Num 24
24
1NIGBATI Balaamu ri pe o wù OLUWA lati bukún Israeli, on kò lọ mọ́ bi ìgba iṣaju, lati wá ìfaiya, ṣugbọn o doju rẹ̀ kọ aginjù.
2Balaamu si gbé oju rẹ̀ soke o si ri Israeli dó gẹgẹ bi ẹ̀ya wọn; ẹmi Ọlọrun si wá sara rẹ̀.
3O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Balaamu ọmọ Beori nwi, ọkunrin ti oju rẹ̀ sí nwi:
4Ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun nwi, ti o nri iran Olodumare, ti o nṣubu lọ, ti oju rẹ̀ ṣí.
5Jakobu, agọ́ rẹ wọnyi ti dara tó, ati ibugbé rẹ iwọ Israeli!
6Bi afonifoji ni nwọn tẹ́ lọ bẹrẹ, bi ọgbà lẹba odònla, bi igi aloe ti OLUWA gbìn, ati bi igi kedari lẹba omi.
7Omi o ṣàn jade lati inu agbè rẹ̀ wá, irú rẹ̀ yio si wà ninu omi pupọ̀, ọba rẹ̀ yio si ga jù Agagi lọ, ijọba rẹ̀ li a o si gbeleke.
8Ọlọrun mú u lati Egipti jade wá; o ní agbara bi ti agbanrere: on o jẹ awọn orilẹ-ède ti iṣe ọtá rẹ̀ run, yio si fọ́ egungun wọn, yio si fi ọfà rẹ̀ ta wọn li atapoyọ.
9O ba, o dubulẹ bi kiniun, ati bi abo-kiniun: tani yio lé e dide? Ibukún ni fun ẹniti o sure fun ọ, ifibú si ni ẹniti o fi ọ bú.
10Ibinu Balaki si rú si Balaamu, o si fi ọwọ́ lù ọwọ́ pọ̀: Balaki si wi fun Balaamu pe, Emi pè ọ lati fi awọn ọtá mi bú, si kiyesi i iwọ si súre fun wọn patapata ni ìgba mẹta yi.
11Njẹ nisisiyi sálọ si ibujoko rẹ: emi ti rò lati sọ ọ di ẹni nla; ṣugbọn kiyesi i, OLUWA fà ọ sẹhin kuro ninu ọlá.
12Balaamu si wi fun Balaki pe, Emi kò ti sọ fun awọn onṣẹ rẹ pẹlu ti iwọ rán si mi pe,
13Bi Balaki tilẹ fẹ́ lati fi ile rẹ̀ ti o kún fun fadakà ati wurá fun mi, emi kò le rekọja ọ̀rọ OLUWA, lati ṣe rere tabi buburu lati inu ara mi wá; ṣugbọn eyiti OLUWA wi, eyina li emi o sọ?
Àsọtẹ́lẹ̀ Ìkẹyìn tí Balaamu Sọ
14Njẹ nisisiyi si kiyesi i, emi nlọ sọdọ awọn enia mi: wá, emi o si sọ fun ọ ohun ti awọn enia yi yio ṣe si awọn enia rẹ li ẹhin-ọla.
15O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Balaamu ọmọ Beori nwi, ọkunrin ti oju rẹ̀ ṣí nwi:
16Ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun nwi, ti o si mọ̀ imọ̀ Ọga-Ogo, ti o ri iran Olodumare, ti o nṣubu lọ, ti oju rẹ̀ si ṣí:
17Emi ri i, ṣugbọn ki iṣe nisisiyi: emi si wò o, ṣugbọn kò sunmọtosi: irawọ kan yio ti inu Jakobu jade wá, ọpa-alade kan yio si ti inu Israeli dide, yio si kọlù awọn igun Moabu, yio si ṣẹ́ gbogbo awọn ọmọ irọkẹ̀kẹ.
18Edomu yio si di iní, Seiri pẹlu yio si di iní, fun awọn ọtá rẹ̀; Israeli yio si ṣe iṣe-agbara.
19Lati inu Jakobu li ẹniti yio ní ijọba yio ti jade wá, yio si run ẹniti o kù ninu ilunla.
20Nigbati o si wò Amaleki, o si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Amaleki ni ekini ninu awọn orilẹ-ède; ṣugbọn igbẹhin rẹ̀ ni ki o ṣegbé.
21O si wò awọn ara Keni, o si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Agbara ni ibujoko rẹ̀, iwọ si tẹ́ itẹ́ rẹ sinu okuta.
22Ṣugbọn a o run awọn ara Keni, titi awọn ara Aṣṣuri yio kó o lọ ni igbekùn.
23O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, A, tani yio wà, nigbati Ọlọrun yio ṣe eyi!
24Awọn ọkọ̀ yio ti ebute Kittimu wá, nwọn o si pọn Aṣṣuri loju, nwọn o si pọn Eberi loju, on pẹlu yio si ṣegbé.
25Balaamu si dide, o si lọ o si pada si ibujoko rẹ̀; Balaki pẹlu si ba ọ̀na rẹ̀ lọ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Num 24: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: