Joh 8
8
Ìtàn Obinrin tí Ó Ṣe Àgbèrè
1JESU si lọ si ori òke Olifi.
2O si tún pada wá si tẹmpili ni kutukutu owurọ̀, gbogbo enia si wá sọdọ rẹ̀; o si joko, o nkọ́ wọn.
3Awọn akọwe ati awọn Farisi si mu obinrin kan wá sọdọ rẹ̀, ti a mu ninu panṣaga; nigbati nwọn si mu u duro larin,
4Nwọn wi fun u pe, Olukọni, a mu obinrin yi ninu panṣaga, ninu ṣiṣe e pãpã.
5Njẹ ninu ofin, Mose paṣẹ fun wa lati sọ iru awọn bẹ̃ li okuta pa: ṣugbọn iwọ ha ti wi?
6Eyini nwọn wi, nwọn ndán a wò, ki nwọn ba le ri ohun lati fi i sùn. Ṣugbọn Jesu bẹrẹ silẹ, o si nfi ika rẹ̀ kọwe ni ilẹ.
7Ṣugbọn nigbati nwọn mbi i lẽre sibẹsibẹ, o gbé ara rẹ̀ soke, o si wi fun wọn pe, Ẹniti o ba ṣe ailẹṣẹ ninu nyin, jẹ ki o kọ́ sọ okuta lù u.
8O si tún bẹ̀rẹ̀ silẹ, o nkọwe ni ilẹ.
9Nigbati nwọn gbọ eyi, nwọn si jade lọ lọkọ̃kan, bẹrẹ lati ọdọ awọn àgba titi de awọn ti o kẹhin; a si fi Jesu nikan silẹ, ati obinrin na lãrin, nibiti o ti wà.
10Jesu si gbé ara rẹ̀ soke, o si wi fun u pe, Obinrin yi, awọn dà? Kò si ẹnikan ti o da ọ lẹbi?
11O wipe, Kò si ẹnikan, Oluwa. Jesu si wi fun u pe, Bẹ̃li emi na kò da ọ lẹbi: mã lọ, lati igbayi lọ má dẹṣẹ̀ mọ́.
Jesu ni Ìmọ́lẹ̀ Ayé
12Jesu si tun sọ fun wọn pe, Emi ni imọlẹ aiye; ẹniti o ba tọ̀ mi lẹhin kì yio rìn ninu òkunkun, ṣugbọn yio ni imọlẹ ìye.
13Nitorina awọn Farisi wi fun u pe, Iwọ njẹri ara rẹ; ẹrí rẹ kì iṣe otitọ.
14Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Bi mo tilẹ njẹri fun ara mi, otitọ li ẹrí mi: nitoriti mo mọ̀ ibiti mo ti wá, mo si mọ̀ ibiti mo nlọ; ṣugbọn ẹnyin kò le mọ̀ ibiti mo ti wá, ati ibiti mo nlọ.
15 Ẹnyin nṣe idajọ nipa ti ara; emi kò ṣe idajọ ẹnikẹni.
16 Ṣugbọn bi emi ba si ṣe idajo, otitọ ni idajọ mi: nitori emi nikan kọ́, ṣugbọn emi ati Baba ti o rán mi.
17 Ẹ si kọ ọ pẹlu ninu ofin nyin pe, otitọ li ẹrí enia meji.
18 Emi li ẹniti njẹri ara mi, ati Baba ti o rán mi si njẹri fun mi.
19 Nitorina nwọn wi fun u pe, Nibo ni Baba rẹ wà? Jesu dahùn pe, Ẹnyin kò mọ̀ mi, bẹli ẹ kò mọ̀ Baba mi: ibaṣepe ẹnyin mọ̀ mi, ẹnyin iba si ti mọ̀ Baba mi pẹlu.
20Ọ̀rọ wọnyi ni Jesu sọ nibi iṣura, bi o ti nkọ́ni ni tẹmpili: ẹnikẹni ko si mu u; nitori wakati rẹ̀ ko ti ide.
Ta Ni Jesu?
21Nitorina o tun wi fun wọn pe, Emi nlọ, ẹnyin yio si wá mi, ẹ ó si kú ninu ẹ̀ṣẹ nyin: ibiti emi gbe nlọ, ẹnyin kì ó le wá.
22Nitorina awọn Ju wipe, On o ha pa ara rẹ̀ bi? nitoriti o wipe, Ibiti emi gbé nlọ, ẹnyin kì ó le wá.
23O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti isalẹ wá; emi ti oke wá: ẹnyin jẹ ti aiye yi; emi kì iṣe ti aiye yi.
24 Nitorina ni mo ṣe wi fun nyin pe, ẹ ó kú ninu ẹ̀ṣẹ nyin: nitori bikoṣepé ẹ ba gbagbọ́ pe, emi ni, ẹ ó kú ninu ẹ̀ṣẹ nyin.
25Nitorina nwọn wi fun u pe, Tani iwọ iṣe? Jesu si wi fun wọn pe, Ani eyinì ti mo ti wi fun nyin li àtetekọṣe.
26 Mo ni ohun pupọ̀ lati sọ, ati lati ṣe idajọ nipa nyin: ṣugbọn olõtọ li ẹniti o ran mi, ohun ti emi si ti gbọ lati ọdọ rẹ̀ wá, nwọnyi li emi nsọ fun araiye.
27Kò yé wọn pe, ti Baba li o nsọ fun wọn.
28Nitorina Jesu wi fun wọn pe, Nigbati ẹ ba gbé Ọmọ-enia soke, nigbana li ẹ o mọ̀ pe, emi ni, ati pe emi kò dá ohunkohun ṣe fun ara mi; ṣugbọn bi Baba ti kọ́ mi, emi nsọ nkan wọnyi.
29 Ẹniti o rán mi si mbẹ pẹlu mi: kò jọwọ emi nikan si; nitoriti emi nṣe ohun ti o wù u nigbagbogbo.
30Bi o ti nsọ nkan wọnyi, ọ̀pọ enia gbà a gbọ́.
Òtítọ́ yóo sọ Yín di Òmìnira
31Nitorina Jesu wi fun awọn Ju ti o gbà a gbọ́ pe, Bi ẹnyin ba duro ninu ọ̀rọ mi, nigbana li ẹnyin jẹ ọmọ-ẹhin mi nitõtọ.
32 Ẹ ó si mọ̀ otitọ, otitọ yio si sọ nyin di omnira.
33Nwọn da a lohùn wipe, Irú-ọmọ Abrahamu li awa iṣe, awa kò si ṣe ẹrú fun ẹnikẹni ri lai: iwọ ha ṣe wipe, Ẹ o di omnira?
34Jesu da wọn lohun pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba ndẹṣẹ, on li ẹrú ẹ̀ṣẹ.
35 Ẹrú kì si igbé ile titilai: Ọmọ ni igbe ile titilai.
36 Nitorina bi Ọmọ ba sọ nyin di omnira, ẹ ó di omnira nitõtọ.
37 Mo mọ̀ pe irú-ọmọ Abrahamu li ẹnyin iṣe; ṣugbọn ẹ nwá ọ̀na ati pa mi, nitori ọ̀rọ mi kò ri àye ninu nyin.
38 Ohun ti emi ti ri lọdọ Baba ni mo nsọ: ẹnyin pẹlu si nṣe eyi ti ẹnyin ti gbọ lati ọdọ baba nyin.
39Nwọn dahùn nwọn si wi fun u pe, Abrahamu ni baba wa. Jesu wi fun wọn pe, Ibaṣepe ọmọ Abrahamu li ẹnyin iṣe, ẹnyin iba ṣe iṣẹ Abrahamu.
40 Ṣugbọn nisisiyi ẹnyin nwá ọ̀na ati pa mi, ẹniti o sọ otitọ fun nyin, eyi ti mo ti gbọ́ lọdọ Ọlọrun: Abrahamu kò ṣe eyi.
41 Ẹnyin nṣe iṣẹ baba nyin. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, A ko bí wa nipa panṣaga: a ni Baba kan, eyini li Ọlọrun.
42Jesu wi fun wọn pe, Ibaṣepe Ọlọrun ni Baba nyin, ẹnyin iba fẹran mi: nitoriti emi ti ọdọ Ọlọrun jade, mo si wá: bẹ̃li emi kò si wá fun ara mi, ṣugbọn on li o rán mi.
43 Ẽtiṣe ti ède mi kò fi yé nyin? nitori ẹ ko le gbọ́ ọ̀rọ mi ni.
44 Ti eṣu baba nyin li ẹnyin iṣe, ifẹkufẹ baba nyin li ẹ si nfẹ ṣe. Apania li on iṣe lati atetekọṣe, ko si duro ni otitọ; nitoriti kò si otitọ ninu rẹ̀. Nigbati o ba nṣeke, ninu ohun tirẹ̀ li o nsọ, nitori eke ni, ati baba eke.
45 Ṣugbọn nitori emi sọ otitọ fun nyin, ẹ kò si gbà mi gbọ́.
46 Tani ninu nyin ti o ti idá mi li ẹbi ẹ̀ṣẹ? Bi mo ba nsọ otitọ ẽṣe ti ẹnyin kò fi gbà mi gbọ́?
47 Ẹniti iṣe ti Ọlọrun, a ma gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun: nitori eyi li ẹnyin kò ṣe gbọ, nitori ẹnyin kì iṣe ti Ọlọrun.
Jesu ti wà ṣiwaju Abrahamu
48Awọn Ju dahùn nwọn si wi fun u pe, Awa kò wi nitõtọ pe, ara Samaria ni iwọ iṣe, ati pe iwọ li ẹmi èṣu?
49Jesu dahùn wipe, Emi kò li ẹmi èṣu; ṣugbọn emi mbọlá fun Baba mi, ẹnyin kò si bọla fun mi.
50 Emi kò wá ogo ara mi: ẹnikan mbẹ ti o nwà a ti o si nṣe idajọ.
51 Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Bi ẹnikan ba pa ọ̀rọ mi mọ́, ki yio ri ikú lailai.
52Awọn Ju wi fun u pe, Nigbayi ni awa mọ̀ pe iwọ li ẹmi èṣu. Abrahamu kú, ati awọn woli; iwọ si wipe, Bi ẹnikan ba pa ọ̀rọ mi mọ́, kì yio tọ́ ikú wò lailai.
53Iwọ ha pọ̀ju Abrahamu baba wa lọ, ẹniti o kú? awọn woli si kú: tani iwọ nfi ara rẹ pè?
54Jesu dahùn wipe, Bi mo ba nyìn ara mi li ogo, ogo mi kò jẹ nkan: Baba mi ni ẹniti nyìn mi li ogo, ẹniti ẹnyin wipe, Ọlọrun nyin ni iṣe:
55 Ẹ kò si mọ̀ ọ; ṣugbọn emi mọ̀ ọ: bi mo ba si wipe, emi kò mọ̀ ọ, emi ó di eke gẹgẹ bi ẹnyin: ṣugbọn emi mọ̀ ọ, mo si pa ọ̀rọ rẹ̀ mọ́.
56 Abrahamu baba nyin yọ̀ lati ri ọjọ mi: o si ri i, o si yọ̀.
57Nitorina awọn Ju wi fun u pe, Ọdún rẹ kò ti ito adọta, iwọ si ti ri Abrahamu?
58Jesu si wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ki Abrahamu to wà, emi ti wà.
59Nitorina nwọn gbé okuta lati sọ lù ú: ṣugbọn Jesu fi ara rẹ̀ pamọ́, o si jade kuro ni tẹmpili.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Joh 8: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: