Sek 9
9
Ìdájọ́ lórí Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tí Wọ́n Yí Israẹli Ká
1Ọ̀RỌ-ÌMỌ ọ̀rọ Oluwa ni ilẹ Hadraki, Damasku ni yio si jẹ ibi isimi rẹ̀: nitori oju Oluwa mbẹ lara enia, ati lara gbogbo ẹ̀ya Israeli.
2Ati Hamati pẹlu yio ṣe ãla rẹ̀: Tire ati Sidoni bi o tilẹ ṣe ọlọgbọ́n gidigidi.
3Tire si mọ odi lile fun ara rẹ̀, o si ko fàdakà jọ bi ekuru, ati wurà daradara bi ẹrẹ̀ ita.
4Kiye si i, Oluwa yio tá a nù, yio si kọlu ipá rẹ̀ ninu okun; a o si fi iná jẹ ẹ run.
5Aṣkeloni yio ri i, yio si bẹ̀ru; Gasa pẹlu yio ri i, yio si kãnu gidigidi, ati Ekroni: nitori oju o tì ireti rẹ̀: ọba yio si ṣegbe kuro ni Gasa, a kì o si gbe Aṣkeloni.
6Ọmọ alè yio si gbe inu Aṣdodi, emi o si ke irira awọn Filistini kuro.
7Emi o si mu ẹ̀jẹ rẹ̀ kuro li ẹnu rẹ̀, ati ohun irira rẹ̀ wọnni kuro lãrin ehín rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o kù, ani on na yio jẹ ti Ọlọrun wa, yio si jẹ bi bãlẹ kan ni Juda, ati Ekroni bi Jebusi.
8Emi o si dó yi ilẹ mi ka nitori ogun, nitori ẹniti nkọja lọ, ati nitori ẹniti npada bọ̀: kò si aninilara ti yio là wọn já mọ: nitori nisisiyi ni mo fi oju mi ri.
Ọba Tí Ń Bọ̀ Wá Jẹ
9Yọ̀ gidigidi, iwọ ọmọbinrin Sioni; ho, Iwọ ọmọbinrin Jerusalemu: kiye si i, Ọba rẹ mbọ̀wá sọdọ rẹ: ododo li on, o si ni igbalà; o ni irẹ̀lẹ, o si ngùn kẹtẹkẹtẹ, ani ọmọ kẹtẹkẹtẹ.
10Emi o si ke kẹkẹ́ kuro ni Efraimu, ati ẹṣin kuro ni Jerusalemu, a o si ké ọrun ogun kuro: yio si sọ̀rọ alafia si awọn keferi: ijọba rẹ̀ yio si jẹ lati okun de okun, ati lati odo titi de opin aiye.
Ìmúpadà Sípò Àwọn Eniyan Mi
11Ni tirẹ pẹlu, emi o fi ẹjẹ majẹmu rẹ rán awọn igbèkun rẹ jade kuro ninu ihò ti kò li omi.
12Ẹ pada si odi agbara, ẹnyin onde ireti: ani loni yi emi sọ pe, emi o san a fun ọ ni igbàmejì.
13Nitori mo fa Juda le bi ọrun mi, mo si fi Efraimu kún u, mo si gbe awọn ọmọ rẹ ọkunrin dide, iwọ Sioni, si awọn ọmọ rẹ ọkunrin, iwọ ilẹ Griki, mo ṣe ọ bi idà alagbara.
14Oluwa yio si fi ara rẹ̀ hàn lori wọn, ọfà rẹ̀ yio si jade lọ bi mànamána: Oluwa Ọlọrun yio si fun ipè, yio si lọ ti on ti ãjà gusù.
15Oluwa awọn ọmọ-ogun yio dãbo bò wọn; nwọn o si jẹ ni run, nwọn o si tẹ̀ okuta kànna-kànna mọlẹ; nwọn o si mu, nwọn o si pariwo bi nipa ọti-waini; nwọn o si kún bi ọpọ́n, ati bi awọn igun pẹpẹ.
16Oluwa Ọlọrun wọn yio si gbà wọn là li ọjọ na bi agbo enia rẹ̀: nitori nwọn o dabi awọn okuta ade, ti a gbe soke bi àmi lori ilẹ rẹ̀.
17Nitori ore rẹ̀ ti tobi to, ẹwà rẹ̀ si ti pọ̀ to! ọkà yio mu ọdọmọkunrin darayá, ati ọti-waini titún yio mu awọn ọdọmọbinrin ṣe bẹ̃ pẹlu.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Sek 9: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: