Orin Solomoni 4

4
Olùfẹ́
1Báwo ni ìwọ ti lẹ́wà tó olólùfẹ́ mi!
Háà, ìwọ jẹ́ arẹwà!
Ìwọ ní ojú àdàbà lábẹ́ ìbòjú rẹ
irun rẹ bò ọ́ lójú bí ọ̀wọ́ ewúrẹ́.
Tí ó sọ̀kalẹ̀ lórí òkè Gileadi.
2Eyín rẹ̀ funfun bí i irun àgbò
tí ó gòkè wá láti ibi ìwẹ̀;
olúkúlùkù wọn bí èjìrẹ́;
kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó da dúró.
3Ètè rẹ dàbí òwú òdòdó;
ẹnu rẹ̀ dùn.
Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dàbí ẹ̀là pomegiranate
lábẹ́ ìbòjú rẹ
4Ọrùn rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Dafidi,
tí a kọ́ pẹ̀lú ìhámọ́ra;
lórí rẹ̀ ni a fi ẹgbẹ̀rún àpáta kọ́,
gbogbo wọn jẹ́ àṣà àwọn alágbára.
5Ọmú rẹ̀ méjèèjì dàbí abo egbin méjì
tí wọ́n jẹ́ ìbejì
tí ń jẹ láàrín ìtànná ewéko lílì.
6Títí ọjọ́ yóò fi rọ̀
tí òjìji yóò fi fò lọ,
Èmi yóò lọ sí orí òkè ńlá òjìá
àti sí òkè kékeré tùràrí.
7Gbogbo ara rẹ jẹ́ kìkì ẹwà, olólùfẹ́ mi;
kò sì ṣí àbàwọ́n lára rẹ.
8Kí a lọ kúrò ní Lebanoni, ìyàwó mi,
ki a lọ kúrò ní Lebanoni.
Àwa wò láti orí òkè Amana,
láti orí òkè ti Seniri, àti téńté Hermoni,
láti ibi ihò àwọn kìnnìún,
láti orí òkè ńlá àwọn ẹkùn.
9Ìwọ ti gba ọkàn mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi;
ìwọ ti gba ọkàn mi
pẹ̀lú ìwò ẹ̀ẹ̀kan ojú rẹ,
pẹ̀lú ọ̀kan nínú ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ,
10Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó, arábìnrin mi, ìyàwó mi!
Ìfẹ́ rẹ tu ni lára ju ọtí wáìnì lọ,
òórùn ìkunra rẹ sì ju òórùn gbogbo tùràrí lọ!
11Ètè rẹ ń kan dídùn bí afárá oyin, ìyàwó mi;
wàrà àti oyin wà lábẹ́ ahọ́n rẹ.
Òórùn aṣọ rẹ sì dàbí òórùn Lebanoni.
12Arábìnrin mi ni ọgbà tí a sọ, arábìnrin mi, ìyàwó mi
ìsun tí a sé mọ́, orísun tí a fi èdìdì dì.
13Ohun ọ̀gbìn rẹ àgbàlá pomegiranate ni
ti òun ti àṣàyàn èso; kipiresi àti nadi,
14Nadi àti Safironi,
kalamusi àti kinamoni,
àti gbogbo igi olóòórùn dídùn,
òjìá àti aloe
pẹ̀lú irú wọn.
15Ìwọ ni ọgbà orísun, kànga omi ìyè,
ìṣàn omi láti Lebanoni wá.
Olólùfẹ́
16Jí ìwọ afẹ́fẹ́ àríwá
kí o sì wá, afẹ́fẹ́ gúúsù!
Fẹ́ lórí ọgbà mi,
kí àwọn òórùn dídùn inú rẹ lè rùn jáde.
Jẹ́ kí olùfẹ́ mi wá sínú ọgbà a rẹ̀
kí ó sì jẹ àṣàyàn èso rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Orin Solomoni 4: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀