10
Àwọn òwe Solomoni
1Àwọn òwe Solomoni:
ọlọ́gbọ́n ọmọ ń mú inú baba rẹ̀ dùn
ṣùgbọ́n aṣiwèrè ọmọ ń ba inú ìyá rẹ̀ jẹ́.
2Ìṣúra tí a kójọ nípa ìwà búburú kò ní èrè
ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú.
3 Olúwa kì í jẹ́ kí ebi máa pa olódodo
ṣùgbọ́n ó ba ète àwọn ènìyàn búburú jẹ́.
4Ọwọ́ tí ó lẹ máa ń sọ ènìyàn di tálákà,
ṣùgbọ́n ọwọ́ tí ó múra ṣíṣẹ́ a máa sọ ni di ọlọ́rọ̀.
5Ẹni tí ó kó irúgbìn jọ ní àsìkò òjò jẹ́ ọlọ́gbọ́n ọmọ,
ṣùgbọ́n ẹni tí ó sùn ní àsìkò ìkórè jẹ́ adójútini ọmọ.
6Ìbùkún ní ó máa ń kún orí olódodo
ṣùgbọ́n ìwà ipá máa ń kún ẹnu ènìyàn búburú.
7Ìrántí olódodo yóò jẹ́ ìbùkún
ṣùgbọ́n orúkọ ènìyàn búburú yóò jẹrà.
8Ẹni tí ó gbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ máa ń gba àṣẹ,
ṣùgbọ́n ètè wérewère yóò parun.
9Ẹni tí ó ń rìn déédé, ń rìn láìléwu
ṣùgbọ́n àṣírí ẹni tí ń rin ọ̀nà pálapàla yóò tú.
10Ẹni tí ń ṣẹ́jú pàkòpàkò fún ibi ń fa àìbalẹ̀ ọkàn
aláìgbọ́n tí ń ṣàròyé kiri yóò parun.
11Ẹnu olódodo jẹ́ orísun ìyè
ṣùgbọ́n ìwà ipá ni ó gba gbogbo ẹnu ènìyàn búburú.
12Ìríra a máa dá ìjà sílẹ̀,
ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa bo gbogbo àṣìṣe mọ́lẹ̀.
13Ọgbọ́n ni a ń bá lẹ́nu àwọn olóye
ṣùgbọ́n kùmọ̀ wà fún ẹ̀yìn àwọn aláìlóye.
14Ọlọ́gbọ́n ènìyàn kó ìmọ̀ jọ
ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n a máa ṣokùnfà ìparun.
15Ọrọ̀ àwọn olódodo ni ìlú olódi wọn,
ṣùgbọ́n òsì ni ìparun aláìní.
16Èrè olódodo ń mú ìyè wá fún wọn
ṣùgbọ́n èrè ènìyàn búburú ń mú ìjìyà wá fún wọn.
17Ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí fi ọ̀nà sí ìyè hàn
ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ ìbáwí mú àwọn mìíràn ṣìnà.
18Ẹni tí ó pa ìkórìíra rẹ̀ mọ́ jẹ́ òpùrọ́
ẹni tí ó sì ń ba ni jẹ́ jẹ́ aláìgbọ́n.
19Nínú ọ̀rọ̀ púpọ̀ a kò le fẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kù
ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n.
20Ètè olódodo jẹ́ ààyò fàdákà
ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú kò níye lórí.
21Ètè olódodo ń bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀
ṣùgbọ́n aláìgbọ́n ń kú nítorí àìlóye.
22Ìbùkún Olúwa ń mú ọrọ̀ wá,
kì í sì í fi ìdààmú sí i.
23Aláìgbọ́n a máa ní inú dídùn sí ìwà búburú
ṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa ní inú dídùn sí ọgbọ́n.
24Ohun tí ènìyàn búburú bẹ̀rù yóò dé bá a;
Olódodo yóò rí ohun tí ó fẹ́ gbà.
25Nígbà tí ìjì bá ti jà kọjá, ènìyàn búburú a kọjá lọ,
ṣùgbọ́n Olódodo yóò dúró ṣinṣin láéláé.
26Bí ọtí kíkan sí eyín, àti èéfín sí ojú
bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ sí ẹni tí ó rán an níṣẹ́.
27Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ọjọ́ ayé gígùn wá,
ṣùgbọ́n a gé ọjọ́ ayé ènìyàn búburú kúrú.
28Ìrètí olódodo ni ayọ̀
ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn búburú jásí òfo.
29Ọ̀nà Olúwa jẹ́ ààbò fún olódodo,
ṣùgbọ́n ìparun ni ó jẹ́ fún àwọn tí ń ṣe ibi.
30A kì yóò fa olódodo tu láéláé
ṣùgbọ́n ènìyàn búburú kì yóò dúró pẹ́ lórí ilẹ̀.
31Ẹnu olódodo ń mú ọgbọ́n jáde wá,
ṣùgbọ́n ètè àyípadà ni a ó gé kúrò.
32Ètè olódodo mọ ohun ìtẹ́wọ́gbà,
ṣùgbọ́n ètè ènìyàn búburú kò mọ̀ ju èké lọ.