Ṣe àfiwé gbogbo èyà
I. Kro 28:20YBCV(Bibeli Mimọ)
Dafidi si sọ fun Solomoni ọmọ rẹ̀ pe, murale ki o si gboyà, ki o si ṣiṣẹ: má bẹ̀ru, bẹ̃ni ki o máṣe dãmu: nitori Oluwa Ọlọrun, ani Ọlọrun mi wà pẹlu rẹ; on kì yio yẹ̀ ọ, bẹ̃ni kì yio kọ̀ ọ silẹ titi iwọ o fi pari gbogbo iṣẹ fun ìsin ile Oluwa.
I. Kro 28:20BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dafidi tún sọ fún Solomoni ọmọ rẹ̀ pé, “Jẹ́ alágbára kí o sì gbóyà, kí o sì ṣe iṣẹ́ náà. Má ṣe bẹ̀rù tàbí dààmú, nítorí OLúWA Ọlọ́run, Ọlọ́run mi, wà pẹ̀lú rẹ. Òun kì yóò sì já ọ kule tàbí kọ ọ sílẹ̀ títí gbogbo iṣẹ́ fún ìsìn ní ti ilé OLúWA yóò fi parí.
I. Kro 28:20YCE(Yoruba Bible)
Dafidi bá sọ fún Solomoni, ọmọ rẹ̀ pé, “Múra gírí, mú ọkàn le, kí o sì ṣe bí mo ti wí. Má bẹ̀rù, má sì jẹ́ kí ọkàn rẹ rẹ̀wẹ̀sì; nítorí OLUWA Ọlọrun, àní Ọlọrun mi, wà pẹlu rẹ. Kò ní já ọ kulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní kọ̀ ọ́ sílẹ̀, títí tí iṣẹ́ ilé OLUWA yóo fi parí.