Èṣu si mu u re ori òke giga, o si fi gbogbo ilẹ-ọba aiye hàn a ni iṣẹju kan. Èṣu si wi fun u pe, Iwọ li emi o fi gbogbo agbara yi ati ogo wọn fun: gbogbo rẹ̀ li a sá ti fifun mi; ẹnikẹni ti o ba si wù mi, emi a fi i fun. Njẹ bi iwọ ba foribalẹ fun mi, gbogbo rẹ̀ ni yio jẹ tirẹ. Jesu si dahùn o si wi fun u pe, Kuro lẹhin mi, Satani, nitoriti a kọwe rẹ̀ pe, Iwọ foribalẹ fun Oluwa Ọlọrun rẹ, on nikanṣoṣo ni ki iwọ ki o si ma sìn.
Kà Luk 4
Feti si Luk 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 4:5-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò