inu ẹnikẹni ha bajẹ ninu nyin bi? jẹ ki o gbadura. Inu ẹnikẹni ha dùn? jẹ ki o kọrin mimọ́.
14Ẹnikẹni ṣe aisan ninu nyin bi? ki o pè awọn àgba ijọ, ki nwọn si gbadura sori rẹ̀, ki nwọn fi oróro kùn u li orukọ Oluwa:
15Adura igbagbọ́ yio si gbà alaisan na là, Oluwa yio si gbé e dide; bi o ba si ṣe pe o ti dẹ̀ṣẹ, a o dari jì i.
16Ẹ jẹwọ ẹ̀ṣẹ nyin fun ara nyin, ki ẹ si mã gbadura fun ara nyin, ki a le mu nyin larada. Iṣẹ ti adura olododo nṣe li agbara pupọ.
17Enia oniru ìwa bi awa ni Elijah, o gbadura gidigidi pe ki ojo ki o máṣe rọ̀, ojo kò si rọ̀ sori ilẹ fun ọdún mẹta on oṣù mẹfa.
18O si tún gbadura, ọrun si tún rọ̀jo, ilẹ si so eso rẹ̀ jade.
19Ará, bi ẹnikẹni ninu nyin ba ṣìna kuro ninu otitọ, ti ẹnikan si yi i pada;
20Jẹ ki o mọ̀ pe, ẹniti o ba yi ẹlẹṣẹ kan pada kuro ninu ìṣina rẹ̀, yio gbà ọkàn kan là kuro lọwọ ikú, yio si bò ọ̀pọlọpọ ẹ̀ṣẹ mọlẹ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Jak 5: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀