Filemoni Ìfáàrà

Ìfáàrà
Ẹrú kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Onesimu, ọ̀gá ẹni tí í ṣe Kristiani kan ní Kolose, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Filemoni. Ẹni tí ó sá ní ọ̀dọ̀ olówó rẹ̀ lọ sí Romu. Níbí ni ó ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ìhìnrere láti ẹnu Paulu tí ó sì di Kristiani. Paulu kọ lẹ́tà yìí sí Filemoni kí ó lè gba Onesimu padà sí ọ̀dọ̀ gẹ́gẹ́ bí arákùnrin rẹ̀ nínú ìgbàgbọ́, kí i sì ṣe bí ẹrú tó ti jẹ́ tẹ́lẹ̀ rí. Paulu sọ pé nísinsin yìí, Onesimu yóò wúlò fún Filemoni àti fún iṣẹ́ ìhìnrere.
Ìwé kékeré yìí ṣe pàtàkì ní gbogbo ọ̀nà. Ohun méjì pàtàkì ni ó fi ara hàn nínú rẹ̀. Ní ọ̀nà kìn-ín-ní, a rí i bí ìhìnrere ṣe ń ṣiṣẹ́, kò sí ẹni tó burú kọjá iṣẹ́ Ọlọ́run tó fi dé orí ẹni tó sálọ. Bí ẹnikẹ́ni bá gba Kristi yóò di ènìyàn ọ̀tun. Ní ọ̀nà kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn èrò tó máa ń fa ìdínà àti ìkórìíra ní ìgbà àtijọ́ ti di àmúkúrò. Filemoni àti Onesimu ti di arákùnrin kan náà nínú ìgbàgbọ́ nísinsin yìí. Ní àìpẹ́ ni gbogbo ìlànà amúnilẹ́rú yóò fọ́ túútúú nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ Kristi.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Paulu kí Filemoni 1-3.
ii. Paulu gbé oríyìn fún Filemoni 4-7.
iii. Paulu bẹ̀bẹ̀ fún Onesimu 8-21.
iv. Ọ̀rọ̀ ìparí 22-25.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Filemoni Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀