9
1Angẹli karùn-ún sì fún ìpè tirẹ̀ mo sì rí ìràwọ̀ kan bọ́ sílẹ̀ láti ọ̀run wá: a sì fi kọ́kọ́rọ́ ihò ọ̀gbun fún un. 2 Ó sì ṣí ihò ọ̀gbun náà, èéfín sì rú jáde láti inú ihò náà wá, bí èéfín ìléru ńlá, oòrùn àti ojú sánmọ̀ sì ṣókùnkùn nítorí èéfín ihò náà. 3 Àwọn eṣú sì jáde ti inú èéfín náà wá sórí ilẹ̀: a sì fi agbára fún wọn gẹ́gẹ́ bí agbára àkéekèe ilẹ̀. 4 A sì fún wọn pé ki wọn má ṣe pa koríko ilẹ̀ lára tàbí ohun tútù kan, tàbí igikígi kan; bí kò ṣe àwọn ènìyàn tí kò ni èdìdì Ọlọ́run ní iwájú wọn. 5A sì pàṣẹ fún wọn pé, kí wọn má ṣe pa wọ́n, ṣùgbọ́n kí a dá wọn ni oró ni oṣù márùn-ún: oró wọn sì dàbí oró àkéekèe, nígbà tí o bá ta ènìyàn. 6 Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn yóò sì máa wá ikú, wọn kì yóò sì rí i; wọn yóò sì fẹ́ láti kú, ikú yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wọn.
7 Ìrísí àwọn eṣú náà sì dàbí àwọn ẹṣin tí a múra sílẹ̀ fún ogun; àti ní orí wọn ni ohun tí o dàbí àwọn adé wúrà wà, ojú wọn sì dàbí ojú ènìyàn; 8 wọ́n sì ní irun bí obìnrin, eyín wọn sì dàbí ti kìnnìún. 9 Wọ́n sì ní ìgbàyà tí ó dàbí ìgbàyà irin; ìró ìyẹ́ wọn sì dàbí ìró kẹ̀kẹ́-ẹṣin púpọ̀ tí ń súré lọ sí ogun. 10Wọ́n sì ni ìrù àti oró bí tí àkéekèe, àti ní ìrù wọn ni agbára wọn wà láti pa ènìyàn lára fún oṣù márùn-ún. 11Wọ́n ní angẹli ọ̀gbun náà bí ọba lórí wọn, orúkọ rẹ̀ ní èdè Heberu ní Abaddoni, àti ni èdè Giriki orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Apollioni.
12Ègbé kan tí kọjá, kíyèsi i, ègbé méjì ń bọ̀ síbẹ̀ lẹ́yìn èyí.
13 Angẹli kẹfà si fọn ìpè rẹ̀, mo sì gbọ́ ohùn kan láti ibi ìwo mẹ́rin pẹpẹ wúrà wá, tí ń bẹ níwájú Ọlọ́run. 14Òun wí fún angẹli kẹfà náà tí o ni ìpè náà pé, “Tú àwọn angẹli mẹ́rin náà sílẹ̀ tí a dè lẹ́bàá odò ńlá Eufurate!” 15A sì tú àwọn angẹli mẹ́rin náà sílẹ̀, tí a ti pèsè tẹ́lẹ̀ fún wákàtí náà, àti ọjọ́ náà, àti oṣù náà, àti ọdún náà, láti pa ìdámẹ́ta ènìyàn. 16Iye ogún àwọn ẹlẹ́ṣin sì jẹ́ àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà igba: mo sì gbọ́ iye wọn.
17Báyìí ni mo sì rí àwọn ẹṣin náà ní ojúran, àti àwọn tí o gùn wọ́n, wọ́n ni ìgbàyà aláwọ̀ iná, àti ti jakinti, àti tí sulfuru: orí àwọn ẹṣin náà sì dàbí orí àwọn kìnnìún; àti láti ẹnu wọn ni iná, àti èéfín, àti sulfuru tí ń jáde. 18Nípa ìyọnu mẹ́ta wọ̀nyí ni a tí pa ìdámẹ́ta ènìyàn, nípa iná, àti nípa èéfín, àti nípa sulfuru tí o ń tí ẹnu wọn jáde. 19Nítorí pé agbára àwọn ẹṣin náà ń bẹ ní ẹnu wọn àti ní ìrù wọn: nítorí pé ìrù wọn dàbí ejò, wọn sì ní orí, àwọn wọ̀nyí ni wọn sì fi ń pa ni lára.
20 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ìyókù tí a kò sì ti ipa ìyọnu wọ̀nyí pa, kò sì ronúpìwàdà iṣẹ́ ọwọ́ wọn, kí wọn má ṣe sin àwọn ẹ̀mí èṣù àti ère wúrà, àti ti fàdákà, àti ti idẹ, àti òkúta, àti ti igi mọ́: àwọn tí kò lè ríran, tàbí kí wọn gbọ́rọ̀, tàbí kí wọn rìn: 21Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ronúpìwàdà ìwà ìpànìyàn wọn, tàbí oṣó wọn tàbí àgbèrè wọn, tàbí olè wọn.