I. A. Ọba 19:11
I. A. Ọba 19:11 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si wipe, Jade lọ, ki o si duro lori oke niwaju Oluwa. Si kiyesi i, Oluwa kọja, ìji nla ati lile si fà awọn oke nla ya, o si fọ́ awọn apata tũtu niwaju Oluwa; ṣugbọn Oluwa kò si ninu iji na: ati lẹhin iji na, isẹlẹ; ṣugbọn Oluwa kò si ninu isẹlẹ na.
I. A. Ọba 19:11 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA wí fún un pé, “Lọ dúró níwájú mi ní orí òkè yìí.” OLUWA ba kọjá lọ, ẹ̀fúùfù líle kán fẹ́, ó la òkè náà, ó sì fọ́ àwọn òkúta rẹ̀ sí wẹ́wẹ́ níwájú OLUWA. Ṣugbọn OLUWA kò sí ninu ẹ̀fúùfù líle náà. Lẹ́yìn ẹ̀fúùfù náà, ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣẹ̀, gbogbo ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mì tìtì. Ṣugbọn OLUWA kò sí ninu ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
I. A. Ọba 19:11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sì wí pé, “Jáde lọ, kí o sì dúró lórí òkè níwájú OLúWA, nítorí OLúWA fẹ́ rékọjá.” Nígbà náà ni ìjì ńlá àti líle sì fa àwọn òkè ńlá ya, ó sì fọ́ àwọn àpáta túútúú níwájú OLúWA; ṣùgbọ́n OLúWA kò sí nínú ìjì náà. Lẹ́yìn ìjì náà ni ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀, ṣùgbọ́n OLúWA kò sí nínú ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀ náà.