Owe 9
9
Ọgbọ́n ati Wèrè
1ỌGBỌ́N ti kọ́ ile rẹ̀, o si gbẹ́ ọwọ̀n rẹ̀ meje:
2O ti pa ẹran rẹ̀; o ti ṣe àdalu ọti-waini rẹ̀; o si ti tẹ́ tabili rẹ̀.
3O ti ran awọn ọmọbinrin rẹ̀ jade, o nke lori ibi giga ilu, pe,
4Ẹnikẹni ti o ṣe òpe ki o yà si ihin: fun ẹniti oye kù fun, o wipe,
5Wá, jẹ ninu onjẹ mi, ki o si mu ninu ọti-waini mi ti mo dàlu.
6Kọ̀ iwere silẹ ki o si yè; ki o si ma rìn li ọ̀na oye.
7Ẹniti o ba ba ẹlẹgàn wi, yio gba itiju fun ara rẹ̀, ati ẹniti o ba ba enia buburu wi yio gbà àbuku rẹ̀.
8Máṣe ba ẹlẹgàn wi, ki o má ba korira rẹ, ba ọlọgbọ́n enia wi, yio si ma fẹ ọ.
9Fi ẹkọ́ fun ọlọgbọ́n enia, yio si ma gbọ́n siwaju, kọ́ enia olõtọ, yio si ma fẹ ọ.
10Ibẹ̀ru Oluwa ni ipilẹṣẹ ọgbọ́n: ati ìmọ Ẹni-Mimọ́ li oye.
11Nitori nipasẹ mi li ọjọ rẹ yio ma lé si i, ati ọdun ìye rẹ yio si ma lé si i.
12Bi iwọ ba gbọ́n, iwọ o gbọ́n fun ara rẹ: ṣugbọn bi iwọ ba iṣe ẹlẹgàn, iwọ nikan ni yio rù u.
13Alaroye li aṣiwere obinrin: òpe ni kò si mọ̀ nkan.
14O sa joko li ẹnu-ọ̀na ile rẹ̀, lori apoti, ni ibi giga ilu.
15Lati ma pè awọn ti nkọja nibẹ, ti nrìn ọ̀na ganran wọn lọ: pe,
16Ẹnikẹni ti o ba ṣe òpe, ki o yà si ìhin: ẹniti oye kù fun, o wi fun u pe,
17Omi ole dùn, ati onjẹ ikọkọ si ṣe didùn.
18Ṣugbọn on kò mọ̀ pe awọn okú wà nibẹ: ati pe awọn alapejẹ rẹ̀ wà ni isalẹ ọrun-apadi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Owe 9: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: