Neh 6
6
Wọ́n Dìtẹ̀ Mọ́ Nehemiah
1O SI ṣe, nigbati Sanballati, ati Tobiah, ati Geṣemu, ara Arabia, ati awọn ọta wa iyokù, gbọ́ pe, mo ti mọ odi na, ati pe, kò kù ibi yiya kan ninu rẹ̀, (bi emi kò tilẹ iti gbe ilẹkùn wọnni ro ni ibode li akoko na;)
2Ni Sanballati ati Geṣemu ranṣẹ si mi, wipe, Wá, jẹ ki a jọ pade ninu ọkan ninu awọn ileto ni pẹtẹlẹ Ono. Ṣugbọn nwọn ngbero ati ṣe mi ni ibi.
3Mo si ran onṣẹ si wọn pe, Emi nṣe iṣẹ nla kan, emi kò le sọkalẹ wá: ẽṣe ti iṣẹ na yio fi duro nigbati mo ba fi i silẹ, ti mo ba si sọkalẹ tọ̀ nyin wá?
4Sibẹ nwọn ranṣẹ si mi nigba mẹrin bayi; mo si da wọn lohùn bakanna.
5Nigbana ni Sanballati rán ọmọ-ọdọ rẹ̀ si mi bakanna nigba karun ti on ti iwe ṣíṣi lọwọ rẹ̀.
6Ninu rẹ̀ li a kọ pe, A nrohin lãrin awọn keferi, Gaṣimu si wi pe, iwọ ati awọn ara Juda rò lati ṣọ̀tẹ: nitori idi eyi ni iwọ ṣe mọ odi na, ki iwọ le jẹ ọba wọn, gẹgẹ bi ọ̀rọ wọnyi.
7Iwọ pẹlu si ti yan awọn woli lati kede rẹ ni Jerusalemu wipe, Ọba wà ni Juda: nisisiyi ni a o si rò o fun ọba gẹgẹ bi ọ̀rọ wọnyi. Njẹ wá nisisiyi, ki a jọ gbimọ̀ pọ̀.
8Nigbana ni mo ranṣẹ si i wipe, A kò ṣe iru eyi, ti iwọ sọ, ṣugbọn iwọ rò wọn li ọkàn ara rẹ ni.
9Nitori gbogbo wọn mu wa bẹ̀ru, wipe, Ọwọ wọn yio rọ ninu iṣẹ na, ki a má le ṣe e. Njẹ nisisiyi, Ọlọrun, mu ọwọ mi le.
10Mo si wá si ile Ṣemaiah ọmọ Delaiah ọmọ Mehetabeeli, ti a há mọ, o si wipe, Jẹ ki a pejọ ni ile Ọlọrun ni inu tempili ki a si tì ilẹkùn tempili; nitori nwọn o wá lati pa ọ; nitõtọ, li oru ni nwọn o wá lati pa ọ.
11Mo si wipe, Enia bi emi a ma sa? Tali o si dabi emi, ti o jẹ wọ inu tempili lọ lati gba ẹmi rẹ̀ là? Emi kì yio wọ̀ ọ lọ.
12Sa kiyesi i, mo woye pe, Ọlọrun kò rán a, ṣugbọn pe, o nsọ asọtẹlẹ yi si mi: nitori Tobiah ati Sanballati ti bẹ̀ ẹ li ọ̀wẹ.
13Nitorina li o ṣe bẹ̀ ẹ li ọ̀wẹ, ki emi ba foya, ki emi ṣe bẹ̃, ki emi si ṣẹ̀, ki nwọn le ri ihìn buburu rò, ki nwọn le kẹgàn mi.
14Ọlọrun mi, rò ti Tobiah ati Sanballati gẹgẹ bi iṣẹ wọn wọnyi, ati ti Noadiah, woli obinrin, ati awọn woli iyokù ti nwọn fẹ mu mi bẹ̀ru,
Ìparí Iṣẹ́ náà
15Bẹ̃li a pari odi na li ọjọ kẹ̃dọgbọn oṣù Eluli, ni ọjọ mejilelãdọta.
16O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ọta wa gbọ́, gbogbo awọn keferi àgbegbe wa si bẹ̀ru, nwọn si rẹ̀wẹsi pupọ li oju ara wọn, nitori nwọn woye pe, lati ọwọ Ọlọrun wá li a ti ṣe iṣẹ wọnyi.
17Pẹlupẹlu li ọjọ wọnni, awọn ijòye Juda ran iwe pupọ si Tobiah, iwe Tobiah si de ọdọ wọn.
18Nitori ọ̀pọlọpọ ni Juda ti ba a mulẹ nitori ti o jẹ ana Sekaniah ọmọ Ara; ọmọ rẹ̀ Johanani si ti fẹ ọmọ Meṣullamu, ọmọ Berekiah.
19Nwọn sọ̀rọ rere rẹ̀ pẹlu niwaju mi, nwọn si sọ ọ̀rọ mi fun u. Tobiah rán iwe lati da aiya já mi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Neh 6: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.