Num 22
22
Ọba Moabu Ranṣẹ Pe Balaamu
1AWỌN ọmọ Israeli si ṣí, nwọn si dó si pẹtẹlẹ̀ Moabu li apa keji Jordani ti o kọjusi Jeriko.
2Balaki ọmọ Sippori si ri gbogbo eyiti Israeli ti ṣe si awọn ọmọ Amori.
3Moabu si bẹ̀ru awọn enia na gidigidi, nitoriti nwọn pọ̀: aisimi si bá Moabu nitori awọn ọmọ Israeli.
4Moabu si wi fun awọn àgba Midiani pe, Nisisiyi li awọn ẹgbẹ yi yio lá ohun gbogbo ti o yi wa ká, bi akọmalu ti ilá koriko igbẹ́. Balaki ọmọ Sippori si jẹ́ ọba awọn ara Moabu ni ìgba na.
5O si ránṣẹ si Balaamu ọmọ Beori si Petori, ti o wà lẹba Odò, si ilẹ awọn ọmọ enia rẹ̀, lati pè e wá, wipe, Wò o, awọn enia kan ti ilẹ Egipti jade wá: si kiyesi i, nwọn bò oju ilẹ, nwọn si joko tì mi:
6Njẹ nisisiyi wa, emi bẹ̀ ọ, fi awọn enia yi bú fun mi; nitoriti nwọn lí agbara jù fun mi; bọya emi o bori, ki awa ki o kọlù wọn, ki emi ki o le lé wọn lọ kuro ni ilẹ yi: nitoriti emi mọ̀ pe ibukún ni fun ẹniti iwọ ba bukún, ifibú si ni ẹniti iwọ ba fibú.
7Ati awọn àgba Moabu, ati awọn àgba Midiani dide lọ ti awọn ti ọrẹ ìbere-afọṣẹ li ọwọ́ wọn; nwọn si tọ̀ Balaamu wá, nwọn si sọ ọ̀rọ Balaki fun u.
8O si wi fun wọn pe, Ẹ wọ̀ nihin li alẹ yi, emi o si mú ọ̀rọ pada tọ̀ nyin wá, bi OLUWA yio ti sọ fun mi: awọn ijoye Moabu si wọ̀ sọdọ Balaamu.
9Ọlọrun si tọ̀ Balaamu wá, o si wipe, Awọn ọkunrin wo ni wọnyi lọdọ rẹ?
10Balaamu si wi fun Ọlọrun pe, Balaki ọmọ Sippori, ọba Moabu, li o ranṣẹ si mi pe,
11Kiyesi i, awọn enia kan ti ilẹ Egipti jade wá, ti o bò oju ilẹ: wá nisisiyi, fi wọn bú fun mi; bọya emi o le bá wọn jà, emi a si lé wọn lọ.
12Ọlọrun si wi fun Balaamu pe, Iwọ kò gbọdọ bá wọn lọ; iwọ kò gbọdọ fi awọn enia na bú: nitoripe ẹni ibukún ni nwọn.
13Balaamu si dide li owurọ̀, o si wi fun awọn ijoye Balaki pe, Ẹ ma ba ti nyin lọ si ilẹ nyin: nitoriti OLUWA kọ̀ lati jẹ ki mbá nyin lọ.
14Awọn ijoye Moabu si dide, nwọn si tọ̀ Balaki lọ, nwọn si wipe, Balaamu kọ̀ lati bá wa wá.
15Balaki si tun rán awọn ijoye si i, ti o si lí ọlá jù wọn lọ.
16Nwọn tọ̀ Balaamu wá, nwọn si wi fun u pe, Bayi ni Balaki ọmọ Sippori wi pe, Emi bẹ̀ ọ, máṣe jẹ ki ohun kan ki o di ọ lọwọ lati tọ̀ mi wá:
17Nitoripe, emi o sọ ọ di ẹni nla gidigidi, emi o si ṣe ohunkohun ti iwọ wi fun mi: nitorina wá, emi bẹ̀ ọ, fi awọn enia yi bú fun mi.
18Balaamu si dahùn o si wi fun awọn iranṣẹ Balaki pe, Balaki iba fẹ́ fun mi ni ile rẹ̀ ti o kún fun fadaká ati wurà, emi kò le rekọja ọ̀rọ OLUWA Ọlọrun mi, lati ṣe ohun kekere tabi nla.
19Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ nyin, ẹ wọ̀ nihin pẹlu li oru yi, ki emi ki o le mọ̀ eyiti OLUWA yio wi fun mi si i.
20Ọlọrun si tọ̀ Balaamu wá li oru, o si wi fun u pe, Bi awọn ọkunrin na ba wá pè ọ, dide, bá wọn lọ; ṣugbọn kìki ọ̀rọ ti emi o sọ fun ọ, eyinì ni ki iwọ ki o ṣe.
21Balaamu si dide li owurọ̀, o si dì kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ ni gãri, o si bá awọn ijoye Moabu lọ.
Balaamu ati Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Rẹ̀
22Ibinu Ọlọrun si rú nitoriti o lọ: angeli OLUWA si duro loju ọ̀na lati di i lọ̀na. Njẹ on gùn kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, awọn iranṣẹ rẹ̀ mejeji si wà pẹlu rẹ̀.
23Kẹtẹkẹtẹ na si ri angeli OLUWA duro loju ọ̀na, idà rẹ̀ fifàyọ si wà li ọwọ́ rẹ̀: kẹtẹkẹtẹ na si yà kuro loju ọ̀na, o si wọ̀ inu igbẹ́: Balaamu si lù kẹtẹkẹtẹ na, lati darí rẹ̀ soju ọ̀na.
24Nigbana ni angeli OLUWA duro li ọna toro ọgbà-àjara meji, ogiri mbẹ ni ìha ihin, ati ogiri ni ìha ọhún.
25Kẹtẹkẹtẹ na si ri angeli OLUWA, o fún ara rẹ̀ mọ́ ogiri, o si fún ẹsẹ̀ Balaamu mọ́ ogiri: on si tun lù u.
26Angeli OLUWA si tun sun siwaju, o si tun duro ni ibi tõro kan, nibiti àye kò sí lati yà si ọwọ́ ọtún tabi si òsi.
27Nigbati kẹtẹkẹtẹ na si ri angeli OLUWA, o wólẹ̀ labẹ Balaamu: ibinu Balaamu si rú pupọ̀, o si fi ọpá lu kẹtẹkẹtẹ na.
28OLUWA si là kẹtẹkẹtẹ na li ohùn, o si wi fun Balaamu pe, Kini mo fi ṣe ọ, ti iwọ fi lù mi ni ìgba mẹta yi?
29Balaamu si wi fun kẹtẹkẹtẹ na pe, Nitoriti iwọ fi mi ṣẹsin: idà iba wà li ọwọ́ mi, nisisiyi li emi iba pa ọ.
30Kẹtẹkẹtẹ na si wi fun Balaamu pe, Kẹtẹkẹtẹ rẹ ki emi ṣe, ti iwọ ti ngùn lati ìgba ti emi ti ṣe tirẹ titi di oni? emi a ha ma ṣe si ọ bẹ̃ rí? On si dahùn wipe, Ndao.
31Nigbana ni OLUWA là Balaamu li oju, o si ri angeli OLUWA duro loju ọ̀na, idà rẹ̀ fifàyọ si wà li ọwọ́ rẹ̀: o si tẹ̀ ori ba, o si doju rẹ̀ bolẹ.
32Angeli OLUWA si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi lù kẹtẹkẹtẹ rẹ ni ìgba mẹta yi? Kiyesi i, emi jade wá lati di ọ lọ̀na, nitori ọ̀na rẹ lòdi niwaju mi.
33Kẹtẹkẹtẹ na si ri mi, o si yà fun mi ni ìgba mẹta yi: bikoṣe bi o ti yà fun mi, pipa ni emi iba pa ọ, emi a si dá on si.
34Balaamu si wi fun angeli OLUWA pe, Emi ti ṣẹ̀; nitori emi kò mọ̀ pe iwọ duro dè mi li ọ̀na; njẹ bi kò ba ṣe didùn inu rẹ, emi o pada.
35Angeli OLUWA si wi fun Balaamu pe, Ma bá awọn ọkunrin na lọ: ṣugbọn kìki ọ̀rọ ti emi o sọ fun ọ, eyinì ni ki iwọ ki o sọ. Bẹ̃ni Balaamu bá awọn ijoye Balaki lọ.
Balaki Lọ Pàdé Balaamu
36Nigbati Balaki gbọ́ pe Balaamu dé, o jade lọ ipade rẹ̀ si Ilu Moabu, ti mbẹ ni àgbegbe Arnoni, ti iṣe ipẹkun ipinlẹ na.
37Balaki si wi fun Balaamu pe, Emi kò ha ranṣẹ kanjukanju si ọ lati pè ọ? ẽṣe ti iwọ kò fi tọ̀ mi wá? emi kò ha to lati sọ ọ di ẹni nla?
38Balaamu si wi fun Balaki pe, Kiyesi i, emi tọ̀ ọ wá: emi ha lí agbara kan nisisiyi rára lati wi ohun kan? ọ̀rọ ti OLUWA fi si mi li ẹnu, on li emi o sọ.
39Balaamu si bá Balaki lọ, nwọn si wá si Kiriati-husotu.
40Balaki si rubọ akọmalu ati agutan, o si ranṣẹ si Balaamu, ati si awọn ijoye ti mbẹ pẹlu rẹ̀.
41O si ṣe ni ijọ́ keji, ni Balaki mú Balaamu, o si mú u wá si ibi giga Baali, ki o ba le ri apakan awọn enia na lati ibẹ̀ lọ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Num 22: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: