Sek 3
3
Ìran wolii náà nípa Olórí Àlùfáà
1O sì fi Joṣua olori alufa hàn mi, o duro niwaju angeli Oluwa, Satani si duro lọwọ ọtun rẹ̀ lati kọju ijà si i.
2Oluwa si wi fun Satani pe, Oluwa ba ọ wi, iwọ Satani; ani Oluwa ti o ti yàn Jerusalemu, o ba ọ wi: igi iná kọ eyi ti a mu kuro ninu iná?
3A si wọ̀ Joṣua li aṣọ ẽri, o si duro niwaju angeli na.
4O si dahùn o wi fun awọn ti o duro niwaju rẹ̀ pe, Bọ aṣọ ẽri nì kuro li ara rẹ̀. O si wi fun u pe, Wò o, mo mu ki aiṣedẽde rẹ kuro lọdọ rẹ, emi o si wọ̀ ọ li aṣọ ẹyẹ.
5Mo si wipe, Jẹ ki wọn fi lawàni mimọ́ wé e li ori. Nwọn si fi lawàni mimọ́ wé e lori, nwọn si fi aṣọ wọ̀ ọ. Angeli Oluwa si duro tì i.
6Angeli Oluwa si tẹnu mọ fun Joṣua pe,
7Bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; bi iwọ o ba rìn li ọ̀na mi, bi iwọ o ba si pa aṣẹ mi mọ, iwọ o si ṣe idajọ ile mi pẹlu, iwọ o si pa ãfin mi mọ pẹlu, emi o si fun ọ li àye ati rìn lãrin awọn ti o duro yi.
8Gbọ́ na, iwọ Joṣua olori alufa, iwọ, ati awọn ẹgbẹ́ rẹ ti o joko niwaju rẹ: nitori ẹni iyanu ni nwọn: nitori kiyesi i, emi o mu iranṣẹ mi, ẸKA, wá.
9Nitori kiyesi i, okuta ti mo ti gbe kalẹ niwaju Joṣua; lori okuta kan ni oju meje o wà: kiyesi i, emi o fin finfin rẹ̀, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, emi o si mu aiṣedẽde ilẹ na kuro ni ijọ kan.
10Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, ni ọjọ na ni olukuluku yio pe ẹnikeji rẹ̀ sabẹ igi àjara ati sabẹ igi ọpọ̀tọ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Sek 3: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: