32
Ìjọba òdodo náà
1Wò ó, ọba kan yóò jẹ nínú òdodo
àwọn olórí yóò máa fi ìdájọ́ ṣe àkóso.
2Ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò jẹ́ bí ibi ìṣápamọ́ kúrò lọ́wọ́ afẹ́fẹ́
àti ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì,
gẹ́gẹ́ bí odò omi ní ilẹ̀ aṣálẹ̀,
àti bí òjìji àpáta ńlá ní ilẹ̀ gbígbẹ.
3Nígbà náà ni ojú àwọn tí ó rí kò ní padé mọ́,
àti etí àwọn tí ó gbọ́ yóò tẹ́tí sílẹ̀.
4Ọkàn àwọn oníwàdùwàdù ni yóò là tí yóò sì yè,
àti ahọ́n tí ń kólòlò ni yóò là geerege.
5A kò ní pe òmùgọ̀ ní ọlọ́lá mọ́
tàbí kí a fi ọ̀wọ̀ tí ó ga jù fún aláìlóòótọ́ ènìyàn.
6Nítorí òmùgọ̀ sọ̀rọ̀ òmùgọ̀,
ọkàn rẹ̀ kún fún ìwà ibi:
òun hùwà àìwà-bí-Ọlọ́run
ó sì ń tan àṣìṣe tí ó kan Olúwa kalẹ̀;
ẹni ebi ń pa ló fi sílẹ̀ lófo
àti fún àwọn tí òǹgbẹ ń gbẹ
ni ó mú omi kúrò.
7Ibi ni gbogbo ọgbọ́n àwọn ìkà ènìyàn jẹ́,
ó ń gba èrò búburú
láti fi ọ̀rọ̀ èké pa tálákà run,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀bẹ̀ aláìní sì tọ̀nà.
8Ṣùgbọ́n ọlọ́lá ènìyàn a máa pète ohun ńlá
àti nípa èrò rere ni yóò dúró.
Àwọn obìnrin Jerusalẹmu
9Ẹ̀yin obìnrin tí ẹ ti gba ìtẹ́lọ́rùn gidi
ẹ dìde kí ẹ tẹ́tí sí mi,
ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin tí ọkàn yín ti balẹ̀,
ẹ gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ!
10Ní ó lé díẹ̀ ní ọdún kan
ẹ̀yin tí ọkàn an yín balẹ̀ yóò wárìrì;
ìkórè àjàrà kò ní múnádóko,
bẹ́ẹ̀ ni ìkórè èso kò ní sí.
11Wárìrì, ẹ̀yin obìnrin onítẹ̀lọ́rùn
bẹ̀rù, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin tí ẹ rò pé ọkàn yín balẹ̀!
Ẹ bọ́ aṣọ yín kúrò,
ẹ ró aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ yín.
12Ẹ lu ọmú yín fún pápá ìgbádùn náà,
fún àwọn àjàrà eléso
13àti fún ilẹ̀ àwọn ènìyàn mi
ilẹ̀ tí ó ti kún fún ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n—
bẹ́ẹ̀ ni, kẹ́dùn fún gbogbo ilé ìtura
àti fún ìlú àríyá yìí.
14Ilé olódi ni a ó kọ̀sílẹ̀,
ìlù aláriwo ni a ó kọ̀ tì;
ilé olódi àti ilé ìṣọ́ ni yóò di ihò títí láéláé,
ìdùnnú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti pápá
oko fún àwọn ẹran ọ̀sìn,
15títí a ó fi tú Ẹ̀mí sí wa lórí láti òkè wá,
àti ti aṣálẹ̀ tí yóò dí pápá oko ọlọ́ràá
àti tí pápá ọlọ́ràá yóò dàbí ẹgàn.
16Ẹ̀tọ́ yóò máa gbé ní inú aṣálẹ̀
àti òdodo yóò sì máa gbé ní pápá oko ọlọ́ràá.
17Èso òdodo náà yóò sì jẹ́ àlàáfíà;
àbájáde òdodo yóò sì jẹ́ ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé títí láé.
18Àwọn ènìyàn mi yóò máa gbé ní ibùgbé àlàáfíà,
ní ibùgbé ìdánilójú,
ní àwọn ibi ìsinmi tí ó parọ́rọ́.
19Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé yìnyín ti tẹ́jú igbó pẹrẹsẹ
àti tí ojú ìlú ti tẹ́ pẹrẹsẹ pátápátá,
20báwo ni ẹ ó ti jẹ́ alábùkún tó,
nípa gbígbin irúgbìn sí ipa odò gbogbo,
àti nípa jíjẹ́ kí àwọn màlúù yín àti
àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ jẹ láìsí ìdíwọ́.