Malaki Ìfáàrà

Ìfáàrà
A ti fún àwọn Júù láààyè láti padà sílé kúrò ní ìgbèkùn, kí wọn sì tún tẹmpili kọ́. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ó bà wọ́n lọ́kàn jẹ́; ilẹ̀ wọn yóò wà bi ti ìṣáájú, ṣùgbọ́n ìjọba kékeré ni a ó fi fun wọn lẹ́yìn odò Persia, ògo ọjọ́ iwájú wọn tí a ti kéde láti ẹnu àwọn wòlíì, a kò ì tí ì fi sílẹ̀ fún wọn àti pé Ọlọ́run wọn kò i tí ì wá sínú tẹmpili rẹ̀ pẹ̀lú ọláńlá àti agbára. Èyí sì mú kí àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ ìrètí wọn nù. Nítorí èyí, ìsìn wọn bẹ̀rẹ̀ sí ní dínkù, wọn kò sì ka òfin sí pàtàkì mọ́. Malaki bá wọn wí nínú iyèméjì wọn sí ìfẹ́ Ọlọ́run àti nínú àìṣòótọ́ wọn sí àlùfáà àti àwọn ènìyàn. Malaki sì bá wọn wí pé, Ọlọ́run tí wọn ń wá yóò wá bí “iná ẹni tí ń da fàdákà” (3.2). Òun yóò wá láti kọ́kọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ (3.5).
Malaki sọ bí májẹ̀mú ìfẹ́ Ọlọ́run fún Israẹli ṣe wà síbẹ̀. Ó sọ bí àwọn ènìyàn ṣe kọ̀ láti ṣe ojúṣe wọn fún Ọlọ́run tí wọ́n sì ń gbéraga sí i, tí wọ́n sì ya kúrò nínú òfin àti ìlànà rẹ̀. Ó kọ ìrúbọ wọn tí wọ́n rú sí i ní ọ̀nà àìtọ́. Ó bá àwọn àlùfáà náà wí nítorí àìdọ́gba wọn pẹ̀lú Ọlọ́run. Ọlọ́run ṣe ìlérí láti rán Olùgbàlà wá láti mú ohun gbogbo padà bọ̀ sí ipò rẹ̀, tí ìgbé ayé yóò sì máa dùn fún wọn bí ti àtẹ̀yìnwá. Ọlọ́run fẹ́ ẹ̀tọ́ rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀; ẹbọ tí a fi ẹran tí ó dára rú, ìdámẹ́wàá àti ọrẹ. Malaki lo àwọn èdè tó ní dídún bí àwítúnwí, gbólóhùn ìbéèrè àmọ̀túnbini. Malaki ṣe àtẹnumọ́ “Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun” bí ìgbà ogún. Ọjọ́ Olúwa ń bọ̀ tí yóò jẹ́ ọjọ́ ẹ̀rù (4.5).
Kókó-ọ̀rọ̀
ii. Ìbẹ̀rẹ̀ Májẹ̀mú ìfẹ́ Ọlọ́run fún ìdúró Israẹli 1.1–1.5.
iii. A bá àìṣòdodo àwọn Israẹli wí 1.6–2.16.
iv. Olúwa yóò wá láti ya àwọn àlùfáà sí mímọ́ àti láti ṣe ìdájọ́ ènìyàn 2.17–3.18.
v. Ìkéde bíbọ̀ Olúwa 4.1-6.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Malaki Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀