Num 18
18
Iṣẹ́ Àwọn Àlùfáàa ati Àwọn Ọmọ Lefi
1OLUWA si sọ fun Aaroni pe, Iwọ ati awọn ọmọ rẹ, ati ile baba rẹ pẹlu rẹ, ni yio ma rù ẹ̀ṣẹ ibi-mimọ́: ati iwọ ati awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ ni yio ma rù ẹ̀ṣẹ iṣẹ-alufa nyin.
2Ati awọn arakunrin rẹ pẹlu, ẹ̀ya Lefi, ẹ̀ya baba rẹ, ni ki o múwa pẹlu rẹ, ki nwọn ki o le dàpọ pẹlu rẹ, ki nwọn ki o ma ṣe iranṣẹ fun ọ: ṣugbọn iwọ ati awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ ni yio ma ṣe iranṣẹ niwaju agọ́ ẹrí.
3Ki nwọn ki o ma pa aṣẹ rẹ mọ́, ki nwọn ki o si ma ṣe itọju gbogbo agọ́, kìki pe nwọn kò gbọdọ sunmọ ohun-èlo ibi-mimọ́ ati pẹpẹ, ki ati awọn, ati ẹnyin pẹlu ki o má ba kú.
4Ki nwọn ki o si dàpọ pẹlu rẹ, ki nwọn ki o si ma ṣe itọju agọ́ ajọ, gẹgẹ bi gbogbo iṣẹ-ìsin agọ́: alejò kan kò sí gbọdọ sunmọ ọdọ nyin.
5Ki ẹnyin ki o si ma ṣe itọju ibi-mimọ́, ati itọju pẹpẹ: ki ibinu ki o má ba sí mọ́ lori awọn ọmọ Israeli.
6Ati emi, kiyesi i, mo ti mú awọn arakunrin nyin, awọn ọmọ Lefi kuro ninu awọn ọmọ Israeli: ẹnyin li a fi wọn fun bi ẹ̀bun fun OLUWA, lati ma ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ.
7Iwọ ati awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ ni yio si ma ṣe itọju iṣẹ-alufa nyin niti ohun gbogbo ti iṣe ti pẹpẹ, ati ti inu aṣọ-ikele: ẹnyin o si ma sìn: emi ti fi iṣẹ-alufa nyin fun nyin, bi iṣẹ-ìsin ẹ̀bun: alejò ti o ba si sunmọtosi li a o pa.
Ìpín Àwọn Àlùfáà
8OLUWA si sọ fun Aaroni pe, Kiyesi i, emi si ti fi itọju ẹbọ igbesọsoke mi fun ọ pẹlu, ani gbogbo ohun mimọ́ awọn ọmọ Israeli, iwọ li emi fi wọn fun ni ipín, ati fun awọn ọmọ rẹ, bi ipín lailai.
9Eyi ni yio ṣe tirẹ ninu ohun mimọ́ julọ, ti a mú kuro ninu iná; gbogbo ọrẹ-ẹbọ wọn, gbogbo ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati gbogbo ẹbọ ẹ̀ṣẹ wọn, ati gbogbo ẹbọ ẹbi wọn, ti nwọn o mú fun mi wá, mimọ́ julọ ni yio jasi fun iwọ ati fun awọn ọmọ rẹ.
10Bi ohun mimọ́ julọ ni ki iwọ ki o ma jẹ ẹ: gbogbo ọkunrin ni yio jẹ ẹ; mimọ́ ni yio jẹ́ fun ọ.
11Eyi si ni tirẹ; ẹbọ igbesọsoke ẹ̀bun wọn, pẹlu gbogbo ẹbọ fifì awọn ọmọ Israeli: emi ti fi wọn fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati fun awọn ọmọ rẹ obinrin pẹlu rẹ, bi ipín lailai: gbogbo awọn ti o mọ́ ninu ile rẹ ni ki o jẹ ẹ.
12Gbogbo oróro daradara, ati gbogbo ọti-waini daradara, ati alikama, akọ́so ninu wọn ti nwọn o mú fun OLUWA wá, iwọ ni mo fi wọn fun.
13Akọ́so gbogbo ohun ti o wà ni ilẹ wọn, ti nwọn o mú fun OLUWA wá, tirẹ ni yio jẹ́; gbogbo ẹniti o mọ́ ni ile rẹ ni ki o jẹ ẹ.
14Ohun ìyasọtọ gbogbo ni Israeli ni ki o jẹ́ tirẹ.
15Gbogbo akọ́bi ninu gbogbo ohun alãye, ti nwọn o mú wa fun OLUWA, iba ṣe ti enia tabi ti ẹranko, ki o jẹ́ tirẹ: ṣugbọn rirà ni iwọ o rà akọ́bi enia silẹ, ati akọ́bi ẹran alaimọ́ ni ki iwọ ki o rà silẹ.
16Gbogbo awọn ti a o ràsilẹ, lati ẹni oṣù kan ni ki iwọ ki o ràsilẹ, gẹgẹ bi idiyelé rẹ, li owo ṣekeli marun, nipa ṣekeli ibi-mimọ́ (ti o jẹ́ ogun gera).
17Ṣugbọn akọ́bi akọmalu, tabi akọbi agutan, tabi akọ́bi ewurẹ, ni iwọ kò gbọdọ ràsilẹ; mimọ́ ni nwọn: ẹ̀jẹ wọn ni ki iwọ ki o ta sori pẹpẹ, ki iwọ ki o si sun ọrá wọn li ẹbọ ti a fi iná ṣe, fun õrùn didùn si OLUWA.
18Ki ẹran wọn ki o si jẹ́ tirẹ, bi àiya fifì, ati bi itan ọtún, ni yio jẹ́ tirẹ.
19Gbogbo ẹbọ igbesọsoke ohun mimọ́ wọnni, ti awọn ọmọ Israeli múwa fun OLUWA, ni mo ti fi fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati fun awọn ọmọ rẹ obinrin pẹlu rẹ, bi ipín lailai: majẹmu iyọ̀ ni lailai niwaju OLUWA fun ọ ati fun irú-ọmọ rẹ pẹlu rẹ.
20OLUWA si sọ fun Aaroni pe, Iwọ ki yio ní iní ninu ilẹ wọn, bẹ̃ni iwọ ki yio ní ipín lãrin wọn: Emi ni ipín rẹ ati iní rẹ lãrin awọn ọmọ Israeli.
Ìpín Àwọn Ọmọ Lefi
21Si kiyesi i, emi si ti fi gbogbo idamẹwa ni Israeli fun awọn ọmọ Lefi ni iní, nitori iṣẹ-ìsin wọn ti nwọn nṣe, ani iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ.
22Awọn ọmọ Israeli kò si gbọdọ sunmọ agọ́ ajọ, ki nwọn ki o má ba rù ẹ̀ṣẹ, ki nwọn má ba kú.
23Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi ni ki o ma ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ, awọn ni yio si ma rù ẹ̀ṣẹ wọn: ìlana lailai ni ni iran-iran nyin, ati lãrin awọn ọmọ Israeli, nwọn kò gbọdọ ní ilẹ-iní.
24Nitori idamẹwa awọn ọmọ Israeli, ti nwọn múwa li ẹbọ igbesọsoke fun OLUWA, ni mo ti fi fun awọn ọmọ Lefi lati ní: nitorina ni mo ṣe wi fun wọn pe, Nwọn kò gbọdọ ní ilẹ-iní lãrin awọn ọmọ Israeli.
Ìdámẹ́wàá Àwọn Ọmọ Lefi
25OLUWA si sọ fun Mose pe,
26Si sọ fun awọn ọmọ Lefi, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba ngbà idamẹwa ti mo ti fi fun nyin ni ilẹiní nyin lọwọ awọn ọmọ Israeli, nigbana ni ki ẹnyin ki o mú ẹbọ igbesọsoke ninu rẹ̀ wá fun OLUWA, idamẹwa ninu idamẹwa na.
27A o si kà ẹbọ igbesọsoke nyin yi si nyin, bi ẹnipe ọkà lati ilẹ ipakà wá, ati bi ọti lati ibi ifunti wá.
28Bayi li ẹnyin pẹlu yio ma mú ẹbọ igbesọsoke wá fun OLUWA ninu gbogbo idamẹwa nyin, ti ẹnyin ngbà lọwọ awọn ọmọ Israeli; ki ẹnyin ki o si mú ẹbọ igbesọsoke OLUWA ninu rẹ̀ tọ̀ Aaroni alufa wá.
29Ninu gbogbo ẹ̀bun nyin ni ki ẹnyin ki o si mú gbogbo ẹbọ igbesọsoke OLUWA wá, ninu gbogbo eyiti o dara, ani eyiti a yàsimimọ́ ninu rẹ̀.
30Nitorina ki iwọ ki o wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba fi eyiti o dara ninu rẹ̀ ṣe ẹbọ igbesọsoke, nigbana ni ki a kà a fun awọn ọmọ Lefi bi ọkà ilẹ-ipakà, ati bi ibisi ibi-ifunti.
31Ẹnyin o si jẹ ẹ ni ibi gbogbo, ati ẹnyin ati awọn ara ile nyin: nitoripe ère nyin ni fun iṣẹ-ìsin nyin ninu agọ́ ajọ.
32Ẹnyin ki yio si rù ẹ̀ṣẹ nitori rẹ̀, nigbati ẹnyin ba fi eyiti o dara ninu rẹ̀ ṣe ẹbọ igbesọsoke: bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ bà ohun mimọ́ awọn ọmọ Israeli jẹ́, ki ẹnyin ki o má ba kú.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Num 18: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: