Ṣe àfiwé gbogbo èyà
I. Kro 10:13-14YBCV(Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni Saulu kú ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o da si Oluwa, nitori ọ̀rọ Oluwa, ti on kò kiyesi, ati pẹlu nitori o lọ bère ọ̀ràn lọwọ abokusọrọ, lati ṣe ibere. Kò si bère lọwọ Oluwa; nitorina li o ṣe pa a, o si yi ijọba na pada sọdọ Dafidi ọmọ Jesse.
I. Kro 10:13-14BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Saulu kú nítorí kò ṣe òtítọ́ sí OLúWA, kò pa ọ̀rọ̀ OLúWA mọ́ pẹ̀lú, ó tọ abókùúsọ̀rọ̀ lọ fún ìtọ́sọ́nà. Kò sì béèrè lọ́wọ́ OLúWA, bẹ́ẹ̀ ni OLúWA pa á, Ó sì yí ìjọba náà padà sọ́dọ̀ Dafidi ọmọ Jese.
I. Kro 10:13-14YCE(Yoruba Bible)
Bẹ́ẹ̀ ni Saulu ṣe kú nítorí aiṣododo rẹ̀; ó ṣàìgbọràn sí àṣẹ OLUWA, ó sì lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ abókùúsọ̀rọ̀, ó lọ bèèrè ìtọ́sọ́nà níbẹ̀, dípò kí ó bèèrè ìtọ́sọ́nà lọ́wọ́ OLUWA. Nítorí náà, OLUWA pa á, ó sì gbé ìjọba rẹ̀ fún Dafidi, ọmọ Jese.
Pín
I. Kro 10YCE