Onidajọ Ìfáàrà

Ìfáàrà
Ìwé Onidajọ sọ nípa ìgbé ayé àwọn ọmọ Israẹli ní ilẹ̀ ìlérí láti ìgbà ikú Joṣua títí wọ́n fi ń jẹ ọba tí ó ń darí wọn, ó jẹ́ àsìkò tí àwọn ọba ti jẹ lòdì sí Ọlọ́run wọn, tí wọ́n sì mú Ọlọ́run bínú. Bákan náà, ó sọ nípa ẹ̀bẹ̀ tí wọ́n máa ń bẹ̀ sí Ọlọ́run nígbà ìṣòro àti wàhálà, èyí mú kí Ọlọ́run gbé àwọn adarí (Onidajọ) dìde ní ilẹ̀ àwọn àjèjì tó ń jẹ wọ́n ní yà tí yóò sì dá àlàáfíà padà fún wọn.
Gideoni rán àwọn ọmọ Israẹli létí pé Olúwa ni ọba wọn. Ohun tí ó ṣe pàtàkì sí wọn ni pé wọ́n ń fẹ́ ọba tí yóò máa darí wọn (ọba ti ayé) tí wọn kò sì náání òfin àti ìlànà ọba ti ọ̀run. Olúwa sì lo ìlànà aninilára láti bá àwọn ènìyàn rẹ̀ wí, àti láti mú kí ìpinnu rẹ̀ wá sí ìmúṣẹ tí ó ti ṣèlérí fún wọn síwájú àsìkò yìí (Le 26.14-45; De 28.15-68) àti láti mú kí ó gbé Olùgbàlà dìde nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ kígbe sókè sí i àti mímú kí jíjọba ní Israẹli di fífìdímúlẹ̀. Igbe àwọn ọmọ Israẹli wá ṣàfihàn ìfìdí jíjẹ ọba múlẹ̀ kí wọn tó lè wọ ilẹ̀ ìlérí láti sinmi (Jo 1.13).
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Israẹli kùnà láti gba ilẹ̀ náà tán 1.1–3.6.
ii. Àwọn onídàájọ́ kékeré 3.7-31.
iii. Onidajọ obìnrin 4.1–5.31.
iv. Àwọn Adájọ́ ńlá 6.1–16.31.
v. Ẹ̀sìn àti ìwà ìṣekúṣe 17.1–21.25.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Onidajọ Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀