A. Oni 18
18
Mika ati Ẹ̀yà Dani
1LI ọjọ́ wọnni ọba kan kò sí ni Israeli: ati li ọjọ́ wọnni ẹ̀ya Dani nwá ilẹ-iní kan lati joko si; nitoripe titi o fi di ọjọ́ na, ilẹ-iní wọn lãrin awọn ẹ̀ya Israeli kò ti ibọ́ si ọwọ́ wọn.
2Awọn ọmọ Dani si rán ọkunrin marun ninu idile wọn lati àgbegbe wọn wá, awọn ọkunrin alagbara, lati Sora, ati Eṣtaolu lọ, lati lọ ṣe amí ilẹ na, ati lati rìn i wò; nwọn si wi fun wọn pe, Ẹ lọ rìn ilẹ na wò: nwọn si dé ilẹ òke Efraimu, si ile Mika, nwọn si wọ̀ nibẹ̀.
3Nigbati nwọn wà leti ile Mika, nwọn si mọ̀ ohùn ọmọkunrin Lefi na: nwọn si wọ̀ inu ile na, nwọn si wi fun u pe, Tali o mú ọ wá ihinyi? kini iwọ si nṣe ni ihinyi? kini iwọ si ní nihin?
4On si wi fun wọn pe, Bayibayi ni Mika ṣe fun mi, o gbà mi si iṣẹ, alufa rẹ̀ li emi si iṣe.
5Nwọn si wi fun u pe, Bère lọdọ Ọlọrun, awa bẹ̀ ọ, ki awa ki o le mọ̀ bi ọ̀na wa ti awa nlọ yio jasi rere.
6Alufa na si wi fun wọn pe, Ẹ ma lọ li alafia: ọ̀na nyin ti ẹnyin nlọ mbẹ niwaju OLUWA.
7Nigbana li awọn ọkunrin mararun na lọ, nwọn si dé Laiṣi, nwọn si ri awọn enia ti o wà ninu rẹ̀, bi nwọn ti joko laibẹ̀ru, gẹgẹ bi iṣe awọn ara Sidoni, ni ijokojẹ ati laibẹ̀ru; kò si sí olori kan ni ilẹ na, ti iba mu oju tì wọn li ohunkohun, nwọn si jìna si awọn ara Sidoni, nwọn kò si ba ẹnikẹni ṣe.
8Nwọn si wá sọdọ awọn arakunrin wọn si Sora ati Eṣtaolu: awọn arakunrin wọn si wi fun wọn pe, Kili ẹnyin wi?
9Nwọn si wipe, Ẹ dide, ki awa ki o tọ̀ wọn: nitoriti awa ri ilẹ na, si kiyesi i, o dara gidigidi: ẹ dakẹ ni? ẹ má ṣe lọra lati lọ, ati lati wọ̀ ibẹ̀ lọ gbà ilẹ na.
10Nigbati ẹnyin ba lọ, ẹnyin o dé ọdọ awọn enia ti o wà laibẹ̀ru, ilẹ na si tobi: nitoriti Ọlọrun ti fi i lé nyin lọwọ; ibiti kò sí ainí ohunkohun ti mbẹ lori ilẹ.
11Awọn enia idile Dani si ti ibẹ̀ lọ, lati Sora ati lati Eṣtaolu, ẹgbẹta ọkunrin ti o hamọra ogun;
12Nwọn si gòke lọ, nwọn si dó si Kiriati-jearimu, ni Juda: nitorina ni nwọn ṣe npè ibẹ̀ na ni Mahane-dani titi o fi di oni yi: kiyesi i, o wà lẹhin Kiriati-jearimu.
13Nwọn si kọja lati ibẹ̀ lọ si ilẹ òke Efraimu, nwọn si wá si ile Mika.
14Nigbana li awọn ọkunrin marun ti a rán ti o ti lọ ṣe amí ilẹ Laiṣi dahùn, nwọn si wi fun awọn arakunrin wọn pe, Ẹ mọ̀ pe efodu kan wà ninu ile wọnyi, ati terafimu, ati ere fifin, ati ere didà? njẹ nitorina ẹ rò eyiti ẹnyin o ṣe.
15Nwọn si yà sibẹ̀, nwọn si wá si ile ọmọkunrin Lefi na, ani si ile Mika, nwọn si bère alafia rẹ̀.
16Awọn ẹgbẹta ọkunrin ti o hamọra ogun ninu awọn ọmọ Dani, duro li ẹnu-ọ̀na.
17Awọn ọkunrin marun ti o ti lọ iṣe amí ilẹ na gòke lọ, nwọn si wá si ibẹ̀ na, nwọn si kó ere fifin, ati efodu, ati terafimu, ati ere didà na: alufa na si duro li ẹnu-ọ̀na pẹlu awọn ẹgbẹta ọkunrin ti o hamọra ogun.
18Nigbati awọn wọnyi si wọ̀ ile Mika lọ, nwọn si mú ere fifin, efodu, ati terafimu, ati ere didà na, nigbana li alufa na wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nṣe yi?
19Nwọn si wi fun u pe, Dakẹ, fi ọwọ́ rẹ lé ẹnu rẹ, ki o si ma bá wa lọ, ki o si ma ṣe baba fun wa ati alufa: o ha san fun ọ lati ṣe alufa fun ile ọkunrin kan, tabi ki iwọ ki o ṣe alufa fun ẹ̀ya ati idile kan ni Israeli?
20Inu alufa na si dùn, o si mú efodu, ati terafimu, ati ere fifin, o si bọ̀ sãrin awọn enia na.
21Bẹ̃ni nwọn yipada nwọn si lọ, nwọn tì awọn ọmọ kekere ati ẹran ati ẹrù siwaju wọn.
22Nigbati nwọn si lọ jìna si ile Mika, awọn ọkunrin ti o wà ninu ile wọnni ti o sunmọ ile Mika kó ara wọn jọ, nwọn si lé awọn ọmọ Dani bá.
23Nwọn si kọ si awọn ọmọ Dani. Nwọn si yi oju wọn pada, nwọn wi fun Mika pe, Kili o ṣe ọ, ti iwọ fi kó irú ẹgbẹ bẹ̃ lẹhin wá?
24On si wipe, Ẹnyin kó awọn oriṣa mi ti mo ṣe lọ, ẹ si mú alufa, ẹ si lọ, kini mo si tun ní? kili eyiti ẹnyin wi fun mi pe, Kili o ṣe ọ?
25Awọn ọmọ Dani si wi fun u pe, Máṣe jẹ ki a gbọ́ ohùn rẹ lãrin wa, ki awọn oninuṣùṣu ki o má bã kọlù nyin, iwọ a si sọ ẹmi rẹ nù, ati ẹmi awọn ara ile rẹ.
26Awọn ọmọ Dani si ba ọ̀na wọn lọ: nigbati Mika si ri i pe, nwọn lagbara jù on lọ, on si yipada, o si pada lọ sinu ile rẹ̀.
27Nwọn si kó awọn nkan wọnni ti Mika ṣe, ati alufa ti o ní, nwọn si wá si Laiṣi sọdọ awọn enia ti o wà ni ijokojẹ ati laibẹ̀ru, nwọn si fi oju idà kọlù wọn, nwọn si fi iná kun ilu na.
28Kò si sí olugbala, nitoriti o jìna si Sidoni, nwọn kò si bá ẹnikẹni ṣe; o si wà ni afonifoji ti o wà ni Beti-rehobu. Nwọn si kọ́ ilu na, nwọn si ngbé inu rẹ̀.
29Nwọn si pè orukọ ilu na ni Dani, gẹgẹ bi orukọ Dani baba wọn, ẹniti a bi fun Israeli: ṣugbọn Laiṣi li orukọ ilu na li atijọ rí.
30Awọn ọmọ Dani si gbé ere fifin na kalẹ: ati Jonatani, ọmọ Gerṣomu, ọmọ Mose, on ati awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin li o nṣe alufa fun ẹ̀ya Dani titi o fi di ọjọ́ ti a fi kó ilẹ na ni igbekun lọ.
31Nwọn si gbé ere fifin ti Mika ṣe kalẹ ni gbogbo ọjọ́ ti ile Ọlọrun fi wà ni Ṣilo.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
A. Oni 18: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: