Ifi Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ní àkókò tí wọn ń ṣe inúnibíni sí àwọn onigbagbọ nítorí gbígbà tí wọ́n gba Jesu bí Oluwa ni a kọ Ìwé Ìfihàn Jesu fún Johanu. Ohun tí ó jẹ ẹni tí ó kọ ìwé yìí lógún jùlọ ni láti fún àwọn olùka ìwé náà ní ìrètí, láti mú wọn lọ́kàn le, ati láti rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ní àkókò ìjìyà ati inúnibíni.
Oríṣìíríṣìí ìran ati ìṣípayá ni ó tẹ̀lé ara wọn ninu ìwé yìí. Ó ní láti jẹ́ pé èdè tí ẹni tí ó kọ ìwé yìí fi kọ ọ́ yé àwọn tí ó kọ ọ́ sí nígbà náà, ṣugbọn bí àdììtú ni ó rí fún gbogbo àwọn ẹlòmíràn. Bí àwọn olórin ti máa ń tẹnumọ́ ohun tí ó bá jẹ́ kókó ninu ọ̀rọ̀ orin wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó kọ ìwé yìí ń tẹnumọ́ kókó ọ̀rọ̀ ìwé náà lemọ́lemọ́ ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà, ninu oríṣìíríṣìí ìran tí ó rí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èrò yàtọ̀ sí ara wọn lórí ìtumọ̀ ìwé yìí, ohun tí ó jẹ́ kókó tí ó wà ní ààrin gbùngbùn rẹ̀ hàn gedegbe. Òun sì ni pé nípasẹ̀ Kristi Oluwa, Ọlọrun yóo ṣẹgun gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ patapata níkẹyìn, tí ó fi kan Èṣù. Ọlọrun yóo sì fún àwọn eniyan rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olódodo ní èrè. Èrè tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ni ibukun ọ̀run titun ati ayé titun tí yóo dé lẹ́yìn tí Ọlọrun bá ti ṣẹgun patapata.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1-8
Ìran tí ó ṣáájú ati ìwé sí àwọn ìjọ meje 1:9—3:22
Ìwé tí a fi èdìdì meje dì 4:1—8:1
Fèrè meje 8:2—11:19
Ẹranko Ewèlè ati àwọn ẹranko meji kan 12:1—13:18
Oríṣìíríṣìí ìran 14:1—15:8
Àwo meje tí ó kún fún ibinu Ọlọrun 16:1-21
Ìparun Babiloni ati ìṣẹ́gun ẹranko náà ati ti wolii èké ati ti Èṣù 17:1—20:10
Ìdájọ́ ìkẹyìn 20:11-15
Ọ̀run titun ati ayé titun, Jerusalẹmu titun 21:1—22:5
Ọ̀rọ̀ ìparí 22:6-21
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Ifi Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: