Luk 10
10
Àwọn tí ó fẹ́ tẹ̀lé Jesu
(Mat 8:19-22)
1LẸHIN nkan wọnyi, Oluwa si yàn adọrin ọmọ-ẹhin miran pẹlu, o si rán wọn ni mejimeji lọ ṣaju rẹ̀, si gbogbo ilu ati ibi ti on tikararẹ̀ yio gbé de.
2O si wi fun wọn pe, Ikore pọ̀, ṣugbọn awọn alagbaṣe ko to nkan: nitorina ẹ bẹ̀ Oluwa ikore, ki o le rán awọn alagbaṣe sinu ikore rẹ̀.
3 Ẹ mu ọ̀na nyin pọ̀n: sa wò o, emi rán nyin lọ bi ọdọ-agutan sãrin ikõkò.
4 Ẹ máṣe mu asuwọn, ẹ máṣe mu apò, tabi bàta: ẹ má si ṣe kí ẹnikẹni li ọ̀na.
5 Ni ilekile ti ẹnyin ba wọ̀, ki ẹ kọ́ wipe, Alafia fun ile yi.
6 Bi ọmọ alafia ba si mbẹ nibẹ̀, alafia nyin yio bà le e: ṣugbọn bi kò ba si, yio tún pada sọdọ nyin.
7 Ni ile kanna ni ki ẹnyin ki o si gbé, ki ẹ mã jẹ, ki ẹ si mã mu ohunkohun ti nwọn ba fifun nyin; nitori ọ̀ya alagbaṣe tọ́ si i. Ẹ maṣe ṣi lati ile de ile.
8 Ati ni ilukilu ti ẹnyin ba wọ̀, ti nwọn ba si gbà nyin, ẹ jẹ ohunkohun ti a ba gbé kà iwaju nyin:
9 Ẹ si mu awọn alaisan ti mbẹ ninu rẹ̀ larada, ki ẹ si wi fun wọn pe, Ijọba Ọlọrun kù dẹ̀dẹ si nyin.
10 Ṣugbọn ni ilukilu ti ẹnyin ba si wọ̀, ti nwọn kò ba si gbà nyin, nigbati ẹnyin ba si jade si igboro ilu na, ki ẹnyin ki o si wipe,
11 Ekuru iyekuru ilu nyin ti o kù si wa lara, a gbọn ọ silẹ fun nyin: ṣugbọn ẹ mọ̀ eyi pe, ijọba Ọlọrun kù dẹ̀dẹ si nyin.
12 Ṣugbọn mo wi fun nyin, yio san fun Sodomu ni ijọ na, jù fun ilu na lọ.
Jesu Dárò Àwọn Ìlú tí Kò Ronupiwada
(Mat 11:20-24)
13 Egbé ni fun iwọ, Korasini! Egbé ni fun iwọ, Betsaida! nitori ibaṣepe a ti ṣe iṣẹ agbara ti a ṣe ninu nyin, ni Tire on Sidoni, nwọn iba ti ronupiwada lailai, nwọn iba si joko ninu aṣọ ọ̀fọ ati ninu ẽru.
14 Ṣugbọn yio san fun Tire on Sidoni nigba idajọ jù fun ẹnyin lọ.
15 Ati iwọ, Kapernaumu, a o ha gbe ọ ga de oke ọrun? a o rẹ̀ ọ silẹ de ipo-oku.
16 Ẹniti o ba gbọ́ ti nyin, o gbọ́ ti emi: ẹniti o ba si kọ̀ nyin, o kọ̀ mi; ẹniti o ba si kọ̀ mi, o kọ̀ ẹniti o rán mi.
Àwọn Mejilelaadọrin Pada Dé
17Awọn adọrin na si fi ayọ̀ pada, wipe, Oluwa, awọn ẹmi èṣu tilẹ foribalẹ fun wa li orukọ rẹ.
18O si wi fun wọn pe, Emi ri Satani ṣubu bi manamana lati ọrun wá.
19 Kiyesi i, emi fun nyin li aṣẹ lati tẹ̀ ejò ati akẽkẽ mọlẹ, ati lori gbogbo agbara ọtá: kò si si ohunkan bi o ti wù ki o ṣe, ti yio pa-nyin-lara.
20 Ṣugbọn ki ẹ máṣe yọ̀ si eyi, pe, awọn ẹmi nforibalẹ fun nyin; ṣugbọn ẹ kuku yọ̀, pe, a kọwe orukọ nyin li ọrun.
Jesu Láyọ̀
(Mat 11:25-27; 13:16-17)
21Ni wakati kanna Jesu yọ̀ ninu Ẹmi Mimọ́ o si wipe, Mo dupẹ lọwọ rẹ, Baba, Oluwa ọrun on aiye, pe, iwọ pa nkan wọnyi mọ́ kuro lọdọ awọn ọlọ́gbọn ati amoye, iwọ si fi wọn hàn fun awọn ọmọ-ọwọ: bẹ̃ni, Baba, bẹ̃li o sá yẹ li oju rẹ.
22 Ohun gbogbo li a fifun mi lati ọdọ Baba mi wá: kò si si ẹniti o mọ̀ ẹniti Ọmọ iṣe, bikoṣe Baba; ati ẹniti Baba iṣe, bikoṣe Ọmọ, ati ẹnikẹni ti o ba si wù Ọmọ lati fi i hàn fun.
23O si yipada si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ li apakan, o ni, Ibukún ni fun ojú ti nri ohun ti ẹnyin nri:
24 Nitori mo wi fun nyin, Woli ati ọba pipọ li o nfẹ lati ri ohun ti ẹnyin nri, nwọn kò si ri wọn, ati lati gbọ ohun ti ẹnyin ngbọ́, nwọn ko si gbọ́ wọn,
Aláàánú Ará Samaria
25Si kiyesi i, amofin kan dide, o ndán a wò, o ni, Olukọni, kili emi o ṣe ki emi ki o le jogún iyè ainipẹkun?
26O si bi i pe, Kili a kọ sinu iwe ofin? bi iwọ ti kà a?
27O si dahùn wipe, Ki iwọ ki o fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo agbara rẹ, ati gbogbo inu rẹ fẹ Oluwa Ọlọrun rẹ; ati ẹnikeji rẹ bi ara rẹ.
28O si wi fun u pe, Iwọ dahùn rere: ṣe eyi, iwọ o si yè.
29Ṣugbọn o nfẹ lati dá ara rẹ̀ lare, o wi fun Jesu pe, Tani ha si li ẹnikeji mi?
30Jesu si dahùn o wipe, Ọkunrin kan nti Jerusalemu sọkalẹ lọ si Jeriko, o si bọ si ọwọ́ awọn ọlọṣà, ti nwọn gbà a li aṣọ, nwọn ṣá a lọgbẹ, nwọn si fi i silẹ lọ li aipa li apatan.
31 Ni alabapade, alufa kan si nsọkalẹ lọ lọna na: nigbati o si ri i, o kọja lọ niha keji.
32 Bẹ̃na si ni ọmọ Lefi kan pẹlu, nigbati o de ibẹ̀, ti o si ri i, o kọja lọ niha keji.
33 Ṣugbọn ara Samaria kan, bi o ti nrè àjo, o de ibi ti o gbé wà: nigbati o si ri i, ãnu ṣe e,
34 O si tọ̀ ọ lọ, o si dì i lọgbẹ, o da oróro on ọti-waini si i, o si gbé e le ori ẹranko ti on tikalarẹ̀, o si mu u wá si ile-èro, o si nṣe itọju rẹ̀.
35 Nigbati o si lọ ni ijọ keji, o fi owo idẹ meji fun olori ile-ero, o si wi fun u pe, Mã tọju rẹ̀; ohunkohun ti iwọ ba si ná kun u, nigbati mo ba pada de, emi ó san a fun ọ.
36 Ninu awọn mẹtẹta wọnyi, tani iwọ rò pe iṣe ẹnikeji ẹniti o bọ si ọwọ́ awọn ọlọṣà?
37O si dahùn wipe, Ẹniti o ṣãnu fun u ni. Jesu si wi fun u pe, Lọ, ki iwọ ki o si ṣe bẹ̃ gẹgẹ.
Jesu Bẹ Mata ati Maria Wò
38O si ṣe, bi nwọn ti nlọ, o wọ̀ iletò kan: obinrin kan ti a npè ni Marta si gbà a si ile rẹ̀.
39O si ni arabinrin kan ti a npè ni Maria, ti o si joko lẹba ẹsẹ Jesu, ti o ngbọ́ ọ̀rọ rẹ̀.
40Ṣugbọn Marta nṣe iyọnu ohun pupọ, o si tọ̀ ọ wá, o ni, Oluwa, iwọ kò kuku ṣu si i ti arabinrin mi fi mi silẹ lati mã nikan ṣe aisimi? Wi fun u ki o ràn mi lọwọ.
41Ṣugbọn Jesu si dahùn, o si wi fun u pe, Marta, Marta, iwọ nṣe aniyan ati lãlã nitori ohun pipọ:
42 Ṣugbọn ohun kan li a kò le ṣe alaini. Maria si ti yàn ipa rere na, ti a kò le gbà lọwọ rẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Luk 10: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: