O. Daf 41

41
Adura Ẹni tí ń Ṣàìsàn
1IBUKÚN ni fun ẹniti nrò ti awọn alaini, Oluwa yio gbà a ni ìgbà ipọnju.
2Oluwa yio pa a mọ́, yio si mu u wà lãye; a o si bukún fun u lori ilẹ: iwọ kì yio si fi i le ifẹ awọn ọta rẹ̀ lọwọ.
3Oluwa yio gbà a ni iyanju lori ẹní àrun: iwọ o tẹ ẹní rẹ̀ gbogbo ni ibulẹ arun rẹ̀.
4Emi wipe, Oluwa ṣãnu fun mi: mu ọkàn mi lara da; nitori ti mo ti ṣẹ̀ si ọ.
5Awọn ọta mi nsọ ibi si mi pe, nigbawo ni on o kú, ti orukọ rẹ̀ yio si run?
6Bi o ba si wá wò mi, on a ma sọ̀rọ ẹ̀tan: aiya rẹ̀ kó ẹ̀ṣẹ jọ si ara rẹ̀; nigbati o ba jade lọ, a ma wi i.
7Gbogbo awọn ti o korira mi jumọ nsọ̀rọ kẹlẹ́ si mi: emi ni nwọn ngbìmọ ibi si.
8Pe, ohun buburu li o dì mọ ọ ṣinṣin: ati ibiti o dubulẹ si, kì yio dide mọ.
9Nitõtọ ọrẹ-iyọrẹ ara mi, ẹniti mo gbẹkẹle, ẹniti njẹ ninu onjẹ mi, o gbe gigisẹ rẹ̀ si mi.
10Ṣugbọn iwọ, Oluwa, ṣãnu fun mi, ki o si gbé mi dide, ki emi ki o le san a fun wọn.
11Nipa eyi ni mo mọ̀ pe iwọ ṣe oju-rere si mi, nitoriti awọn ọta mi kò yọ̀ mi.
12Bi o ṣe ti emi ni, iwọ dì mi mu ninu ìwatitọ mi, iwọ si gbé mi kalẹ niwaju rẹ titi lai.
13Olubukún ni Oluwa, Ọlọrun Israeli, lailai titi lai. Amin, Amin.
IWE II

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 41: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀