Ifi 9
9
1ANGẸLI karun si fun, mo si ri irawọ kan bọ́ si ilẹ lati ọrun wá: a si fi iṣika iho ọgbun fun u.
2O si ṣí iho ọgbun na; ẹ̃fin si ru jade lati inu iho na wá, bi ẹ̃fin ileru nla; õrùn ati oju sanma si ṣõkun nitori ẹ̃fin iho na.
3Ẽṣú si jade ti inu ẹ̃fin na wá sori ilẹ: a si fi agbara fun wọn bi akẽkẽ ilẹ ti li agbara.
4A si sọ fun wọn pe ki nwọn ki o máṣe pa koriko ilẹ lara, tabi ohun tutù kan, tabi igikigi kan; bikoṣe awọn enia ti kò ni èdidi Ọlọrun ni iwaju wọn.
5A si paṣẹ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe pa wọn, ṣugbọn ki a dá wọn li oró li oṣù marun: oró wọn si dabi oró akẽkẽ, nigbati o ba ta enia.
6Li ọjọ wọnni li awọn enia yio si mã wá ikú, nwọn kì yio si ri i; nwọn o si fẹ lati kú, ikú yio si sá kuro lọdọ wọn.
7Iré awọn ẽṣú na si dabi awọn ẹṣin ti a mura silẹ fun ogun; ati li ori wọn ni bi ẹnipe awọn ade ti o dabi wura wà, oju wọn si dabi oju enia;
8Nwọn si ni irun bi irun obinrin, ehin wọn si dabi ti kiniun.
9Nwọn si ni awo ìgbàiya, bi awo ìgbàiya irin; iró iyẹ́ wọn si dabi iró kẹkẹ́ ẹṣin pupọ̀ ti nsúré lọ si ogun.
10Nwọn si ni ìru ati oró bi ti akẽkẽ, ati ni ìru wọn ni agbara wọn wà lati pa enia lara fun oṣù marun.
11Nwọn ni angẹli ọgbun na bi ọba lori wọn, orukọ rẹ̀ li ede Heberu ni Abaddoni, ati li ède Griki orukọ rẹ̀ amã jẹ Apollioni.
12Egbé kan kọja; kiyesi i, egbé meji mbọ̀ sibẹ lẹhin eyi.
13Angẹli kẹfa si fun, mo si gbọ́ ohùn kan lati ibi iwo mẹrin pẹpẹ wura wá, ti mbẹ niwaju Ọlọrun,
14Nwi fun angẹli kẹfa na ti o ni ipè na pe, Tú awọn angẹli mẹrin nì silẹ ti a dè lẹba odò nla Eufrate.
15A si tú awọn angẹli mẹrin na silẹ, ti a ti pese tẹlẹ fun wakati na, ati ọjọ na, ati oṣù na, ati ọdun na, lati pa idamẹta enia.
16Iye ogun awọn ẹlẹṣin si jẹ ãdọta ọkẹ́ lọna igba: mo si gbọ́ iye wọn.
17Bayi ni mo si ri awọn ẹṣin na li ojuran, ati awọn ti o gùn wọn; nwọn ni awo ìgbaiya iná, ati ti jakinti, ati ti imí ọjọ: ori awọn ẹṣin na si dabi ori awọn kiniun; ati lati ẹnu wọn ni iná, ati ẹ̃fin, ati imí ọjọ ti njade.
18Nipa iyọnu mẹta wọnyi li a ti pa idamẹta enia, nipa iná, ati nipa, ẹ̃fin, ati nipa imí ọjọ ti o nti ẹnu wọn jade.
19Nitoripe agbara awọn ẹṣin na mbẹ li ẹnu wọn ati ni iru wọn: nitoripe ìru wọn dabi ejò, nwọn si ni ori, awọn wọnyi ni nwọn si fi npa-ni-lara.
20Ṣugbọn awọn enia iyokù, ti a kò si ti ipa iyọnu wọnyi pa, kò si ronupiwada iṣẹ́ ọwọ́ wọn, ki nwọn ki o máṣe sìn awọn ẹmi èṣu, ati ere wura, ati ti fadaka, ati ti idẹ, ati ti okuta, ati ti igi mọ́, awọn ti kò le riran, tabi ki nwọn gbọran, tabi ki nwọn rìn:
21Bẹ̃ni nwọn kò ronupiwada enia pipa wọn, tabi oṣó wọn, tabi àgbere wọn, tabi olè wọn.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Ifi 9: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: