Luk 1
1
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju sí Tiofilu
1NIWỌNBI ọ̀pọ enia ti dawọle e lati tò ìhin wọnni jọ lẹsẹsẹ, eyiti o ti gbilẹ ṣinṣin lãrin wa,
2Ani gẹgẹ bi awọn ti o ṣe oju wọn lati ibẹrẹ, ti nwọn si jasi iranṣẹ ọrọ na, ti fi le wa lọwọ;
3O si yẹ fun mi pẹlu, lati kọwe si ọ lẹsẹsẹ bi mo ti wadi ohun gbogbo kinikini si lati ipilẹsẹ, Teofilu ọlọla jùlọ,
4Ki iwọ ki o le mọ̀ ọtitọ ohun wọnni, ti a ti kọ́ ọ.
Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Ìbí Johanu Onítẹ̀bọmi
5Nigba ọjọ Herodu ọba Judea, alufa kan wà, ni ipa ti Abia, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Sakariah: aya rẹ̀ si ṣe ọkan ninu awọn ọmọbinrin Aaroni, orukọ rẹ̀ a si ma jẹ Elisabeti.
6Awọn mejeji si ṣe olododo niwaju Ọlọrun, nwọn nrìn ni gbogbo ofin on ìlana Oluwa li ailẹgan.
7Ṣugbọn nwọn kò li ọmọ, nitoriti Elisabeti yàgan, awọn mejeji si di arugbo.
8O si ṣe, nigbati o nṣe iṣẹ alufa niwaju Ọlọrun ni ipa iṣẹ́ tirẹ̀,
9Bi iṣe awọn alufa, ipa tirẹ̀ ni ati ma fi turari jóna, nigbati o ba wọ̀ inu tẹmpili Oluwa lọ.
10Gbogbo ijọ awọn enia si ngbadura lode li akokò sisun turari.
11Angẹli Oluwa kan si fi ara hàn a, o duro li apa ọtún pẹpẹ turari.
12Nigbati Sakariah si ri i, ori rẹ̀ wúle, ẹ̀ru si ba a.
13Ṣugbọn angẹli na wi fun u pe, Má bẹ̀ru, Sakariah: nitoriti adura rẹ gbà; Elisabeti aya rẹ yio si bí ọmọkunrin kan fun ọ, iwọ o si sọ orukọ rẹ̀ ni Johanu.
14Iwọ o si li ayọ̀ ati inu didùn: enia pipọ yio si yọ̀ si ibí rẹ̀.
15Nitori on o pọ̀ niwaju Oluwa, kì yio si mu ọti-waini, bẹ̃ni kì yio si mu ọti-lile; yio si kún fun Ẹmi Mimọ́ ani lati inu iya rẹ̀ wá.
16On o si pa pipọ da ninu awọn ọmọ Israeli si Oluwa Ọlọrun wọn.
17Ẹmí ati agbara Elijah ni on o si fi ṣaju rẹ̀ lọ, lati pa ọkàn awọn baba dà si ti awọn ọmọ, ati ti awọn alaigbọran si ọgbọ́n awọn olõtọ; ki o le pèse enia ti a mura silẹ dè Oluwa.
18Sakariah si wi fun angẹli na pe, Àmi wo li emi o fi mọ̀ eyi? Emi sá di àgba, ati Elisabeti aya mi si di arugbo.
19Angẹli na si dahùn o wi fun u pe, Emi ni Gabrieli, ti ima duro niwaju Ọlọrun; emi li a rán wá lati sọ fun ọ, ati lati mu ìhin ayọ̀ wọnyi fun ọ wá.
20Si kiyesi i, iwọ o yadi, iwọ kì yio si le fọhun, titi ọjọ na ti nkan wọnyi yio fi ṣẹ, nitori iwọ ko gbà ọ̀rọ mi gbọ́ ti yio ṣẹ li akokò wọn.
21Awọn enia si duro dè Sakariah, ẹnu si yà wọn nitoriti o pẹ ninu tẹmpili.
22Nigbati o si jade, kò le fọhun si wọn: nwọn si woye pe o ri iran ninu tẹmpili: nitoriti o nṣe apẹrẹ si wọn, o si yà odi.
23O si ṣe, nigbati ọjọ iṣẹ isin rẹ̀ pe, o lọ si ile rẹ̀.
24Lẹhin ọjọ wọnyi ni Elisabeti aya rẹ̀ lóyun, o si fi ara rẹ̀ pamọ́ li oṣù marun, o ni,
25Bayi li Oluwa ṣe fun mi li ọjọ ti o ṣijuwò mi, lati mu ẹ̀gan mi kuro lọdọ araiye.
Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Ìbí Jesu
26Li oṣù kẹfa a si rán angẹli Gabrieli lati ọdọ Ọlọrun lọ si ilu kan ni Galili, ti a npè ni Nasareti,
27Si wundia kan ti a fẹ fun ọkunrin kan, ti a npè ni Josefu, ti idile Dafidi; orukọ wundia na a si ma jẹ Maria.
28Angẹli na si tọ̀ ọ wá, o ni, Alãfia iwọ ẹniti a kọjusi ṣe li ore, Oluwa pẹlu rẹ: alabukun-fun ni iwọ ninu awọn obinrin.
29Ṣugbọn ọkàn rẹ̀ kò lelẹ nitori ọ̀rọ na, o si rò ninu ara rẹ̀ pe, irú kíki kili eyi.
30Angẹli na si wi fun u pe, Má bẹ̀ru, Maria: nitori iwọ ti ri ojurere lọdọ Ọlọrun.
31Sá si kiyesi i, iwọ o lóyun ninu rẹ, iwọ o si bí ọmọkunrin kan, iwọ o si pè orukọ rẹ̀ ni JESU.
32On o pọ̀, Ọmọ Ọgá-ogo julọ li a o si ma pè e: Oluwa Ọlọrun yio si fi itẹ́ Dafidi baba rẹ̀ fun u:
33Yio si jọba ni ile Jakọbu titi aiye; ijọba rẹ̀ ki yio si ni ipẹkun.
34Nigbana ni Maria wi fun angẹli na pe, Eyi yio ha ti ṣe ri bẹ̃, nigbati emi kò ti mọ̀ ọkunrin?
35Angẹli na si dahùn o si wi fun u pe, Ẹmí Mimọ́ yio tọ̀ ọ wá, ati agbara Ọgá-ogo yio ṣiji bò ọ: nitorina ohun mimọ́ ti a o ti inu rẹ bi, Ọmọ Ọlọrun li a o ma pè e.
36Si kiyesi i, Elisabeti ibatan rẹ, on pẹlu si lóyun ọmọkunrin kan li ogbologbo rẹ̀: eyi si li oṣu kẹfa fun ẹniti a npè li agàn.
37Nitori kò si ohun ti Ọlọrun ko le ṣe.
38Maria si wipe, Wò ọmọ-ọdọ Oluwa; ki o ri fun mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Angẹli na si fi i silẹ lọ.
Maria Lọ Bẹ Elisabẹti Wò
39Ni ijọ wọnyi ni Maria si dide, o lọ kánkan si ilẹ-òke, si ilu kan ni Juda;
40O si wọ̀ ile Sakariah lọ o si ki Elisabeti.
41O si ṣe, nigbati Elisabeti gbọ́ kikí Maria, ọlẹ̀ sọ ninu rẹ̀; Elisabeti si kún fun Ẹmí Mimọ́:
42O si ke li ohùn rara, o si wipe, Alabukun-fun ni iwọ ninu awọn obinrin, alabukun-fun si ni fun ọmọ inu rẹ.
43Nibo si li eyi ti wá ba mi, ti iya Oluwa mi iba fi tọ̀ mi wá?
44Sawò o, bi ohùn kikí rẹ ti bọ́ si mi li etí, ọlẹ̀ sọ ninu mi fun ayọ̀.
45Alabukun-fun si li ẹniti o gbagbọ́: nitori nkan wọnyi ti a ti sọ fun u lati ọdọ Oluwa wá yio ṣẹ.
Maria Kọ Orin Ìyìn
46Maria si dahùn, o ni, Ọkàn mi yìn Oluwa logo,
47Ẹmí mi si yọ̀ si Ọlọrun Olugbala mi.
48Nitoriti o ṣijuwò ìwa irẹlẹ ọmọbinrin ọdọ rẹ̀: sá wò o, lati isisiyi lọ gbogbo iran enia ni yio ma pè mi li alabukunfun.
49Nitori ẹniti o li agbara ti ṣe ohun ti o tobi fun mi; mimọ́ si li orukọ rẹ̀.
50Anu rẹ̀ si mbẹ fun awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀ lati irandiran.
51O ti fi agbara hàn li apa rẹ̀; o ti tú awọn onirera ká ni ironu ọkàn wọn.
52O ti mu awọn alagbara kuro lori itẹ́ wọn, o si gbé awọn talakà leke.
53O ti fi ohun ti o dara kún awọn ti ebi npa; o si rán awọn ọlọrọ̀ pada lọwọ ofo.
54O ti ràn Israeli ọmọ-ọdọ rẹ̀ lọwọ, ni iranti ãnu rẹ̀;
55Bi o ti sọ fun awọn baba wa, fun Abrahamu, ati fun irú-ọmọ rẹ̀ lailai.
56Maria si ba a joko niwọn oṣù mẹta, o si pada lọ si ile rẹ̀.
57Ọjọ Elisabeti pe wayi ti yio bí; o si bí ọmọkunrin kan.
Ìbí Johanu Onítẹ̀bọmi
58Ati awọn aladugbo, ati awọn ibatan rẹ̀ gbọ́ bi Oluwa ti ṣe ãnu nla fun u; nwọn si ba a yọ̀.
59O si ṣe, ni ijọ kẹjọ nwọn wá lati kọ ọmọ na nila; nwọn si sọ orukọ rẹ̀ ni Sakariah, gẹgẹ bi orukọ baba rẹ̀.
60Iya rẹ̀ si dahùn, o ni Bẹ̃kọ; bikoṣe Johanu li a o pè e.
61Nwọn si wi fun u pe, Kò si ọkan ninu awọn ará rẹ ti a npè li orukọ yi.
62Nwọn si ṣe apẹrẹ si baba rẹ̀, bi o ti nfẹ ki a pè e.
63O si bère walã, o kọ, wipe, Johanu li orukọ rẹ̀. Ẹnu si yà gbogbo wọn.
64Ẹnu rẹ̀ si ṣí lọgan, okùn ahọn rẹ̀ si tú, o si sọ̀rọ, o si nyìn Ọlọrun.
65Ẹ̀ru si ba gbogbo awọn ti mbẹ li àgbegbe wọn: a si rohin gbogbo nkan wọnyi ká gbogbo ilẹ òke Judea.
66Gbogbo awọn ti o gbọ́ si tò o sinu ọkàn wọn, nwọn nwipe, Irú ọmọ kili eyi yio jẹ! Ọwọ́ Oluwa si wà pẹlu rẹ̀.
Sakaraya Sọ Àsọtẹ́lẹ̀
67Sakariah baba rẹ̀ si kún fun Ẹmí Mimọ́, o si sọtẹlẹ, o ni,
68Olubukun li Oluwa Ọlọrun Israeli; nitoriti o ti bojuwò, ti o si ti dá awọn enia rẹ̀ nide,
69O si ti gbé iwo igbala soke fun wa ni ile Dafidi ọmọ-ọdọ rẹ̀;
70Bi o ti wi li ẹnu awọn woli rẹ̀ mimọ́, ti nwọn ti mbẹ nigbati aiye ti ṣẹ̀:
71Pe, a o gbà wa là lọwọ awọn ọtá wa, ati lọwọ gbogbo awọn ti o korira wa;
72Lati ṣe ãnu ti o ti leri fun awọn baba wa, ati lati ranti majẹmu rẹ̀ mimọ́,
73Ara ti o ti bú fun Abrahamu baba wa,
74Pe on o fifun wa, lati gbà wa lọwọ awọn ọtá wa, ki awa ki o le ma sìn i laifòya,
75Ni mimọ́ ìwa ati li ododo niwaju rẹ̀, li ọjọ aiye wa gbogbo.
76Ati iwọ, ọmọ, woli Ọgá-ogo li a o ma pè ọ: nitori iwọ ni yio ṣaju Oluwa lati tún ọ̀na rẹ̀ ṣe;
77Lati fi ìmọ igbala fun awọn enia rẹ̀ fun imukuro ẹ̀ṣẹ wọn,
78Nitori iyọ́nu Ọlọrun wa; nipa eyiti ìla-õrùn lati oke wá bojuwò wa,
79Lati fi imọlẹ fun awọn ti o joko li òkunkun ati li ojiji ikú, ati lati fi ẹsẹ wa le ọ̀na alafia.
80Ọmọ na si dàgba, o si le li ọkàn, o si wà ni ijù titi o fi di ọjọ ifihàn rẹ̀ fun Israeli.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Luk 1: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.