Joh Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìhìn Rere Johanu fi Jesu hàn gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ ayérayé Ọlọrun tí “ó di eniyan tí ó sì ń gbé ààrin wa.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà alára ti wí, ìdí tí a fi kọ ọ́ ni pé kí àwọn tí wọ́n bá kà á lè gbàgbọ́ pé Jesu ni Olùgbàlà tí Ọlọrun ṣe ìlérí, òun sì ni Ọmọ Ọlọrun; ati pé kí wọ́n lè ní ìyè nípasẹ̀ gbigbagbọ tí wọ́n bá gbà á gbọ́.
Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ iṣaaju tí ó fihàn pé Jesu ni ọ̀rọ̀ ayérayé Ọlọrun, apá kinni ìhìn rere náà sọ nípa àwọn oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ìyanu tí ó fihàn pé Jesu ni Olùgbàlà tí Ọlọrun ṣe ìlérí, òun ni Ọmọ Ọlọrun. Lẹ́yìn èyí, ẹni tí ó kọ ìwé náà ṣe àkójọ àwọn àlàyé tí ó ṣe nípa ohun tí àwọn iṣẹ́ ìyanu dúró fún. Ninu apá tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ni ó ti sọ nípa àwọn mélòó kan tí wọ́n gba Jesu gbọ́ tí wọ́n sì di ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àwọn mìíràn takò ó, wọ́n kọ̀, wọn kò gbà á gbọ́. Orí 13 dé 17 sọ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nípa bí Jesu ti fara mọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tímọ́tímọ́ ní alẹ́ ọjọ́ tí wọ́n mú un. Ó tún sọ nípa ọ̀rọ̀ ìpalẹ̀mọ́ ati ìmúnilọ́kànle tí Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà tí ó kù fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ kí wọ́n kàn án mọ́ agbelebu. Orí bíi mélòó kan tí ó parí ìwé náà sọ nípa bí wọ́n ṣe mú Jesu, tí wọ́n wá ẹ̀sùn sí i lẹ́sẹ̀, tí wọ́n kàn án mọ́ agbelebu ati bí ó ṣe jinde. Ó tún sọ nípa bí ó ṣe farahan àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́yìn ajinde rẹ̀.
Johanu tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀bùn ìyè ainipẹkun ninu Kristi. Láti ìsinsìnyìí lọ ni ẹ̀bùn tí àwọn tí wọ́n bá gba Jesu bí ọ̀nà, òtítọ́ ati ìyè yóo rí gbà ti bẹ̀rẹ̀. Ọ̀kan ninu àwọn ohun tí ó gúnni lọ́kàn ninu ìwé Johanu ni bí ó ṣe ń mú àwọn nǹǹkan yẹpẹrẹ inú ìgbé-ayé wa ojoojumọ, tí ó sì ń lò wọ́n gẹ́gẹ́ bí àpèjúwe pataki láti tọ́ka sí àwọn nǹǹkan ti ẹ̀mí tí wọ́n jẹ́ kókó; fún bíi àpẹẹrẹ: omi, oúnjẹ, ìmọ́lẹ̀, olùṣọ́ aguntan ati àwọn aguntan rẹ̀, ati igi àjàrà pẹlu èso rẹ̀.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀rọ̀ àkọ́sọ 1:1-18
Johanu Onítẹ̀bọmi ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu kinni 1:19-51
Àwọn iṣẹ́ tí Jesu ṣe ní gbangba 2:1—12:50
Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ní Jerusalẹmu ati agbègbè rẹ̀ 13:1—19:42
Ajinde ati ìfarahàn Oluwa 20:1-31
Ọ̀rọ̀ ìparí: ìfarahàn mìíràn ní Galili 21:1-25

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Joh Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀