Job 14
14
1ENIA ti a bi ninu obinrin ọlọjọ diẹ ni, o si kún fun ipọnju.
2O jade wá bi itana eweko, a si ke e lulẹ, o si nfò lọ bi ojiji, kò si duro pẹ́.
3Iwọ si nṣiju rẹ wò iru eyinì, iwọ si mu mi wá sinu idajọ pẹlu rẹ.
4Tali o le mu ohun mimọ́ lati inu aimọ́ jade wá? kò si ẹnikan!
5Njẹ ati pinnu ọjọ rẹ̀, iye oṣu rẹ̀ mbẹ li ọwọ rẹ, iwọ ti pàla rẹ̀, bẹ̃li on kò le ikọja rẹ̀.
6Yipada kuro lọdọ rẹ̀, ki o le simi titi yio fi pé ọjọ rẹ̀ bi alagbaṣe.
7Nitoripe abá wà fun igi, bi a ba ke e lulẹ, pe yio si tun sọ, ati pe ẹka rẹ̀ titun, kì yio dá.
8Bi gbongbo rẹ̀ tilẹ di ogbó ninu ilẹ, ti kukute rẹ̀ si kú ni ilẹ.
9Sibẹ nigbati o ba gbõrùn omi, yio sọ, yio si yọ ẹka jade bi eweko.
10Ṣugbọn enia kú, a si ṣàn danu; ani enia jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, on ha da?
11Bi omi ti itán ninu ipa odò, ti odò si ifà ti si igbẹ.
12Bẹ̃li enia dubulẹ ti kò si dide mọ́, titi ọrun kì yio fi si mọ́, nwọn kì yio ji, a kì yio ji wọn kuro loju orun wọn.
13A! iwọ iba fi mi pamọ ni ipo-okú, ki iwọ ki o fi mi pamọ ni ìkọkọ, titi ibinu rẹ yio fi rekọja, iwọ iba lana igba kan silẹ fun mi, ki o si ranti mi.
14Bi enia ba kú yio si tun yè bi? gbogbo ọjọ igba ti a là silẹ fun mi li emi o duro dè, titi amudọtun mi yio fi de.
15Iwọ iba pè, emi iba si da ọ lohùn, iwọ o si ni ifẹ si iṣẹ ọwọ rẹ.
16Ṣugbọn nisisiyi iwọ nkaye iṣisẹ mi, iwọ kò fà ọwọ rẹ kuro nitori ẹ̀ṣẹ mi.
17A fi edidi di irekọja mi sinu àpo, iwọ si rán aiṣedede mi pọ̀.
18Ati nitotọ oke nla ti o ṣubu, o dasan, a si ṣi apata kuro ni ipo rẹ̀.
19Omi a ma yinrin okuta, iwọ a si mu omi ṣàn bo ohun ti o hù jade lori ilẹ, iwọ si sọ ireti enia di ofo.
20Iwọ si ṣẹgun rẹ̀ lailai, on si kọja lọ iwọ pa awọ oju rẹ̀ dà, o si ran a lọ kuro.
21Awọn ọmọ rẹ̀ bọ́ si ipo ọlá, on kò si mọ̀, nwọn si rẹ̀ silẹ, on kò si kiyesi i lara wọn.
22Ṣugbọn ẹran-ara rẹ̀ ni yio ri irora, ọkàn rẹ̀ ni yio si ma ni ibinujẹ ninu rẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Job 14: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: