Ifi 7
7
Ọ̀kẹ́ Meje Ó Lé Ẹgbaaji (144,000) Eniyan Israẹli
1LẸHIN eyi ni mo ri angẹli mẹrin duro ni igun mẹrẹrin aiye, nwọn di afẹfẹ mẹrẹrin aiye mu, ki o máṣe fẹ́ sori ilẹ, tabi sori okun, tabi sara igikigi.
2Mo si ri angẹli miran ti o nti ìha ìla-õrùn goke wá, ti on ti èdidi Ọlọrun alãye lọwọ: o si kigbe li ohùn rara si awọn angẹli mẹrin na ti a fifun lati pa aiye ati okun lara,
3Wipe, Ẹ máṣe pa aiye, tabi okun, tabi igi lara, titi awa o fi fi èdidi sami si awọn iranṣẹ Ọlọrun wa ni iwaju wọn.
4Mo si gbọ́ iye awọn ẹniti a fi èdidi sami si: awọn ti a sami si jẹ ọkẹ́ meje o le ẹgbaji lati inu gbogbo ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli wá.
5Lati inu ẹ̀ya Juda a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Reubeni a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Gadi a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa.
6Lati inu ẹ̀ya Aṣeri a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Neftalimu a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Manasse a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa.
7Lati inu ẹ̀ya Simeoni a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Lefi a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Issakari a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa.
8Lati inu ẹ̀ya Sebuloni a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Josefu a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Benjamini a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa.
Àwọn Aṣẹ́gun láti Gbogbo Orílẹ̀-Èdè
9Lẹhin na, mo ri, si kiyesi i, ọ̀pọlọpọ enia ti ẹnikẹni kò le kà, lati inu orilẹ-ède gbogbo, ati ẹya, ati enia, ati lati inu ède gbogbo wá, nwọn duro niwaju itẹ́, ati niwaju Ọdọ-Agutan na, a wọ̀ wọn li aṣọ funfun, imọ̀-ọpẹ si mbẹ li ọwọ́ wọn;
10Nwọn si kigbe li ohùn rara, wipe, Igbala ni ti Ọlọrun wa ti o joko lori itẹ́, ati ti Ọdọ-Agutan.
11Gbogbo awọn angẹli si duro yi itẹ́ na ká, ati yi awọn àgba ati awọn ẹda alãye mẹrin na ká, nwọn wolẹ nwọn si dojubolẹ niwaju itẹ́ na nwọn si sìn Ọlọrun,
12Wipe, Amin: Ibukún, ati ogo, ati ọgbọ́n, ati ọpẹ́, ati agbara, ati ipá fun Ọlọrun wa lai ati lailai. Amin.
13Ọkan ninu awọn àgba na si dahùn, o bi mi pe, Tali awọn wọnyi ti a wọ̀ li aṣọ funfun nì? nibo ni nwọn si ti wá?
14Mo si wi fun u pe, Oluwa mi, Iwọ li o le mọ̀. O si wi fun mi pe, Awọn wọnyi li o jade lati inu ipọnju nla, nwọn si fọ̀ aṣọ wọn, nwọn si sọ wọn di funfun ninu ẹ̀jẹ Ọdọ-Agutan na.
15Nitorina ni nwọn ṣe mbẹ niwaju itẹ́ Ọlọrun, ti nwọn si nsìn i li ọsán ati li oru ninu tẹmpili rẹ̀: ẹniti o joko lori itẹ́ na yio si ṣiji bò wọn.
16Ebi kì yio pa wọn mọ́, bẹ̃li ongbẹ kì yio gbẹ wọn mọ́; bẹ̃li õrùn kì yio pa wọn tabi õrukõru.
17Nitori Ọdọ-Agutan ti mbẹ li arin itẹ́ na ni yio mã ṣe oluṣọ-agutan wọn, ti yio si mã ṣe amọna wọn si ibi orisun omi iyè: Ọlọrun yio si nù omije gbogbo nù kuro li oju wọn.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Ifi 7: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: