Ifi 18
18
Babiloni tú
1LẸHIN nkan wọnyi mo si ri angẹli miran, o nti ọrun sọkalẹ wá ti on ti agbara nla; ilẹ aiye si ti ipa ogo rẹ̀ mọlẹ.
2O si kigbe li ohùn rara, wipe, Babiloni nla ṣubu, o ṣubu, o si di ibujoko awọn ẹmi èṣu, ati ihò ẹmí aimọ́ gbogbo, ati ile ẹiyẹ aimọ́ gbogbo, ati ti ẹiyẹ irira.
3Nitori nipa ọti-waini irunu àgbere rẹ̀ ni gbogbo awọn orilẹ-ede ṣubu, awọn ọba aiye si ti ba a ṣe àgbere, ati awọn oniṣowo aiye si di ọlọrọ̀ nipa ọ̀pọlọpọ wọbia rẹ̀.
4Mo si gbọ́ ohùn miran lati ọrun wá, nwipe, Ẹ ti inu rẹ̀ jade, ẹnyin enia mi, ki ẹ má bã ṣe alabapin ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ki ẹ má bã si ṣe gbà ninu iyọnu rẹ̀.
5Nitori awọn ẹ̀ṣẹ rẹ̀ gá ani de ọrun, Ọlọrun si ti ranti aiṣedẽdẽ rẹ̀.
6San a fun u, ani bi on ti san fun-ni, ki o si ṣe e ni ilọpo meji fun u gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀: ninu ago na ti o ti kùn, on ni ki ẹ si kún fun u ni meji.
7Niwọn bi o ti yin ara rẹ̀ logo to, ti o si huwa wọbia, niwọn bẹ̃ ni ki ẹ da a loro ki ẹ si fún u ni ibanujẹ: nitoriti o wi li ọkàn rẹ̀ pe, mo joko bi ọbabirin, emi kì si iṣe opó, emi ki yio si ri ibinujẹ lai.
8Nitorina ni ijọ kan ni iyọnu rẹ̀ yio de, ikú, ati ibinujẹ, ati ìyan; a o si fi iná sun u patapata: nitoripe alagbara ni Oluwa Ọlọrun ti nṣe idajọ rẹ̀.
9Ati awọn ọba aiye, ti o ti mba a ṣe àgbere, ti nwọn si mba a hu iwà wọbia, yio si pohùnrere ẹkún le e lori, nigbati nwọn ba wo ẹ̃fin ijona rẹ̀.
10Nwọn o duro li okere rére nitori ibẹru iṣẹ oró rẹ̀, nwọn o mã wipe, Egbé, Egbé ni fun ilu nla na, Babiloni, ilu alagbara ni! nitori ni wakati kan ni idajọ rẹ de.
11Awọn oniṣowo aiye si nsọkun, nwọn si nṣọ̀fọ lori rẹ̀; nitoripe ẹnikẹni kò rà ọjà wọn mọ́:
12Ọjà wura, ati ti fadaka, ati ti okuta iyebiye, ati ti perli, ati ti aṣọ ọgbọ wíwe, ati ti elese aluko, ati ti ṣẹ́dà, ati ti ododó, ati ti gbogbo igi olõrun didun, ati ti olukuluku ohun èlo ti ehin-erin, ati ti olukuluku ohun èlo ti a fi igi iyebiye ṣe, ati ti idẹ, ati ti irin, ati ti okuta marbili,
13Ati ti kinamoni, ati ti oniruru ohun olõrun didun, ati ti ohun ikunra, ati ti turari, ati ti ọti-waini, ati ti oróro, ati ti iyẹfun daradara, ati ti alikama, ati ti ẹranlá, ati ti agutan, ati ti ẹṣin, ati ti kẹkẹ́, ati ti ẹrú, ati ti ọkàn enìa.
14Ati awọn eso ti ọkàn rẹ nṣe ifẹkufẹ si, sì lọ kuro lọdọ rẹ, ati ohun gbogbo ti o dùn ti o si dara ṣegbe mọ ọ loju, a kì yio si tún ri wọn mọ́ lai.
15Awọn oniṣowo nkan wọnyi, ti a ti ipa rẹ̀ sọ di ọlọrọ̀, yio duro li òkere rére nitori ìbẹru iṣẹ oró rẹ̀, nwọn o mã sọkun, nwọn o si mã ṣọ̀fọ,
16Wipe, Ègbé, egbé ni fun ilu nla nì, ti a wọ̀ li aṣọ ọgbọ wíwẹ, ati ti elese aluko, ati ti ododó, ati ti a si fi wura ṣe lọṣọ́, pẹlu okuta iyebiye ati perli!
17Nitoripe ni wakati kan ni ọrọ̀ ti o pọ̀ tobẹ̃ di asan. Ati olukuluku olori ọkọ̀, ati olukuluku ẹniti nrin oju omi lọ si ibikibi, ati awọn ti nṣiṣẹ, ninu ọkọ̀, ati awọn ti nṣowo oju okun duro li òkere rére,
18Nwọn si kigbe nigbati nwọn ri ẹ̃fin jijona rẹ̀, wipe, Ilu wo li o dabi ilu nla yi?
19Nwọn si kù ekuru si ori wọn, nwọn kigbe, nwọn sọkun, nwọn si nṣọfọ, wipe, Egbé, Egbé ni fun ilu nla na, ninu eyi ti a sọ gbogbo awọn ti o ni ọkọ̀ li okun di ọlọrọ̀ nipa ohun iyebiye rẹ̀! nitoripe ni wakati kan a sọ ọ di ahoro.
20Yọ̀ lori rẹ̀, iwọ ọrun, ati ẹnyin aposteli mimọ́ ati woli; nitori Ọlọrun ti gbẹsan nyin lara rẹ̀.
21Angẹli alagbara kan si gbé okuta kan soke, o dabi ọlọ nla, o si jù u sinu okun, wipe, Bayi li a o fi agbara nla bì Babiloni ilu nla nì wó, a kì yio si ri i mọ́ lai.
22Ati ohùn awọn aludùru, ati ti awọn olorin, ati ti awọn afunfère, ati ti awọn afunpè ni a kì yio si gbọ́ ninu rẹ mọ́ rara; ati olukuluku oniṣọnà ohunkohun ni a kì yio si ri ninu rẹ mọ́ lai; ati iró ọlọ li a kì yio si gbọ́ mọ́ ninu rẹ lai;
23Ati imọlẹ fitila ni kì yio si tàn ninu rẹ mọ́ lai; a ki yio si gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ti iyawo ninu rẹ mọ́ lai: nitoripe awọn oniṣowo rẹ li awọn ẹni nla aiye; nitoripe nipa oṣó rẹ li a fi tàn orilẹ-ède gbogbo jẹ.
24Ati ninu rẹ̀ li a gbé ri ẹ̀jẹ awọn woli, ati ti awọn enia mimọ́, ati ti gbogbo awọn ti a pa lori ilẹ aiye.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Ifi 18: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: