O. Daf 13

13
Adura Ìrànlọ́wọ́
1IWỌ o ti gbagbe mi pẹ to, Oluwa, lailai? iwọ o ti pa oju rẹ mọ́ pẹ to kuro lara mi?
2Emi o ti ma gbìmọ li ọkàn mi pẹ to? ti emi o ma ni ibinujẹ li ọkàn mi lojojumọ? ọta mi yio ti gberaga sori mi pẹ to?
3Rò o, ki o si gbohùn mi, Oluwa Ọlọrun mi: mu oju mi mọlẹ, ki emi ki o má ba sùn orun ikú.
4Ki ọta mi ki o má ba wipe, emi ti ṣẹgun rẹ̀; awọn ti nyọ mi lẹnu a si ma yọ̀, nigbati a ba ṣi mi nipò.
5Ṣugbọn emi o gbẹkẹle ãnu rẹ; ọkàn mi yio yọ̀ ni igbala rẹ.
6Emi o ma kọrin si Oluwa, nitoriti o ṣe fun mi li ọ̀pọlọpọ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 13: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀