Num 20
20
Ohun Tí Ó Ṣẹlẹ̀ ní Kadeṣi
1AWỌN ọmọ Israeli si wá, ani gbogbo ijọ, si aginjù Sini li oṣù kini: awọn enia na si joko ni Kadeṣi; Miriamu si kú nibẹ̀, a si sin i nibẹ̀.
2Omi kò si sí fun ijọ: nwọn si kó ara wọn jọ pọ̀ si Mose ati si Aaroni.
3Awọn enia si mbá Mose sọ̀, nwọn si wipe, Awa iba kuku ti kú nigbati awọn arakunrin wa kú niwaju OLUWA!
4Ẽha si ti ṣe ti ẹnyin fi mú ijọ OLUWA wá si aginjù yi, ki awa ati ẹran wá ki o kú nibẹ̀?
5Ẽha si ti ṣe ti ẹnyin fi mú wa gòke ti Egipti wá, lati mú wa wá si ibi buburu yi? ki iṣe ibi irugbìn, tabi ti ọpọtọ, tabi ti àjara, tabi ti pomegranate; bẹ̃ni kò sí omi lati mu.
6Mose ati Aaroni si lọ kuro niwaju ijọ si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, nwọn si doju wọn bolẹ: ogo OLUWA si hàn si wọn.
7OLUWA si sọ fun Mose pe,
8Mú ọpá nì, ki o si pe ijọ awọn enia jọ, iwọ, ati Aaroni arakunrin rẹ, ki ẹ sọ̀rọ si apata nì li oju wọn, yio si tú omi rẹ̀ jade; iwọ o si mú omi lati inu apata na jade fun wọn wá: iwọ o si fi fun ijọ ati fun ẹran wọn mu.
9Mose si mú ọpá na lati iwaju OLUWA lọ, bi o ti fun u li aṣẹ.
10Mose ati Aaroni si pe ijọ awọn enia jọ niwaju apata na, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin gbọ̀ nisisiyi, ẹnyin ọlọtẹ; ki awa ki o ha mú omi lati inu apata yi fun nyin wá bi?
11Mose si gbé ọwọ́ rẹ̀ soke, o si fi ọpá rẹ̀ lù apata na lẹ̃meji: omi si tú jade li ọ̀pọlọpọ, ijọ awọn enia si mu, ati ẹran wọn pẹlu.
12OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, Nitoriti ẹnyin kò gbà mi gbọ́, lati yà mi simimọ́ loju awọn ọmọ Israeli, nitorina ẹnyin ki yio mú ijọ awọn enia yi lọ si ilẹ na ti mo fi fun wọn.
13Wọnyi li omi Meriba; nitoriti awọn ọmọ Israeli bá OLUWA sọ̀, o si di ẹni ìya-simimọ́ ninu wọn.
Ọba Edomu kò Jẹ́ kí Àwọn Ọmọ Israẹli Kọjá
14Mose si rán onṣẹ lati Kadeṣi si ọba Edomu, wipe, Bayi ni Israeli arakunrin rẹ wi, Iwọ sá mọ̀ gbogbo ìrin ti o bá wa:
15Bi awọn baba wa ti sọkalẹ lọ si Egipti, ti awa si ti gbé Egipti ni ìgba pipẹ; awọn ara Egipti si ni wa lara, ati awọn baba wa:
16Nigbati awa si kepè OLUWA, o gbọ́ ohùn wa, o si rán angeli kan, o si mú wa lati Egipti jade wá; si kiyesi i, awa mbẹ ni Kadeṣi, ilu kan ni ipinlẹ àgbegbe rẹ:
17Jẹ ki awa ki o là ilẹ rẹ kọja lọ, awa bẹ̀ ọ: awa ki yio là inu oko rẹ, tabi inu ọgbà-àjara, bẹ̃li awa ki yio mu ninu omi kanga: ọ̀na opópo ọba li awa o gbà, awa ki o yà si ọwọ́ ọtún tabi si òsi, titi awa o fi kọja ipinlẹ rẹ.
18Edomu si wi fun u pe, Iwọ ki yio kọja lọdọ mi, ki emi ki o má ba jade si ọ ti emi ti idà.
19Awọn ọmọ Israeli si wi fun u pe, Ọ̀na opópo ọba li awa o gbà: bi awa ba mu ninu omi rẹ, emi ati ẹran mi, njẹ emi o san owo rẹ̀: laiṣe ohun miran, ki nsá fi ẹsẹ̀ mi là ilẹ kọja.
20O si wipe, Iwọ ki yio là ilẹ kọja. Edomu si mú ọ̀pọ enia jade tọ̀ ọ wá pẹlu ọwọ́ agbara.
21Bẹ̃li Edomu kọ̀ lati fi ọ̀na fun Israeli li àgbegbe rẹ̀: Israeli si ṣẹri kuro lọdọ rẹ̀.
Ikú Aaroni
22Awọn ọmọ Israeli, ani gbogbo ijọ si ṣí kuro ni Kadeṣi, nwọn si wá si òke Hori.
23OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni li òke Hori li àgbegbe ilẹ Edomu wipe,
24A o kó Aaroni jọ pẹlu awọn enia rẹ̀: nitoripe on ki yio wọ̀ inu ilẹ na ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli, nitoriti ẹnyin ṣọ̀tẹ si aṣẹ mi, nibi omi Meriba.
25Mú Aaroni ati Eleasari ọmọ rẹ̀, ki o si mú wọn wá si ori-òke Hori:
26Ki o si bọ́ Aaroni li aṣọ rẹ̀, ki o si fi wọn wọ̀ Eleasari ọmọ rẹ̀: a o si kó Aaroni jọ pẹlu awọn enia rẹ̀, yio si kú nibẹ̀.
27Mose si ṣe bi OLUWA ti fun u li aṣẹ: nwọn si gòke lọ si ori òke Hori li oju gbogbo ijọ.
28Mose si bọ́ Aaroni li aṣọ rẹ̀, o si fi wọn wọ̀ Eleasari ọmọ rẹ̀; Aaroni si kú nibẹ̀ li ori òke na: Mose ati Eleasari si sọkalẹ lati ori òke na wá.
29Nigbati gbogbo ijọ ri pe Aaroni kú, nwọn ṣọfọ Aaroni li ọgbọ̀n ọjọ́, ani gbogbo ile Israeli.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Num 20: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: