Ṣe àfiwé gbogbo èyà
I. Kro 28:9YBCV(Bibeli Mimọ)
Ati iwọ, Solomoni ọmọ mi, mọ̀ Ọlọrun baba rẹ, ki o si fi aiya pipé ati fifẹ ọkàn sìn i: nitori Oluwa a ma wá gbogbo aiya, o si mọ̀ gbogbo ete ironu: bi iwọ ba ṣafẹri rẹ̀, iwọ o ri i; ṣugbọn bi iwọ ba kọ̀ ọ silẹ on o ta ọ nù titi lai.
I. Kro 28:9BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Àti ìwọ, ọmọ mi Solomoni, rántí Ọlọ́run baba à rẹ, kí o sì sìn ín pẹ̀lú tọkàntọkàn pẹ̀lú ìfọkànsí pẹ̀lú ọkàn tí ó pé, nítorí OLúWA ṣàwárí gbogbo ọkàn ó sì mọ gbogbo èrò. Tí ìwọ bá wá a, ìwọ yóò rí i; ṣùgbọ́n tí ìwọ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, òun yóò kọ̀ ọ́ títí láé.
I. Kro 28:9YCE(Yoruba Bible)
“Ìwọ Solomoni, ọmọ mi, mọ Ọlọrun àwọn baba rẹ, kí o sì fi gbogbo ọkàn rẹ sìn ín tìfẹ́tìfẹ́, nítorí OLUWA a máa wádìí ọkàn, ó sì mọ gbogbo èrò ati ète eniyan. Bí o bá wá OLUWA, o óo rí i, ṣugbọn bí o bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, yóo ta ọ́ nù títí lae.
Pín
I. Kro 28YCE