Nehemiah Ìfáàrà

Ìfáàrà
Ohun kan náà ni ìwé Nehemiah yìí àti ìwé Esra ń sọ fún wa. Àwọn méjèèjì ní àwòjìji kan náà, a kò sì le yà wọ́n nínú ara wọn. Gẹ́gẹ́ bí àgbéyẹ̀wò wọ́n, àwọn kan sọ pé Esra ni ó kọ́kọ́ dé Jerusalẹmu, lẹ́yìn èyí ni Nehemiah tó dé, bákan náà àwọn kan sọ pé Nehemiah ni ó kọ́kọ́ dé ṣáájú Esra. Èyí mú kí wọn tẹpẹlẹ mọ́ ọn pé a kò le ya àwọn méjèèjì nínú ara wọn. Ìdí èyí ló mú kí Jeromu, ọ̀kan lára àwọn onímọ̀ Bíbélì pe ìwé Nehemiah ní ìwé kejì ìwé Esra.
Kókó tí ó ṣe gbòógì tí ìwé Nehemiah dálé lórí náà ni ìpè Nehemiah, ìpè láàrín àwọn ọmọ Israẹli láti tún odi Jerusalẹmu tó wó mọ. Nehemiah fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn wọ́n nípa odi tí ó wó yìí, ó sì pe ìpè jáde láti tún odi náà mọ.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Nehemiah ní ìgbà àkọ́kọ́ 1.1–2.16.
ii. Nehemiah gba àmọ̀ràn láti tún odi kọ́ 2.17–7.3.
iii. Àwọn ìgbèkùn tí ó padà dé 7.4–7.73.
iv. Esra ka ìwé òfin, àwọn ènìyàn jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn 8.1–10.39.
v. Ibùgbé tuntun ní Jerusalẹmu 11.1–11.36.
vi. Iṣẹ́ ìgbẹ̀yìn Nehemiah 12.1–13.31.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Nehemiah Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀