Owe 24
24
1IWỌ máṣe ilara si awọn enia buburu, bẹ̃ni ki o má si ṣe fẹ lati ba wọn gbe.
2Nitoriti aiya wọn ngbiro iparun, ète wọn si nsọ̀rọ ìwa-ika.
3Ọgbọ́n li a fi ikọ ile; oye li a si fi ifi idi rẹ̀ kalẹ.
4Nipa ìmọ ni iyará fi ikún fun oniruru ọrọ̀ iyebiye ati didùn.
5Ọlọgbọ́n enia li agbara: nitõtọ enia ìmọ a sọ agbara rẹ̀ di pupọ.
6Nitori nipa ìgbimọ ọgbọ́n ni iwọ o fi ṣigun rẹ: ati ninu ọ̀pọlọpọ ìgbimọ ni iṣẹgun.
7Ọgbọ́n ga jù aṣiwère lọ: on kì yio yà ẹnu rẹ̀ ni ẹnu-bode.
8Ẹniti nhùmọ ati ṣe ibi li a o pè li enia ìwa-ika.
9Ironu wère li ẹ̀ṣẹ; irira ninu enia si li ẹlẹgàn.
10Bi iwọ ba rẹwẹsi li ọjọ ipọnju, agbara rẹ ko to nkan.
11Bi iwọ ba fà sẹhin ati gbà awọn ti a wọ́ lọ sinu ikú, ati awọn ti a yàn fun pipa.
12Ti iwọ si wipe, wò o, awa kò mọ̀ ọ; kò ha jẹ pe ẹniti ndiwọ̀n ọkàn nkiyesi i? ati ẹniti npa ọkàn rẹ mọ́, on li o mọ̀, yio si san a fun enia gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀.
13Ọmọ mi, jẹ oyin, nitoriti o dara; ati afara oyin, ti o dùn li ẹnu rẹ:
14Bẹ̃ni ìmọ ọgbọ́n yio ri si ọkàn rẹ: bi iwọ ba ri i, nigbana ni ère yio wà, a kì yio si ke ireti rẹ kuro.
15Máṣe ba ni ibuba bi enia buburu, lati gba ibujoko olododo: máṣe fi ibi isimi rẹ̀ ṣe ijẹ.
16Nitoripe olõtọ a ṣubu nigba meje, a si tun dide: ṣugbọn enia buburu yio ṣubu sinu ibi.
17Máṣe yọ̀ nigbati ọta rẹ ba ṣubu, má si ṣe jẹ ki inu rẹ ki o dùn nigbati o ba kọsẹ̀:
18Ki Oluwa ki o má ba ri i, ki o si buru li oju rẹ̀, on a si yi ibinu rẹ̀ pada kuro lori rẹ̀.
19Máṣe ilara si awọn enia buburu, má si ṣe jowu enia buburu.
20Nitoripe, ère kì yio si fun enia ibi; fitila enia buburu li a o pa.
21Ọmọ mi, iwọ bẹ̀ru Oluwa ati ọba: ki iwọ ki o má si ṣe dàpọ mọ awọn ti nṣe ayidayida.
22Nitoripe wàhala wọn yio dide lojiji, ati iparun awọn mejeji, tali o mọ̀ ọ!
Àfikún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́gbọ́n Tẹ̀síwájú sí i
23Wọnyi pẹlu ni ọ̀rọ awọn ọlọgbọ́n. Kò dara lati ṣe ojuṣãju ni idajọ.
24Ẹniti o ba wi fun enia buburu pe, olododo ni iwọ; on ni awọn enia yio bú, awọn orilẹ-ède yio si korira rẹ̀.
25Ṣugbọn awọn ti o ba a wi ni yio ni inu-didùn, ibukún rere yio si bọ̀ sori wọn.
26Yio dabi ẹniti o ṣe ifẹnukonu: ẹniti o ba ṣe idahùn rere.
27Mura iṣẹ rẹ silẹ lode, ki o si fi itara tulẹ li oko rẹ; nikẹhin eyi, ki o si kọ́ ile rẹ.
28Máṣe ẹlẹri si ẹnikeji rẹ lainidi: ki iwọ ki o má si ṣe fi ète rẹ ṣẹ̀tan.
29Máṣe wipe, bẹ̃li emi o ṣe si i, gẹgẹ bi o ti ṣe si mi: emi o san a fun ọkunrin na gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀.
30Mo kọja lọ li oko ọlẹ, ati lẹba ọgbà-ajara ẹniti oye kù fun:
31Si kiyesi i, ẹgún kún bo gbogbo rẹ̀, igbó si bo oju rẹ̀, iganna okuta rẹ̀ si wo lulẹ.
32Nigbana ni mo ri, mo si fi ọkàn mi si i gidigidi: mo wò o, mo si gbà ẹkọ́.
33Orun diẹ si i, õgbe diẹ, ikawọkòpọ lati sùn diẹ.
34Bẹ̃li òṣi rẹ yio de bi ẹniti nrìn; ati aini rẹ bi ọkunrin ti o hamọra ogun.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Owe 24: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: