Job 30
30
1ṢUGBỌN nisisiyi awọn ti mo gbà li aburo nfi mi ṣẹ̀sin, baba ẹniti emi kẹgàn lati tò pẹlu awọn ajá agbo-ẹran mi.
2Pẹlupẹlu agbara ọwọ wọn kini o le igbè fun mi, awọn ẹniti kikún ọjọ wọn kò si.
3Nitori aini ati ìyan nwọn di ẹni itakete, nwọn si girijẹ ohun jijẹ iju, ti o wà ni isọdahoro ati òfo lati lailai.
4Awọn ẹniti njá ewe-iyọ li ẹ̀ba igbẹ, gbongbo igikigi li ohun jijẹ wọn.
5A le wọn jade kuro lãrin enia, nwọn si ho le wọn bi ẹnipe si olè.
6Lati gbé inu pàlapala okuta afonifoji, ninu iho ilẹ ati ti okuta.
7Ninu igbẹ ni nwọn ndún, nwọn ko ara wọn jọ pọ̀ labẹ ẹgun neteli.
8Awọn ọmọ ẹniti oye kò ye, ani ọmọ awọn enia lasan, a si le wọn kuro ninu ilẹ.
9Njẹ nisisiyi emi di ẹni-orin fun wọn, ani emi di ẹni-asọrọsi fun wọn.
10Nwọn korira mi, nwọn sa kuro jina si mi, nwọn kò si dá si lati tutọ́ si mi loju.
11Nitoriti Ọlọrun ti tu okun-ìye mi, o si pọn mi loju; awọn pẹlu si dẹ̀ ijanu niwaju mi.
12Awọn enia lasan dide li apa ọ̀tun mi, nwọn tì mi li ẹsẹ kuro, nwọn si là ipa-ọ̀na iparun silẹ dè mi.
13Nwọn dà ipa-ọ̀na mi rú, nwọn ran jàmba mi lọwọ, awọn ti kò li oluranlọwọ;
14Nwọn de si mi bi yiya omi gburu, ni ariwo nla ni nwọn ko ara wọn kátì si mi.
15Ẹ̀ru nla yipada bà mi, nwọn lepa ọkàn mi bi ẹfùfù, alafia mi si kọja lọ bi awọsanma.
16Ati nisisiyi ọkàn mi si dà jade si mi, ọjọ ipọnju dì mi mu.
17Oru gùn mi ninu egungun mi, eyiti o bù mi jẹ kò si simi.
18Nipa agbara nla aṣọ mi di pipada, o si lẹmọ́ mi li ara yika bi ọrùn aṣọ ileke mi.
19O ti mu mi lọ sinu ẹrẹ̀, emi si dabi ekuru ati ẽru,
20Emi kepè ọ, iwọ kò si gbọ́ ti emi, emi dide duro, iwọ si fi oju lile wò mi.
21Iwọ pada di ẹni-ìka si mi, ọwọ agbara rẹ ni iwọ fi de ara rẹ li ọ̀na si mi.
22Iwọ gbe mi soke si ẹ̀fufu, iwọ mu mi fò lọ, bẹ̃ni iwọ si sọ mi di asan patapata.
23Emi sa mọ̀ pe iwọ o mu mi lọ sinu ikú, ati si ile-apejọ fun gbogbo alãye.
24Bi o ti wu ki o ṣe, ẹnikan kì yio ha nawọ rẹ̀ ni igba iṣubu rẹ̀, tabi kì yio ké ninu iparun rẹ̀.
25Emi kò ha sọkun bi fun ẹniti o wà ninu iṣẹ, ọkàn mi kò ha bajẹ fun talaka bi?
26Nigbati mo fojusọna fun alafia, ibi si de, nigbati emi duro de imọlẹ, òkunkun si de.
27Ikùn mi nru, kò si simi, ọjọ ipọnju ti bá mi.
28Emi nṣọ̀fọ lọ rinkiri laisi õrùn, emi dide duro ni awujọ, mo si kigbe.
29Emi jasi arakunrin ajáko, emi di ẹgbẹ́ awọn abo-ogongo.
30Àwọ mi di dudu li ara mi, egungun mi si jórun fun õru.
31Dùru mi pẹlu si di ti ọ̀fọ, ati ohun-ọnà orin mi si di ohùn awọn ti nsọkún.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Job 30: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: