Mat 22
22
Òwe Àsè Igbeyawo
(Luk 14:15-24)
1Jesu si dahùn, o si tún fi owe sọ̀rọ fun wọn pe,
2 Ijọba ọrun dabi ọba kan, ti o ṣe igbeyawo fun ọmọ rẹ̀.
3 O si rán awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ lọ ipè awọn ti a ti pè tẹlẹ si ibi iyawo: ṣugbọn nwọn kò fẹ wá.
4 O si tún rán awọn ọmọ-ọdọ miran, wipe, Ẹ wi fun awọn ti a pè pe, Wò o, mo se onjẹ mi tan: a pa malu ati gbogbo ẹran abọpa mi, a si ṣe ohun gbogbo tan: ẹ wá si ibi iyawo.
5 Ṣugbọn nwọn ko fi pè nkan, nwọn ba tiwọn lọ, ọkan si ọ̀na oko rẹ̀, omiran si ọ̀na òwò rẹ̀:
6 Awọn iyokù si mu awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, nwọn ṣe àbuku si wọn, nwọn si lù wọn pa.
7 Nigbati ọba si gbọ́ eyi, o binu: o si rán awọn ogun rẹ̀ lọ, o pa awọn apania wọnni run, o si kun ilu wọn.
8 Nigbana li o wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, A se ase iyawo tan, ṣugbọn awọn ti a ti pè kò yẹ.
9 Nitorina ẹ lọ si ọ̀na opópo, iyekiye ẹniti ẹ ba ri, ẹ pè wọn wá si ibi iyawo.
10 Bẹ̃li awọn ọmọ-ọdọ wọnni si jade lọ si ọ̀na opópo, nwọn si kó gbogbo awọn ẹniti nwọn ri jọ, ati buburu ati rere: ibi ase iyawo si kún fun awọn ti o wá jẹun.
11 Nigbati ọba na wá iwò awọn ti o wá jẹun, o ri ọkunrin kan nibẹ̀ ti kò wọ̀ aṣọ iyawo:
12 O si bi i pe, Ọrẹ́, iwọ ti ṣe wọ̀ ìhin wá laini aṣọ iyawo? Kò si le fọhùn.
13 Nigbana li ọba wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ di i tọwọ tẹsẹ, ẹ gbé e kuro, ki ẹ si sọ ọ sinu òkunkun lode; nibẹ̀ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà.
14 Nitori ọ̀pọlọpọ li a pè, ṣugbọn diẹ li a yàn.
Ọ̀rọ̀ Jesu nípa Sísan Owó-orí fún Kesari
(Mak 12:13-17; Luk 20:20-26)
15Nigbana li awọn Farisi lọ, nwọn gbìmọ bi nwọn o ti ṣe ri ọ̀rọ gbámọ ọ li ẹnu.
16Nwọn si rán awọn ọmọ-ẹhin wọn pẹlu awọn ọmọ-ẹhin Herodu lọ sọdọ rẹ̀, wipe, Olukọni, awa mọ̀ pe olotitọ ni iwọ, iwọ̀ si nkọni li ọ̀na Ọlọrun li otitọ, bẹ̃ni iwọ ki iwoju ẹnikẹni: nitoriti iwọ kì iṣe ojuṣaju enia.
17Njẹ wi fun wa, Iwọ ti rò o si? Ó tọ́ lati mã san owode fun Kesari, tabi ko tọ́?
18Ṣugbọn Jesu mọ̀ ìro buburu wọn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ndán mi wò, ẹnyin agabagebe?
19 Ẹ fi owodẹ kan hàn mi. Nwọn si mu owo idẹ kan tọ̀ ọ wá.
20O si bi wọn pe, Aworan ati akọle tali eyi?
21Nwọn wi fun u pe, Ti Kesari ni. Nigbana li o wi fun wọn pe, Njẹ ẹ fi ohun ti iṣe ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti iṣe ti Ọlọrun fun Ọlọrun.
22Nigbati nwọn si ti gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, ẹnu yà wọn, nwọn fi i silẹ, nwọn si ba tiwọn lọ.
Ìjiyàn lórí Ajinde Àwọn Òkú
(Mak 12:18-27; Luk 20:27-40)
23Ni ijọ kanna li awọn Sadusi tọ̀ ọ wá, awọn ti o wipe ajinde okú kò si, nwọn si bi i,
24Wipe, Olukọni, Mose wipe, Bi ẹnikan ba kú li ailọmọ, ki arakunrin rẹ̀ ki o ṣu aya rẹ̀ lopó, ki o le gbe irú dide fun arakunrin rẹ̀.
25Awọn arakunrin meje kan ti wà lọdọ wa: eyi ekini lẹhin igbati o gbé aya rẹ̀ ni iyawo, o kú, bi kò ti ni irúọmọ, o fi aya rẹ̀ silẹ fun arakunrin rẹ̀:
26Gẹgẹ bẹ̃li ekeji pẹlu, ati ẹkẹta titi o fi de ekeje.
27Nikẹhin gbogbo wọn, obinrin na kú pẹlu.
28Njẹ li ajinde oku, aya ti tani yio ha ṣe ninu awọn mejeje? nitori gbogbo wọn li o sá ni i.
29Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹnyin ṣìna, nitori ẹnyin kò mọ̀ iwe-mimọ́, ẹ kò si mọ̀ agbara Ọlọrun.
30 Nitoripe li ajinde okú, nwọn kì igbeyawo, a kì si fi wọn funni ni igbeyawo, ṣugbọn nwọn dabi awọn angẹli Ọlọrun li ọrun.
31 Ṣugbọn niti ajinde okú, ẹnyin kò ti kà eyi ti a sọ fun nyin lati ọdọ Ọlọrun wá wipe,
32 Emi li Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu? Ọlọrun ki iṣe Ọlọrun awọn okú, bikoṣe ti awọn alãye.
33Nigbati awọn enia gbọ́ eyi, ẹnu yà wọn si ẹkọ́ rẹ̀.
Òfin tí Ó Ṣe Pataki Jùlọ
(Mak 12:28-34; Luk 10:25-28)
34Ṣugbọn nigbati awọn Farisi gbọ́ pe, o pa awọn Sadusi li ẹnu mọ́, nwọn pè ara wọn jọ.
35Nigbana li ọkan ninu wọn, ti iṣe amofin, ndán a wò, o si bi i lẽre ọ̀rọ kan, wipe,
36Olukọni, ewo li aṣẹ nla ninu ofin?
37Jesu si wi fun u pe, Ki iwọ ki o fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo inu rẹ, fẹ́ Ọlọrun Oluwa rẹ.
38 Eyi li ekini ati ofin nla.
39 Ekeji si dabi rẹ̀, Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ.
40 Ninu awọn ofin mejeji yi ni gbogbo ofin ati wolĩ rọ̀ mọ́.
Ọ̀rọ̀ Iyàn lórí Ẹni tí Í Ṣe Ọmọ Dafidi
(Mak 12:35-37; Luk 20:41-44)
41Bi awọn Farisi ti kó ara wọn jọ, Jesu bi wọn,
42Wipe, Ẹnyin ti rò ti Kristi si? ọmọ tani iṣe? Nwọn wi fun u pe, Ọmọ Dafidi ni.
43O wi fun wọn pe, Ẽha ti ṣe ti Dafidi nipa ẹmí fi npè e li Oluwa, wipe,
44 OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Iwọ joko li ọwọ́ ọtún mi, titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apoti itisẹ rẹ?
45 Njẹ bi Dafidi ba npè e li Oluwa, ẽha ti ri ti o fi ṣe ọmọ rẹ̀?
46Kò si si ẹnikan ti o le da a li ohùn ọ̀rọ kan, bẹ̃ni kò si ẹniti o jẹ bi i lẽre ohun kan mọ́ lati ọjọ na lọ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Mat 22: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.