Jobu Ìfáàrà

Ìfáàrà
Ìwé Jobu jẹ́ kí a mọ̀ pé, Jobu jẹ́ ẹni tí ó fi gbogbo ayé rẹ̀ fẹ́ Ọlọ́run, ì bà ṣe pọ̀ pẹ́kípẹ́kí wà láàrín àwọn méjèèjì. Nígbà tí Satani alátakò gbọ́ pé Ọlọ́run pe Jobu ní Olódodo, ìgbà yìí ni ó bẹ Ọlọ́run pé kí ó gba òun láàyè láti dán an wò, Ọlọ́run sì fún un ni ààyè láti ṣe bẹ́ẹ̀. Gbogbo akitiyan èṣù lórí Jobu ló jà sì asán nítorí tí kò sọ ohun búburú sí Ọlọ́run.
Gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ Jobu nínú ìwé rẹ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ ìdárò, irú ìdárò tí Jobu ṣe rí bí i ti inú ìwé Saamu. Nítòótọ́ àwọn ọ̀rẹ́ Jobu wá láti tù ú nínú, wọ́n béèrè pé, èéṣe tí Jobu fi ń jìyà. Nítorí pé Jobu jẹ́ olódodo níwájú Ọlọ́run, èṣù kò ráàyè nínú ayé rẹ̀, Ọlọ́run sì dá a padà sí ipò rẹ̀, ó sì dá àwọn ohun ìní rẹ̀ náà padà fún un.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìgbé ayé Jobu 1.1–2.13.
ii. Ìjíròrò àti wàhálà Jobu 3.1-26.
iii. Ìfi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ 4.1–14.22.
iv. Ìfi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ èkejì 15.1–21.34.
v. Ìfi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ ẹlẹ́kẹta 22.1–27.23.
vi. Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n àti òye 28.1-28.
vii. Ìparí ọ̀rọ̀ Jobu 29.1–31.40.
viii. Ọ̀rọ̀ Elihu 32.1–37.24.
ix. Èsì Olúwa 38.1–42.6.
x. Ọ̀rọ̀ ìparí 42.7-17.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Jobu Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀