O. Daf 101
101
Ìlérí Ọba
1EMI o kọrin ãnu ati ti idajọ: Oluwa, si ọ li emi o ma kọrin.
2Emi o ma rìn ìrin mi pẹlu ọgbọ́n li ọ̀na pipé. Nigbawo ni iwọ o tọ̀ mi wá! emi o ma rìn ninu ile mi pẹlu aiya pipé.
3Emi ki yio gbé ohun buburu siwaju mi: emi korira iṣẹ awọn ti o yapa, kì yio fi ara mọ mi.
4Aiya ṣiṣo yio kuro lọdọ mi: emi kì yio mọ̀ enia buburu.
5Ẹnikẹni ti o ba nsọ̀rọ ẹnikeji rẹ̀ lẹhin, on li emi o ke kuro: ẹniti o ni ìwo giga ati igberaga aiya, on li emi kì yio jẹ fun.
6Oju mi yio wà lara awọn olõtọ, ki nwọn ki o le ma ba mi gbe: ẹniti o ba nrìn li ọ̀na pipé, on ni o ma sìn mi.
7Ẹniti o ba nṣe ẹ̀tan, kì o gbe inu ile mi: ẹniti o ba nsẹke kì yio duro niwaju mi.
8Lojojumọ li emi o ma run gbogbo enia buburu ilẹ na; ki emi ki o le ke gbogbo oluṣe buburu kuro ni ilu Oluwa.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
O. Daf 101: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: