1 Tẹsalonika Ìfáàrà

Ìfáàrà
Nínú ìrìnàjò iṣẹ́ ìránṣẹ́ Paulu kejì, ó ṣe ìbẹ̀wò sí Tẹsalonika ṣùgbọ́n ó sá nítorí iná inúnibíni ń jò geere níbẹ̀ (Ìṣe àwọn Aposteli 17.1-9). Lẹ́yìn tó mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n lọ sí Anteni, tó sì parí ìrìnàjò náà sí Kọrinti, Paulu gbọ́ láti ẹnu Timotiu ẹni tí ó rán lọ ṣe ìwádìí nípa àwọn ará Tẹsalonika pé wọ́n ṣì dúró ṣinṣin bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro dojúkọ wọ́n. Paulu kọ lẹ́tà yìí láti tù wọ́n nínú àti láti mú wọn lọ́kàn le pàápàá àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà nínú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. Ó tún kọ̀wé láti fi ẹsẹ̀ ìgbàgbọ́ wọn múlẹ̀ nínú ìlànà ilé Ọlọ́run, Ẹ̀mí Mímọ́, Kristi, ìgbé ayé onígbàgbọ́ àti nípa ìpadàbọ̀ Kristi ní ìgbà kejì. Nítorí àwọn onígbàgbọ́ kan ti kú, àwọn onígbàgbọ́ tókù ní ìgbàgbọ́ nínú ikú àti àjíǹde jẹ lógún. Paulu kọ̀wé láti fún wọn ní ìdánilójú pé òkú nínú Kristi yóò kọ́ jí dìde (4.16).
Paulu tu àwọn onígbàgbọ́ tí a ṣe inúnibíni sí nínú pẹ̀lú ìdánilójú pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú wọn àti pé ó fún wa ní ìdánilójú pé a ó ṣẹ́gun. Ìṣẹ́gun ìgbẹ̀yìn yóò wáyé ní ìpadàbọ̀ Kristi, nígbà tí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ yóò ti òkè ọ̀run sọ̀kalẹ̀ láti kó wa jọ sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ kí a bá à lè wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ títí ayé (4.17). Nítorí èyí a gbọdọ̀ dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́ bí a tilẹ̀ dojúkọ inúnibíni kí a sì gbé ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run, kí a wà ní àìlábùkù.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Paulu dúpẹ́ tọkàntọkàn lọ́wọ́ àwọn ará Tẹsalonika 1.1-10.
ii. Paulu dáàbò bo ara rẹ̀ 2.1-16.
iii. Àpèjúwe àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lẹ́yìn tó fi Tẹsalonika sílẹ̀ 2.7–3.13.
iv. Ọ̀rọ̀ ìyànjú lórí ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run 4.1-12.
v. Ìpadàbọ̀ Kristi nígbà kejì 4.13–5.11.
vi. Ọ̀rọ̀ ìyànjú ìparí 5.12-28.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

1 Tẹsalonika Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀