O. Daf 119
119
Òfin OLUWA
1IBUKÚN ni fun awọn ẹniti o pé li ọ̀na na, ti nrìn ninu ofin Oluwa.
2Ibukún ni fun awọn ti npa ẹri rẹ̀ mọ́, ti si nwá a kiri tinu-tinu gbogbo.
3Nwọn kò dẹṣẹ pẹlu: nwọn nrìn li ọ̀na rẹ̀.
4Iwọ ti paṣẹ fun wa lati pa ẹkọ́ rẹ mọ́ gidigidi.
5Ọ̀na mi iba jẹ là silẹ lati ma pa ilana rẹ mọ́!
6Nigbana li oju kì yio tì mi, nigbati emi ba njuba aṣẹ rẹ gbogbo.
7Emi o ma fi aiya diduro-ṣinṣin yìn ọ, nigbati emi ba ti kọ́ idajọ ododo rẹ.
8Emi o pa ilana rẹ mọ́: máṣe kọ̀ mi silẹ patapata.
Pípa Òfin OLUWA mọ́
9Nipa ewo li ọdọmọkunrin yio fi mu ọ̀na rẹ̀ mọ́? nipa ikiyesi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.
10Tinu-tinu mi gbogbo li emi fi ṣe afẹri rẹ: máṣe jẹ ki emi ṣina kuro ninu aṣẹ rẹ.
11Ọ̀rọ rẹ ni mo pamọ́ li aiya mi, ki emi ki o má ba ṣẹ̀ si ọ.
12Olubukún ni iwọ, Oluwa: kọ́ mi ni ilana rẹ.
13Ẹnu mi li emi fi nsọ gbogbo idajọ ẹnu rẹ.
14Emi ti nyọ̀ li ọ̀na ẹri rẹ, bi lori oniruru ọrọ̀.
15Emi o ma ṣe àṣaro ninu ẹkọ́ rẹ emi o si ma juba ọ̀na rẹ.
16Emi o ma ṣe inu-didùn ninu ilana rẹ: emi kì yio gbagbe ọ̀rọ rẹ.
Ayọ̀ ninu Òfin OLUWA
17Fi ọ̀pọlọpọ ba iranṣẹ rẹ ṣe, ki emi ki o le wà lãye, ki emi ki o le ma pa ọ̀rọ rẹ mọ́.
18Là mi li oju, ki emi ki o le ma wò ohun iyanu wọnni lati inu ofin rẹ.
19Alejo li emi li aiye: máṣe pa àṣẹ rẹ mọ́ fun mi.
20Aiya mi bù nitori ifojusọna si idajọ rẹ nigbagbogbo.
21Iwọ ti ba awọn agberaga wi, ti a ti fi gégun, ti o ti ṣina kuro nipa aṣẹ rẹ.
22Mu ẹ̀gan ati àbuku kuro lara mi; nitoriti emi ti pa ẹri rẹ mọ́.
23Awọn ọmọ-alade joko pẹlu, nwọn nsọ̀rọ mi: ṣugbọn iranṣẹ rẹ nṣe àṣaro ninu ilana rẹ:
24Ẹri rẹ pẹlu ni didùn-inu mi ati ìgbimọ mi.
Ìpinnu láti Pa Òfin OLUWA mọ́
25Ọkàn mi lẹ̀ mọ́ erupẹ: iwọ sọ mi di ãye gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.
26Emi ti rohin ọ̀na mi, iwọ si gbohùn mi: mã kọ́ mi ni ilana rẹ.
27Mu oye ọ̀na ẹkọ́ rẹ ye mi: bẹ̃li emi o ma ṣe aṣaro iṣẹ iyanu rẹ.
28Ọkàn mi nrọ fun ãrẹ̀: iwọ mu mi lara le gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.
29Mu ọ̀na eke kuro lọdọ mi: ki o si fi ore-ọfẹ fi ofin rẹ fun mi.
30Emi ti yàn ọ̀na otitọ: idajọ rẹ ni mo fi lelẹ niwaju mi.
31Emi ti faramọ ẹri rẹ: Oluwa, máṣe dojutì mi.
32Emi o ma sare li ọ̀na aṣẹ rẹ, nitori iwọ bùn aiya mi laye.
Adura fún Òye
33Oluwa, kọ́ mi li ọ̀na rẹ; emi o si ma pa a mọ́ de opin.
34Fun mi li oye, emi o si pa ofin rẹ mọ́; nitõtọ, emi o ma kiyesi i tinutinu mi gbogbo.
35Mu mi rìn ni ipa aṣẹ rẹ; nitori ninu rẹ̀ ni didùn inu mi.
36Fa aiya mi si ẹri rẹ, ki o má si ṣe si oju-kòkoro.
37Yi oju mi pada kuro lati ma wò ohun asan; mu mi yè li ọna rẹ.
38Fi ọ̀rọ rẹ mulẹ si iranṣẹ rẹ, ti iṣe ti ìbẹru rẹ̀.
39Yi ẹ̀gan mi pada ti mo bẹ̀ru: nitori ti idajọ rẹ dara.
40Kiyesi i, ọkàn mi ti fà si ẹkọ́ rẹ: sọ mi di ãye ninu ododo rẹ.
Gbígbẹ́kẹ̀lé ninu Òfin OLUWA
41Jẹ ki ãnu rẹ ki o tọ̀ mi wá pẹlu, Oluwa, ani igbala rẹ gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.
42Bẹ̃li emi o ni ọ̀rọ ti emi o fi da ẹni ti ngàn mi lohùn; nitori mo gbẹkẹle ọ̀rọ rẹ.
43Lõtọ máṣe gbà ọ̀rọ otitọ kuro li ẹnu mi rara; nitori ti mo ti nṣe ireti ni idajọ rẹ.
44Bẹ̃li emi o ma pa ofin rẹ mọ́ patapata titi lai ati lailai.
45Bẹ̃li emi o ma rìn ni alafia; nitori ti mo wá ẹkọ́ rẹ.
46Emi o si ma sọ̀rọ ẹri rẹ niwaju awọn ọba, emi kì yio si tiju.
47Emi o si ma ṣe inu-didùn ninu aṣẹ rẹ, ti emi ti fẹ.
48Ọwọ mi pẹlu li emi o gbe soke si aṣẹ rẹ, ti emi ti fẹ; emi o si ma ṣe Ìṣàrò-ìlànà rẹ.
Igbẹkẹ le ninu Òfin OLUWA
49Ranti ọ̀rọ nì si ọmọ-ọdọ rẹ, ninu eyiti iwọ ti mu mi ṣe ireti.
50Eyi ni itunu mi ninu ipọnju mi: nitori ọ̀rọ rẹ li o sọ mi di ãye.
51Awọn agberaga ti nyọ-ṣuti si mi gidigidi: sibẹ emi kò fa sẹhin kuro ninu ofin rẹ.
52Oluwa, emi ranti idajọ atijọ; emi si tu ara mi ninu.
53Mo ni ibinujẹ nla nitori awọn enia buburu ti o kọ̀ ofin rẹ silẹ.
54Ilana rẹ li o ti nṣe orin mi ni ile atipo mi.
55Emi ti ranti orukọ rẹ Oluwa, li oru, emi si ti pa ofin rẹ mọ́.
56Eyi ni mo ni nitori ti mo pa ẹkọ rẹ mọ́.
Ìfọkànsí Òfin OLUWA
57Oluwa, iwọ ni ipin mi: emi ti wipe, emi o pa ọ̀rọ rẹ mọ́.
58Emi ti mbẹ̀bẹ oju-rere rẹ tinutinu mi gbogbo: ṣãnu fun mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.
59Emi rò ọ̀na mi, mo si yi ẹsẹ mi pada si ẹri rẹ.
60Emi yara, emi kò si lọra lati pa ofin rẹ mọ́.
61Okùn awọn enia buburu ti yi mi ka: ṣugbọn emi kò gbagbe ofin rẹ.
62Lãrin ọganjọ emi o dide lati dupẹ fun ọ nitori ododo idajọ rẹ.
63Ẹgbẹ gbogbo awọn ti o bẹ̀ru rẹ li emi, ati ti awọn ti npa ẹkọ́ rẹ mọ́.
64Oluwa, aiye kún fun ãnu rẹ: kọ́ mi ni ilana rẹ.
Iyebíye ni Òfin OLUWA
65Iwọ ti nṣe rere fun iranṣẹ rẹ Oluwa, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.
66Kọ́ mi ni ìwa ati ìmọ̀ rere; nitori ti mo gbà aṣẹ rẹ gbọ́.
67Ki a to pọ́n mi loju emi ti ṣina: ṣugbọn nisisiyi emi ti pa ọ̀rọ rẹ mọ́.
68Iwọ ṣeun iwọ si nṣe rere; kọ́ mi ni ilana rẹ.
69Awọn agberaga ti hùmọ eke si mi: ṣugbọn emi o pa ẹkọ́ rẹ mọ́ tinutinu mi gbogbo.
70Aiya wọn sebọ bi ọrá; ṣugbọn emi o ṣe inu-didùn ninu ofin rẹ.
71O dara fun mi ti a pọ́n mi loju; ki emi ki o le kọ́ ilana rẹ.
72Ofin ẹnu rẹ dara fun mi jù ẹgbẹgbẹrun wura ati fadaka lọ.
Òdodo ni Òfin OLUWA
73Ọwọ rẹ li o ti da mi, ti o si ṣe àworan mi: fun mi li oye, ki emi ki o le kọ́ aṣẹ rẹ.
74Inu awọn ti o bẹ̀ru rẹ yio dùn, nigbati nwọn ba ri mi; nitori ti mo ti reti li ọ̀rọ rẹ.
75Oluwa, emi mọ̀ pe, ododo ni idajọ rẹ, ati pe li otitọ ni iwọ pọ́n mi loju.
76Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki iṣeun-ãnu rẹ ki o mã ṣe itunu mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ si iranṣẹ rẹ.
77Jẹ ki irọnu ãnu rẹ ki o tọ̀ mi wá, ki emi ki o le yè: nitori ofin rẹ ni didùn-inu mi.
78Jẹ ki oju ki o tì agberaga; nitori ti nwọn ṣe arekereke si mi li ainidi: ṣugbọn emi o ma ṣe àṣaro ninu ẹkọ́ rẹ.
79Jẹ ki awọn ti o bẹ̀ru rẹ ki o yipada si mi, ati awọn ti o ti mọ̀ ẹri rẹ.
80Jẹ ki aiya mi ki o pé ni ilana rẹ; ki oju ki o máṣe tì mi.
Adura Ìdáǹdè
81Ọkàn mi ndaku fun igbala rẹ; ṣugbọn emi ni ireti li ọ̀rọ rẹ.
82Oju mi ṣofo nitori ọ̀rọ rẹ, wipe, Nigbawo ni iwọ o tù mi ninu?
83Nitori ti emi dabi igo-awọ loju ẽfin; ṣugbọn emi kò gbagbe ilana rẹ.
84Ijọ melo li ọjọ iranṣẹ rẹ? nigbawo ni iwọ o ṣe idajọ lara awọn ti nṣe inunibini si mi?
85Awọn agberaga ti wà ìho silẹ dè mi, ti kì iṣe gẹgẹ bi ofin rẹ.
86Otitọ li aṣẹ rẹ gbogbo: nwọn fi arekereke ṣe inunibini si mi: iwọ ràn mi lọwọ.
87Nwọn fẹrẹ run mi li ori ilẹ; ṣugbọn emi kò kọ ẹkọ́ rẹ silẹ.
88Sọ mi di ãye gẹgẹ bi iṣeun-ãnu rẹ; bẹ̃li emi o pa ẹri ẹnu rẹ mọ́.
Igbagbọ ninu Òfin OLUWA
89Oluwa, lai, ọ̀rọ rẹ kalẹ li ọrun.
90Lati iran-diran li otitọ rẹ; iwọ ti fi idi aiye mulẹ, o si duro.
91Nwọn duro di oni nipa idajọ rẹ: nitori pe iranṣẹ rẹ ni gbogbo wọn.
92Bikoṣepe bi ofin rẹ ti ṣe inu-didùn mi, emi iba ti ṣegbe ninu ipọnju mi.
93Lai emi kì yio gbagbe ẹkọ́ rẹ; nitori pe awọn ni iwọ fi sọ mi di ãye.
94Tirẹ li emi, gbà mi; nitori ti emi wá ẹkọ́ rẹ.
95Awọn enia buburu ti duro dè mi lati pa mi run: ṣugbọn emi o kiyesi ẹri rẹ.
96Emi ti ri opin ohun pipé gbogbo: ṣugbọn aṣẹ rẹ gbõro gidigidi.
Ìfẹ́ sí Òfin OLUWA
97Emi ti fẹ ofin rẹ to! iṣaro mi ni li ọjọ gbogbo.
98Nipa aṣẹ rẹ iwọ mu mi gbọ́n jù awọn ọta mi lọ: nitori ti o wà pẹlu mi lailai.
99Emi ni iyè ninu jù gbogbo awọn olukọ mi lọ, nitoripe ẹri rẹ ni iṣaro mi.
100Oye ye mi jù awọn àgba lọ, nitori ti mo pa ẹkọ́ rẹ mọ́.
101Mo ti fà ẹsẹ mi sẹhin kuro nipa ọ̀na ibi gbogbo, ki emi ki o le pa ọ̀rọ rẹ mọ́.
102Emi kò yà kuro ni idajọ rẹ: nitoripe iwọ li o kọ́ mi.
103Ọ̀rọ rẹ ti dùn mọ́ mi li ẹnu to! jù oyin lọ li ẹnu mi!
104Nipa ẹkọ́ rẹ emi ni iyè ninu: nitorina mo korira ọ̀na eke gbogbo.
Ìmọ́lẹ̀ láti Inú Òfin OLUWA
105Ọ̀rọ rẹ ni fitila fun ẹsẹ̀ mi, ati imọlẹ si ipa ọ̀na mi.
106Emi ti bura, emi o si mu u ṣẹ, pe, emi o pa idajọ ododo rẹ mọ́.
107A pọ́n mi loju gidigidi: Oluwa sọ mi di ãye, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.
108Emi bẹ̀ ọ, Oluwa, gbà ọrẹ atinuwa ẹnu mi, ki o si kọ́ mi ni idajọ rẹ.
109Ọkàn mi wà li ọwọ mi nigbagbogbo: emi kò si gbagbe ofin rẹ.
110Awọn enia buburu ti dẹkun silẹ fun mi: ṣugbọn emi kò ṣina kuro nipa ẹkọ́ rẹ.
111Ẹri rẹ ni ogún mi lailai: nitori awọn li ayọ̀ inu mi.
112Emi ti fà aiya mi si ati pa ilana rẹ mọ́ nigbagbogbo, ani de opin.
Ààbò ninu Òfin OLUWA
113Emi korira oniye meji: ṣugbọn ofin rẹ ni mo fẹ.
114Iwọ ni ibi ipamọ́ mi ati asà mi: emi nṣe ireti ninu ọ̀rọ rẹ.
115Kuro lọdọ mi, ẹnyin oluṣe-buburu: emi o si pa ofin Ọlọrun mi mọ́.
116Gbé mi soke gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ, ki emi ki o le yè: ki o má si jẹ ki oju ireti mi ki o tì mi.
117Gbé mi soke, emi o si wà li ailewu: emi o si juba ìlana rẹ nigbagbogbo.
118Iwọ ti tẹ̀ gbogbo awọn ti o ṣina kuro ninu ilana rẹ mọlẹ: nitori pe ẹ̀tan ni ironu wọn.
119Iwọ ṣá gbogbo awọn enia buburu aiye tì bi ìdarọ́: nitorina emi fẹ ẹri rẹ.
120Ara mi warìri nitori ìbẹru rẹ; emi si bẹ̀ru idajọ rẹ.
Pípa Òfin OLUWA mọ́
121Emi ti ṣe idajọ ati ododo: iwọ kì yio jọwọ mi lọwọ fun awọn aninilara mi.
122Ṣe onigbọwọ fun iranṣẹ rẹ fun rere: máṣe jẹ ki awọn agberaga ki o ni mi lara.
123Oju kún mi nitori igbala rẹ, ati nitori ọ̀rọ ododo rẹ.
124Ṣe si iranṣẹ rẹ gẹgẹ bi ãnu rẹ, ki o si kọ́ mi ni ilana rẹ.
125Iranṣẹ rẹ li emi: fun mi li oye, emi o si mọ̀ ẹri rẹ.
126Oluwa, o to akokò fun ọ lati ṣiṣẹ: nitori ti nwọn ti sọ ofin rẹ di ofo.
127Nitorina emi fẹ aṣẹ rẹ jù wura, ani, jù wura didara lọ.
128Nitorina emi kà gbogbo ẹkọ́ rẹ si otitọ patapata: emi si korira gbogbo ọ̀na eke.
Ìfẹ́ láti Pa Òfin OLUWA Mọ́
129Iyanu li ẹri rẹ: nitorina li ọkàn mi ṣe pa wọn mọ́.
130Ifihan ọ̀rọ rẹ funni ni imọlẹ; o si fi oye fun awọn òpe.
131Emi yà ẹnu mi, emi mí hẹlẹ: nitori ti ọkàn mi fà si aṣẹ rẹ.
132Iwọ bojuwò mi; ki o si ṣãnu fun mi, gẹgẹ bi iṣe rẹ si awọn ti o fẹ orukọ rẹ.
133Fi iṣisẹ mi mulẹ ninu ọ̀rọ rẹ: ki o má si jẹ ki ẹ̀ṣẹkẹṣẹ ki o jọba lori mi.
134Gbà mi lọwọ inilara enia; bẹ̃li emi o si ma pa ẹkọ́ rẹ mọ́.
135Ṣe oju rẹ ki o mọlẹ si iranṣẹ rẹ lara; ki o si kọ mi ni ilana rẹ.
136Odò omi ṣàn silẹ li oju mi nitori nwọn kò pa ofin rẹ mọ́.
Òtítọ́ ni Òfin OLUWA
137Olododo ni iwọ, Oluwa, ati diduro-ṣinṣin ni idajọ rẹ.
138Iwọ paṣẹ ẹri rẹ li ododo ati otitọ gidigidi.
139Itara mi ti pa mi run nitori ti awọn ọta mi ti gbagbe ọ̀rọ rẹ.
140Funfun gbò li ọ̀rọ rẹ: nitorina ni iranṣẹ rẹ ṣe fẹ ẹ.
141Emi kere ati ẹni ẹ̀gan ni: ṣugbọn emi kò gbagbe ẹkọ́ rẹ.
142Ododo rẹ ododo lailai ni, otitọ si li ofin rẹ.
143Iyọnu ati àrokan dì mi mu: ṣugbọn aṣẹ rẹ ni inu-didùn mi.
144Ododo ẹri rẹ aiye-raiye ni: fun mi li oye, emi o si yè.
Adura Ìdáǹdè
145Tinu-tinu mi gbogbo ni mo fi kigbe; Oluwa, da mi lohùn; emi o pa ilana rẹ mọ́.
146Emi kigbe si ọ; gbà mi là, emi o si ma pa ẹri rẹ mọ́.
147Emi ṣaju kutukutu owurọ, emi ke: emi nṣe ireti ninu ọ̀rọ rẹ.
148Oju mi ṣaju iṣọ-oru, ki emi ki o le ma ṣe iṣaro ninu ọ̀rọ rẹ.
149Gbohùn mi gẹgẹ bi ãnu rẹ: Oluwa, sọ mi di ãye gẹgẹ bi idajọ rẹ.
150Awọn ti nlepa ìwa-ika sunmọ itosi: nwọn jina si ofin rẹ.
151Oluwa, iwọ wà ni itosi: otitọ si ni gbogbo aṣẹ rẹ.
152Lati inu ẹri rẹ, emi ti mọ̀ nigba atijọ pe, iwọ ti fi idi wọn mulẹ lailai.
Ẹ̀bẹ̀ fún Ìrànlọ́wọ́
153Wò ipọnju mi, ki o si gbà mi: nitori ti emi kò gbagbe ofin rẹ.
154Gbà ẹjọ mi rò, ki o rà mi pada: sọ mi di ãye nipa ọ̀rọ rẹ.
155Igbala jina si awọn enia buburu: nitori ti nwọn kò wá ilana rẹ.
156Ọ̀pọ ni irọnu ãnu rẹ, Oluwa: sọ mi di ãye gẹgẹ bi idajọ rẹ.
157Ọ̀pọ li awọn oninunibini mi ati awọn ọta mi; ṣugbọn emi kò fà sẹhin kuro ninu ẹri rẹ.
158Emi wò awọn ẹlẹtan, inu mi si bajẹ; nitori ti nwọn kò pa ọ̀rọ rẹ mọ́.
159Wò bi emi ti fẹ ẹkọ́ rẹ: Oluwa, sọ mi di ãye gẹgẹ bi ãnu rẹ.
160Otitọ ni ipilẹṣẹ ọ̀rọ rẹ; ati olukulùku idajọ ododo rẹ duro lailai.
Fífi Ara Ẹni fún Òfin OLUWA
161Awọn ọmọ-alade ṣe inunibini si mi li ainidi: ṣugbọn ọkàn mi warìri nitori ọ̀rọ rẹ.
162Emi yọ̀ si ọ̀rọ rẹ, bi ẹniti o ri ikogun pupọ.
163Emi korira, mo si ṣe họ̃ si eke ṣiṣe: ṣugbọn ofin rẹ ni mo fẹ.
164Nigba meje li õjọ li emi nyìn ọ nitori ododo idajọ rẹ.
165Alafia pupọ̀ li awọn ti o fẹ ofin rẹ ni: kò si si ohun ikọsẹ fun wọn.
166Oluwa, emi ti nreti igbala rẹ, emi si ṣe aṣẹ rẹ.
167Ọkàn mi ti pa ẹri rẹ mọ́; emi si fẹ wọn gidigidi.
168Emi ti npa ẹkọ́ ati ẹri rẹ mọ́; nitori ti gbogbo ọ̀na mi mbẹ niwaju rẹ.
Adura Ìrànlọ́wọ́
169Oluwa, jẹ ki ẹkún mi ki o sunmọ iwaju rẹ: fun mi li oye gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.
170Jẹ ki ẹ̀bẹ mi ki o wá siwaju rẹ: gbà mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.
171Ete mi yio sọ iyìn jade, nigbati iwọ ba ti kọ́ mi ni ilana rẹ.
172Ahọn mi yio sọ niti ọ̀rọ rẹ: nitori pe ododo ni gbogbo aṣẹ rẹ.
173Jẹ ki ọwọ rẹ ki o ràn mi lọwọ; nitori ti mo ti yàn ẹkọ rẹ.
174Oluwa, ọkàn mi ti fà si igbala rẹ; ofin rẹ si ni didùn-inu mi.
175Jẹ ki ọkàn mi ki o wà lãye, yio si ma yìn ọ; si jẹ ki idajọ rẹ ki o ma ràn mi lọwọ.
176Emi ti ṣina kiri bi agutan ti o nù; wá iranṣẹ rẹ nitori ti emi kò gbagbe aṣẹ rẹ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
O. Daf 119: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: