Saamu 140

140
Saamu 140
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
1 Olúwa, gbà mi lọ́wọ́ ọkùnrin búburú u nì,
yọ mí lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì;
2Ẹni tí ń ro ìwà búburú ní inú wọn;
nígbà gbogbo ni wọ́n ń rú ìjà sókè sí mi.
3Wọ́n ti pọ́n ahọ́n wọn bí ejò,
oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ ní abẹ́ ètè wọn.
4 Olúwa, pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú;
yọ mí kúrò lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì
ẹni tí ó ti pinnu rẹ̀ láti bi ìrìn mi ṣubú
5Àwọn agbéraga ti dẹkùn sílẹ̀ fún mi àti okùn:
wọ́n ti na àwọ̀n lẹ́bàá ọ̀nà;
wọ́n ti kẹ́kùn sílẹ̀ fún mi.
6Èmi wí fún Olúwa pé ìwọ ni Ọlọ́run mi;
Olúwa, gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.
7 Olúwa Olódùmarè, agbára ìgbàlà mi,
ìwọ ni ó bo orí mi mọ́lẹ̀ ní ọjọ́ ìjà.
8 Olúwa, máa ṣe fi ìfẹ́ ènìyàn búburú fún un;
Má ṣe kún ọgbọ́n búburú rẹ̀ lọ́wọ́;
kí wọn kí ó máa ba à gbé ara wọn ga. Sela.
9Bí ó ṣe ti orí àwọn tí ó yí mi káàkiri ni,
jẹ́ kí ète ìka ara wọn kí ó bò wọ́n mọ́lẹ̀.
10A ó da ẹ̀yin iná sí wọn lára:
Òun yóò wọ́ wọn lọ sínú iná,
sínú ọ̀gbun omi jíjìn,
kí wọn kí ó má ba à le dìde mọ́.
11Má ṣe jẹ́ kí aláhọ́n búburú fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ní ayé;
ibi ni yóò máa dọdẹ ọkùnrin ìkà nì láti bì í ṣubú.
12Èmi mọ̀ pé, Olúwa yóò mú ọ̀nà olùpọ́njú dúró,
yóò sì ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn tálákà
13Nítòótọ́ àwọn olódodo yóò
máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ;
àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yóò máa gbé iwájú rẹ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Saamu 140: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀